Ẹ̀KỌ́ 7
Títẹnumọ́ Àwọn Kókó Pàtàkì
KÌ Í ṣe gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nìkan ni òǹkàwé tó dáńgájíá máa ń fún láfiyèsí, kódà kì í ṣe ìpínrọ̀ tí irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ ti fara hàn nìkan ló máa fún láfiyèsí. Nígbà tó bá ń kàwé, yóò ní àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àkójọ ọ̀rọ̀ tó fẹ́ kà jáde látòkèdélẹ̀ lọ́kàn. Èyí lá jẹ́ kó mọ ibi tó máa tẹnu mọ́.
Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní sí àwọn kókó tó máa hàn gedegbe nínú ohun tó bá kà. Kò ní sóhun tó máa fara hàn kedere. Nígbà tó bá kà á tán, ó lè ṣòro fún àwùjọ láti rántí kókó kan pàtó tó ṣe pàtàkì.
Títẹnumọ́ àwọn kókó pàtàkì bó ṣe yẹ sábà máa ń gbé àkọsílẹ̀ tí a bá ń kà látinú Bíbélì yọ. Irú ìtẹnumọ́ bẹ́ẹ̀ lè mú kí kíka àwọn ìpínrọ̀ túbọ̀ nítumọ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tàbí ní ìpàdé ìjọ. Ó sì ṣe pàtàkì pàápàá nígbà táa bá ń ka àsọyé tó jẹ́ ìwé kíkà, bó ṣe máa ń rí nínú àwọn àsọyé kan ní àpéjọ àgbègbè wa.
Bí O Ṣe Lè Ṣe É. Ní ilé ẹ̀kọ́, wọ́n lè yan ibì kan fún ọ láti kà nínú Bíbélì. Kí ló yẹ kí o tẹnu mọ́? Bí àkójọ ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ kà bá dá lórí kókó pàtàkì kan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan, á dára pé kí o jẹ́ kí nǹkan yẹn hàn kedere.
Yálà apá tó o fẹ́ kà jẹ́ ewì tàbí àlàyé, òwe tàbí ìtàn, àwọn olùgbọ́ rẹ yóò jàǹfààní tó o bá kà á dáadáa. (2 Tím. 3:16, 17) Láti lè ṣe èyí, o gbọ́dọ̀ ronú nípa ibi tó o fẹ́ kà àtàwọn tó o fẹ́ kà á fún.
Bó o bá fẹ́ ka ìwé sókè níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tàbí ní ìpàdé ìjọ, kí làwọn kókó pàtàkì tó yẹ kó o tẹnu mọ́? Àwọn ìdáhùn sí ìbéèrè tó wà níbẹ̀ ni kó o kà sí àwọn kókó pàtàkì wọ̀nyẹn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, tẹnu mọ́ àwọn kókó tó jẹ mọ́ àkọlé kékeré tí àkójọ ọ̀rọ̀ náà wà lábẹ́ rẹ̀.
Tó o bá níṣẹ́ nínú ìjọ, kò yẹ kí o kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ sórí ìwé kó o wá máa kà á. Àmọ́ ṣá o, a máa ń pèsè ìwé kíkà fún àwọn àsọyé kan nígbà àpéjọ kó lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan náà la máa gbọ́ ní àwọn àpéjọ wa, ká sì sọ wọ́n lọ́nà kan náà. Kí olùbánisọ̀rọ̀ lè tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì nínú irú ìwé kíkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó kọ́kọ́ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àkójọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Kí làwọn kókó pàtàkì ibẹ̀? Ó yẹ kó lè dá wọn mọ̀. Kì í ṣe àwọn èrò tó bá kàn ṣáà ti ronú pé ó dùn mọ́ni ló ti di kókó pàtàkì. Ṣùgbọ́n àwọn kókó pàtàkì yìí jẹ́ lájorí èrò tí à ń fi àkójọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún fúnra rẹ̀ ṣàlàyé. Nígbà mìíràn, kókó pàtàkì tí a sọ ní gbólóhùn ṣókí la fi ń nasẹ̀ ìtàn tàbí àlàyé kan nínú àsọyé tó jẹ́ ìwé kíkà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀yìn tá a bá ti ṣàlàyé àwọn ẹ̀rí tó ti kókó pàtàkì kan lẹ́yìn ni gbólóhùn tó rinlẹ̀ yóò tó wáyé. Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá ti dá àwọn kókó wọ̀nyí mọ̀, ó yẹ kí ó fàlà sídìí wọn nínú ìwé tó fẹ́ kà. Wọn kì í sábà pọ̀, wọ́n lè má ju mẹ́rin tàbí márùn-ún lọ. Lẹ́yìn ìyẹn, ó ní láti fi kíkà rẹ̀ dánra wò gan-an débi pé àwọn tí yóò kà á fún yóò lè tètè dá wọn mọ̀. Ìwọ̀nyí gan-an ni kókó tó yẹ kó hàn gedegbe nínú àsọyé náà. Bí ó bá tẹnu mọ́ ibi tó yẹ nígbà tó bá ń ka àkójọ ọ̀rọ̀ ọ̀hún, á ṣeé ṣe láti lè tètè rántí àwọn kókó pàtàkì wọ̀nyẹn. Ohun tó yẹ kó jẹ olùbánisọ̀rọ̀ lógún nìyẹn.
Onírúurú ọ̀nà ni olùbánisọ̀rọ̀ lè gbà tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ láti lè mú kí àwọn olùgbọ́ dá àwọn kókó pàtàkì mọ̀. Ó lè lo ìtara tó túbọ̀ pọ̀ sí i, ó lè yára tàbí kó rọra sọ ọ́, ó lè yí ìwọ̀n ohùn tó ń lò láti fi bí nǹkan ṣe rí lára hàn padà, tàbí kí ó fara ṣàpèjúwe lọ́nà tó yẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.