MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìfẹ́ Ni A Fi Ń Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀—Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Òtítọ́
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Bíi ti Jésù, àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí òtítọ́ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé. (Jo 18:37) Láìka ti pé inú ayé tó kún fún irọ́ àti ìwà àìṣòdodo là ń gbé, a gbọ́dọ̀ máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́, ká máa sọ òtítọ́, ká sì máa ronú lórí ohun yòówù tí ó jẹ́ òtítọ́.—1Kọ 13:6; Flp 4:8.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Pinnu pé oò ní máa tẹ́tí sí òfófó àti pé oò ní máa ṣe òfófó.—1Tẹ 4:11
Má ṣe máa yọ̀ tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan
Àwọn ohun tó dáa tó sì ń fúnni níṣìírí ni kó o jẹ́ kó máa múnú rẹ dùn
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ NÍ ÌFẸ́ LÁÀÁRÍN ARA YÍN”—MÁA YỌ̀ PẸ̀LÚ ÒTÍTỌ́, KÌ Í ṢE LÓRÍ ÀÌṢÒDODO, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ọ̀nà wo ni Dámilọ́lá gbà “yọ̀ lórí àìṣòdodo”?
Báwo ni Àìná ṣe yí ìjíròrò òun àti Dámilọ́lá sí èyí tó ń gbéni ró?
Àwọn nǹkan tó dáa wo la lè sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́, kì í ṣe lórí àìṣòdodo