Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
OCTOBER 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 9-10
“Jésù Ń Bójú Tó Àwọn Àgùntàn Rẹ̀”
nwtsty àwòrán àti fídíò
Ọgbà Àgùntàn
Ọgbà àgùntàn jẹ́ ibi àkámọ́ tí wọ́n máa ń kó àwọn àgùntàn sí láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn olè àtàwọn ẹranko ẹhànnà. Inú ọgbà àgùntàn yìí làwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń kó agbo ẹran wọn sí lálẹ́. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọgbà àgùntàn kì í ní òrùlé, ó máa ń yàtọ̀ síra, ó sì máa ń tóbi jura. Òkúta ni wọ́n sábà máa ń fi ṣe odi yí i ká, tá á sì ní ẹnu ọ̀nà kan péré. (Nu 32:16; 1Sa 24:3; Sef 2:6) Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa gbígba “ẹnu ọ̀nà” ọgbà àgùntàn kan wọlé, èyí tí ó ní “olùṣọ́nà” kan. (Jo 10:1,3) Àwọn ọgbà àgùntàn kan wà fún gbogbo ìlú, oríṣiríṣi àwọn olùṣọ́ àgùntàn ló lè kó ẹran wọ́n wá sun ibẹ̀, olùṣọ́nà láá máa ṣọ́ àwọn àgùntàn yẹn. Tílẹ̀ bá mọ́, olùṣọ́nà máa ṣí ilẹ̀kùn káwọn olùṣọ́ àgùntàn lè kó ẹran wọn. Olùṣọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan máa pe agbo ẹran tiẹ̀, wọ́n á dá ohùn rẹ̀ mọ̀, wọ́n á sì jáde wá. (Jo 10:3-5) Jésù sọ̀rọ̀ nípa olùṣọ́ àgùntàn àti agbo ẹran láti ṣàpèjúwe bí òun ṣe ń bójú tó àwọn ọmọlẹ́yìn òun.—Jo 10:7-14.
Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni—“Ẹ Wà Lójúfò”
5 Ohun tó máa ń jẹ́ kí àwọn àgùntàn àti olùṣọ́ àgùntàn mọwọ́ ara wọn dáadáa ni pé olùṣọ́ àgùntàn máa ń mọ gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa àwọn àgùntàn rẹ̀, àwọn àgùntàn rẹ̀ náà sì máa ń fọkàn tán an. Wọ́n dá ohùn rẹ̀ mọ̀, wọ́n sì máa ń ṣègbọràn sí i. Jésù sọ pé: ‘Mo mọ àwọn àgùntàn mi, àwọn àgùntàn mi sì mọ̀ mí.’ Kì í ṣe ìmọ̀ oréfèé lásán ni Jésù ní nípa ìjọ. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “mọ̀” nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí “mímọ ẹnì kan ní àmọ̀dunjú.” Torí náà, Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà mọ àwọn àgùntàn rẹ̀ níkọ̀ọ̀kan. Ó mọ ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn nílò, ó mọ àìlera wọn, ó sì mọ ohun tí agbára wọ́n gbé. Kódà, Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa yìí ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn àgùntàn rẹ̀. Àwọn àgùntàn náà mọ olùṣọ́ àgùntàn wọn dunjú wọ́n sì fọkàn tán an gẹ́gẹ́ bí aṣáájú wọn.
“Kì Í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
17 Ọ̀gbẹ́ni George A. Smith kọ ohun tó fojú ara rẹ̀ rí sínú ìwé kan tó pè ní The Historical Geography of the Holy Land, ó sọ pé: “Nígbà míì, ẹ̀gbẹ́ ọ̀kan lára àwọn kànga tó wà nílẹ̀ Jùdíà la ti máa ń sinmi ọ̀sán. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn bíi mẹ́ta tàbí mẹ́rin máa ń kó agbo àgùntàn wọn wá síbẹ̀. Gbogbo àwọn àgùntàn náà á dà pọ̀ mọ́ra wọn, a sì máa ń rò ó pé báwo ni darandaran kọ̀ọ̀kan á ṣe dá àgùntàn tiẹ̀ mọ̀. Àmọ́ táwọn àgùntàn náà bá ti mu omi tán, tí wọ́n sì ti ṣeré tán, darandaran kọ̀ọ̀kan á gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nínú àfonífojì náà. Kálukú wọ́n á wá máa pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ bó ṣe máa ń pè wọ́n. Àwọn àgùntàn darandaran kọ̀ọ̀kan á sì máa lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n á tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe tò wá sídìí omi tẹ́lẹ̀.” Kò jọ pé àpèjúwe mìíràn wà tó tún dáa ju èyí tí Jésù lò yìí láti fa kókó tó fẹ́ mú jáde yọ. Ìyẹn ni pé tá a bá gba àwọn ohun tó ń kọ́ wa tá a sì fi wọ́n sílò, tá a tún jẹ́ kó máa darí wa, nígbà náà, a lè sọ pé a wà lábẹ́ àbójútó “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” náà.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 10:16
mú wá: Tàbí “darí.” Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà aʹgo lè túmọ̀ sí “mú wá (wọlé)” tàbí “láti darí,” ó sinmi lórí àyíká ọ̀rọ̀. Ìwé àfọwọ́kọ Gíríìkì kan tí wọ́n kọ ní nǹkan bí ọdún 200 Sànmánì Kristẹni náà lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó jọ ọ́ (sy·naʹgo), èyí tí wọ́n sábà máa ń túmọ̀ sí “láti kó jọpọ̀.” Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà ni Jésù, ó máa ń kó àwọn àgùntàn rẹ̀ jọpọ̀, ó máa ń tọ́ wọn sọ́nà, ó ń dáàbò bò wọ́n, ó sì máa ń bọ́ àwọn àgùntàn tó wà nínú ọ̀wọ́ yìí (tá a tún pè ní “agbo kékeré” nínú Lk 12:32) àti àwọn àgùntàn mìíràn. Gbogbo wọn para pọ̀ jẹ́ agbo kan, lábẹ́ olùṣọ́ àgùntàn kan. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé ìṣọ̀kan máa wà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 9:38
wárí fún un: Tàbí “wólẹ̀ fún un; dọ̀bálẹ̀ fún un; júbà rẹ̀.” Níbi tí wọ́n bá ti lo ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà pro·sky·neʹo láti tọ́ka sí ìjọsìn tí ẹnì kan ṣe sí òrìṣà tàbí ọlọ́run kan, wọ́n sábà máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí “láti jọ́sìn.” (Mt 4:10; Lk 4:8) Ní àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ọkùnrin tó ti jẹ́ afọ́jú láti kékeré tí Jésù wò sàn gbà pé Ọlọ́run ló rán Jésù wá sáyé, ìdí nìyẹn tó fi wárí fún un. Ó mọ̀ dáadáa pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run tàbí òrìṣà kan, ó mọ̀ pé òun ni “Ọmọ ènìyàn,” tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wá láti ọ̀run. (Jo 9:35) Nígbà tó wólẹ̀ fún Jésù, ṣe ló ṣe bí àwọn kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí àwọn náà wólẹ̀ nígbà tí wọ́n rí wòlíì, ọba tàbí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan. (1Sa 25:23, 24; 2Sa 14:4-7; 1Ọb 1:16; 2Ọb 4:36, 37) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó wárí fún Jésù ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé àwọn mọrírì bí Ọlọ́run ṣe fi nǹkan kan han àwọn tàbí pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 2:2; 8:2; 14:33; 15:25.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 10:22
Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́: Hanukkah (chanuk·kahʹ) ni wọ́n ń pe àjọyọ̀ yìí lédè Hébérù, tó túmọ̀ sí “Ìṣílé; Ìyàsímímọ́.” Ọjọ́ mẹ́jọ ni wọ́n fi ń ṣe àjọyọ̀ yìí, ó máa ń bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù Kísíléfì, èyí tó sún mọ́ ìgbà òtútù, (wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ìgbà òtútù nínú ẹsẹ yìí àti Àfikún 19) àjọyọ̀ yìí ni wọ́n sì máa ń fi rántí bí wọ́n ṣe tún tẹ́ńpìlì Jèhófà yà sí mímọ́ lọ́dún 165 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọba Síríà tó ń jẹ́ Antiochus IV Epiphanes fi hàn pé òun kórìíra Jèhófà, Ọlọ́run àwọn Júù, nípa bó ṣe sọ tẹ́ńpìlì Jèhófà di ẹlẹ́gbin. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ́ pẹpẹ kan sórí pẹpẹ ńlá, níbi tí wọ́n ti máa ń rú ọrẹ ẹbọ sísun tẹ́lẹ̀. Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] oṣù Kísíléfì, ọdún 168 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Antiochus fi ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ, kó lè kó ẹ̀gbin bá tẹ́ńpìlì Jèhófà pátápátá, ó tún ní kí wọ́n wọ́n omitoro ẹlẹ́dẹ̀ yíká pẹpẹ náà. Ó sun àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì, ó wó ilé àwọn àlùfáà, ó sì gbé pẹpẹ oníwúrà, tábìlì àkàrà ìfihàn àti ọ̀pá fìtílà lọ. Ó wá tún tẹ́ńpìlì Jèhófà yà sí mímọ́ fún òòṣà Súúsì ti Olympus. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, Judas Maccabaeus gba ìlú Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì pa dà. Lẹ́yìn tí wọ́n wẹ tẹ́ńpìlì náà mọ́, wọ́n tún un yà sí mímọ́ ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] oṣù Kísíléfì, ọdún 165 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ní ọjọ́ tó pé ọdún mẹ́ta géérégé tí Antiochus sọ pẹpẹ Jèhófà di ẹlẹ́gbin nígbà tó rúbọ sí òòṣà Súúsì lórí rẹ̀. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ ọrẹ ẹbọ sísun tí wọ́n máa ń rú sí Jèhófà lójoojúmọ́ pa dà. Kò sí ibi kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó sọ pé Jèhófà ló mú kí Judas Maccabaeus ṣẹ́gun, kó sì mú tẹ́ńpìlì pa dà bọ̀ sípò. Àmọ́, Jèhófà ti lo àwọn ọkùnrin láti orílẹ̀-èdè míì, irú bi Kírúsì ti Páṣíà, láti ṣe àwọn nǹkan kan, kí ohun tó fẹ́ lórí ìjọsìn rẹ̀ lè ṣẹ. (Ais 45:1) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti parí èrò pé Jèhófà lè lo ọkùnrin tó jólóòótọ́ láti mú ètè Rẹ̀ ṣẹ. Ìwé Mímọ́ fi hàn pé tẹ́ńpìlì gbọ́dọ̀ wà nípò tó dáa, kí nǹkan sì máa lọ bó ṣe yẹ níbẹ̀, kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti ìrúbọ rẹ̀ lè nímùúṣẹ. Bákan náà, ẹbọ táwọn ọmọ Léfì máa ń rú gbọ́dọ̀ máa bá a lọ títí di àsìkò tí Mèsáyà máa wá rú ẹbọ tó ga jù, ìyẹn ẹ̀mí rẹ̀ tó fi lélẹ̀ nítorí àwa èèyàn. (Da 9:27; Jo 2:17; Heb 9:11-14) Kò sí àṣẹ tó sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa ṣe Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́. (Kol 2:16, 17) Síbẹ̀, Bíbélì ò sọ pé Jésù tàbí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dẹ́bi fún àwọn tó ń ṣe àjọyọ̀ yìí.
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 11-12
“Máa Tu Àwọn Míì Nínú Bí I Ti Jésù”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 11:24, 25
Mo mọ̀ pé yóò dìde: Màtá rò pé Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ní ọjọ́ ìkẹyìn. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 6:39.) Ìgbàgbọ́ tó ní nínú ẹ̀kọ́ yẹn lágbára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó hàn gbangba pé ẹ̀kọ́ nípa àjíǹde wà nínú Ìwé Mímọ́, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n ń pè ní àwọn Sadusí láyé ìgbà yẹn kò gbà pé àjíǹde máa wáyé. (Da 12:13; Mk 12:18) Lọ́wọ́ kejì, àwọn Farisí gbà gbọ́ pé ọkàn èèyàn kì í kú. Màtá mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ àjíǹde tí Jésù kọ́ wọn, ó sì ti rí bí Jésù ṣe jí àwọn òkú dìde, àmọ́ kò tíì rí èyí tí òkú rẹ̀ pẹ́ tó ti Lásárù.
Èmi ni àjíǹde àti ìyè: Ikú Jésù àti àjíǹde rẹ̀ ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó ti kú láti pa dà wà láàyè. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, Jèhófà fún un ní agbára láti jí òkú dìde àti láti fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 5:26.) Nínú Iṣi 1:18, Jésù pe ara rẹ̀ ní “alààyè,” ẹni tó “ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì lọ́wọ́.” Torí náà, Jésù ni ìrètí tí àwọn alààyè àti àwọn òkú ní. Ó ṣèlérí pé òun máa ṣí ibojì, òun sì máa fún àwọn tó ti kú ní ìyè, ìyẹn àwọn tó máa lọ sí ọ̀run láti bá a jọba àti àwọn tó máa wà láyé lábẹ́ ìjọba tí Jésù á máa dárí láti ọ̀run.—Jo 5:28,29; 2Pe 3:13.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 11:33-35
sunkún: Tàbí “ké.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “sunkún” sábà máa ń tọ́ka sí kéèyàn sunkún síta. Ọ̀rọ̀ ìṣe yẹn kan náà ni Bíbélì lò fún Jésù nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù.—Lk 19:41.
kérora . . . ó sì dààmú: Bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí pa pọ̀ nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì jẹ́ ká rí i bí ìmọ̀lára Jésù ṣe lágbára tó torí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tá a tú sí “kérora” (em·bri·maʹo·mai) máa ń tọ́ka sí ìmọ̀lára tó jinlẹ̀ gan-an, àmọ́ nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ṣe ló ń jẹ́ ká rí bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù ṣe dùn ún tó, tó sì wá kérora. Ní tààràtà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “dààmú” (ta·rasʹso) sábà máa ń tọ́ka sí kéèyàn kún fún ṣìbáṣìbo tàbí kí ọkàn èèyàn dà rú. Ọ̀mọ̀wé kan tiẹ̀ sọ pé, ní àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ohun tó túmọ̀ sí ni “kéèyàn ní ìdàrúdàpọ̀ inú lọ́hùn-ún; kéèyàn ní ìroragógó tàbí ìbànújẹ́ tó le gan-an.” Ọ̀rọ̀ ìṣe yìí náà ni Bíbélì lò nínú Jo 13:21 nígbà tó ń ṣàlàyé ìmọ̀lára Jésù nígbà tó rántí pé Júdásì ló máa da òun.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 11:35.
nínú ẹ̀mí: Ó ní láti jẹ́ pé wọ́n lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà pneuʹma láti fi ṣàpèjúwe ohun kan tó ń sún èèyàn láti ṣe nǹkan kan láti inú ọkàn ìṣàpẹẹrẹ, táá sì mú kí ẹnì náà sọ̀rọ̀ tàbí ṣe nǹkan lọ́nà kan ṣá.
bẹ̀rẹ̀ sí da omijé: Ọ̀rọ̀ ìṣe tí Bíbélì lò níbí yìí (da·kryʹo) náà ni ọ̀rọ̀ orúkọ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “omijé,” ọ̀rọ̀ yìí ni Bíbélì tún lò nínú àwọn ẹsẹ yìí Lk 7:38; Iṣe 20:19,31; Heb 5:7; Iṣi 7:17; 21:4. Ó ń tọ́ka sí omi tó ń jáde lójú ẹni tó ń sunkún. Ibí nìkan ni wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ ìṣe yìí nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ó sì yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò nínú Jo 11:33 (wo àlàyé ọ̀rọ̀) níbi tó ti ń sọ̀rọ̀ nípa ẹkún Màríà àti àwọn Júù. Jésù mọ̀ pé òun máa jí Lásárù dìde, àmọ́ ó dùn ún gidi gan-an pé ẹdùn ọkàn ti bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Ìfẹ́ àtọkànwá tó ní àti bó ṣe káàánú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí ló sún un láti da omijé níwájú àwọn èèyàn. Ìtàn yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé Jésù mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tó pàdánù èèyàn wọn nínú ikú, èyí tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 11:49
àlùfáà àgbà: Nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ò sí lábẹ́ orílẹ̀-èdè míì, ẹni tó bá jẹ́ àlùfáà àgbà máa wà nípò yẹn títí tó máa fi kú. (Nu 35:25) Àmọ́ nígbà tí Ìjọba ilẹ̀ Róòmù ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, àwọn tí wọ́n bá yàn sípò àṣẹ lè yan àlùfáà àgbà, wọ́n sì lè yọ ọ́ nípò. Àwọn ará ilẹ̀ Róòmù ló fi Káyáfà sípò àlùfáà àgbà, ó mọ bí èèyàn ṣe ń ṣojú àwọn èèyàn dáadáa, ó sì pẹ́ ní ipò yẹn ju àwọn tó ti wà ní ipò yẹn ṣáájú rẹ̀. Nǹkan bí ọdún 18 Sànmánì Kristẹni ló dé ipò àlùfáà àgbà, ó sì wà níbẹ̀ títí di nǹkan bí ọdún 36 Sànmánì Kristẹni. Nígbà tí Jòhánù sọ pé Káyáfà ni àlùfáà àgbà ní ọdún yẹn, ìyẹn ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó ní láti jẹ́ pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé Káyáfà ló wà ní ipò àlùfáà àgbà ní ọdún mánigbàgbé tí wọ́n ṣe ikú pa Jésù.—Wo Àfikún 16 láti mọ ibi tó ṣeé ṣe kí ilé Káyáfà wà.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 12:42
àwọn olùṣàkóso: Ó ní láti jẹ́ pé àwọn tó wà ní Sànhẹ́dírìn ìyẹn ilé ẹjọ́ àwọn Júù ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “àwọn olùṣàkóso” ń tọ́ka sí. Bíbélì lo ọ̀rọ̀ yẹn nínú Jo 3:1 nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Nikodémù tó jẹ́ mẹ́ńbà ilé ẹjọ́ yẹn.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 3:1.
lé wọn jáde kúrò nínú sínágọ́gù: Tàbí “yọ kúrò ní sínágọ́gù.” Ẹsẹ yìí àti Jo 12:42 àti 16:2 nìkan ni wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà a·po·sy·naʹgo·gos tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ajúwe. Tí wọ́n bá yọ ẹnìkan ní ẹgbẹ́ yìí, wọn ò ní bá a sọ̀rọ̀ mọ́, wọn ò sì ní báa da nǹkan pọ̀. Ọrọ̀ ajé máa dẹnu kọlẹ̀ fún ẹni náà àti ìdílé rẹ̀, torí pé àwọn Júù míì ò ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú wọn mọ́. Lóòótọ́, ibi tí wọ́n ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ni sínágọ́gù jẹ́, àmọ́ wọ́n tún máa ń lò ó fún ilé ẹjọ́ àdúgbò tó láṣẹ láti fìyà jẹ ẹni tó bá ṣẹ̀, wọ́n lè ní kí wọ́n na ẹni náà lẹ́gba tàbí kí wọ́n fi àwọn àǹfààní kan du ẹni náà.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 10:17.
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 13-14
“Mo Fi Àwòṣe Lélẹ̀ fún Yín”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 13:5
wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn: Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, sálúbàtà ni wọ́n sábà máa ń wọ̀. Bàtà pẹlẹbẹ tí wọ́n kàn fi okùn so ìtẹ̀lẹ̀ bàtà mọ́ àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọrùn ẹsẹ̀ ni, torí náà, ẹsẹ̀ ẹni tó ń rin ìrìn àjò máa dọ̀tí torí ekuru àti ẹrọ̀fọ̀ ojú ọ̀nà. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ àṣà wọn láti máa bọ́ bàtà tí wọ́n bá fẹ́ wọ ilé kan, ẹni tó bá sì mọ aájò àlejò ṣe máa rí i dájú pé òun ṣètò bí wọ́n ṣe máa fọ ẹsẹ̀ àwọn àlejò. Bíbélì mẹ́nu ba àṣà yìí láwọn ibi mélòó kan. (Jẹ 18:4, 5; 24:32; 1Sa 25:41; Lk 7: 37, 38, 44) Nígbà tí Jésù wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ṣe ló fi àṣà yẹn kọ́ wọn pé kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ sin ara wọn.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 13:12-14
ó yẹ: Tàbí “àìgbọdọ̀máṣe.” Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tí Bíbélì lò níbí sábà máa ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ owó, ìyẹn “kéèyàn jẹ ẹnì kan lówó; kéèyàn jẹ ẹnì kan ní nǹkan.” (Mt 18:28, 30, 34; Lk 16:5, 7) Wọ́n lò ó ní ibí àti àwọn àyíká ọ̀rọ̀ míì lọ́nà tó tún gbòòrò, ìyẹn ni pé ó túmọ̀ sí ohun kan tó jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe tàbí ohun kan tó di dandan fúnni láti ṣe.—1Jo 3:16; 4:11; 3Jo 8.
Ọkùnrin Títóbilọ́lá Jù Lọ Ṣe Iṣẹ́ Rírẹlẹ̀
Nípa wíwẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, Jésù pèsè ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tó lágbára nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ní tòótọ́, kò yẹ kí àwọn Kristẹni máa ronú pé àwọn ṣe pàtàkì dépò pé ṣe ló yẹ kí àwọn ẹlòmíràn máa sìn wọ́n nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ kí wọ́n máa jà kìràkìtà torí àtidé ipò ọlá àti iyì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀, ẹni tó “wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù múra tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ rírẹlẹ̀ jù lọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní kejì.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 14:6
Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè: Jésù ni ọ̀nà torí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nìkan la lè gbà láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà. Òun tún “ni ọ̀nà” kan ṣoṣo tí aráyé lè gbà bá Ọlọ́run rẹ́. (Jo 16:23; Ro 5:8) Jésù ni òtítọ́ torí pé ó máa ń sọ òtítọ́, ìgbésí ayé rẹ̀ sì jẹ́rìí sí òtítọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ló mú ṣẹ, ìyẹn sì ṣàfihàn ipa pàtàkì tó máa kó láti mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ. (Jo 1:14; Iṣi 19:10) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn di “ ‘bẹ́ẹ̀ ni’ [tàbí nímùúṣẹ] nípasẹ̀ rẹ̀.” (2Kọ 1:20) Jésù tún ni ìyè torí pé nípasẹ̀ ìràpadà, ó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún aráyé láti ní “ìyè tòótọ́,” ìyẹn, “ìyè àìnípẹ̀kun.” (1Ti 6:12, 19; Ef 1:7; 1Jo 1:7) Ó tún máa jẹ́ “ìyè” fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tó máa jíǹde, tó sì máa wà nínú Párádísè títí láé.—Jo 5:28, 29.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 14:12
àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí: Kì í ṣe ohun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe iṣẹ́ ìyanu tó pọ̀ ju tòun lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù ló ń sọ, ó ń sọ̀rọ̀ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù wọn ṣe máa gbòòrò ju ti òun lọ, ìyẹn sì fi hàn pé Jésù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa wàásù ní àwọn ibi tí òun fúnra rẹ̀ kò dé, wọ́n máa wàásù fún èèyàn púpọ̀, wọ́n sì máa pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà ju Jésù lọ. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ jẹ́ kó ṣe kedere pé ó fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa bá iṣẹ́ náà lọ.
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 15-17
“Ẹ Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 15:19
ayé: Nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà koʹsmos ń tọ́ka sí aráyé, ìyẹn àwọn aláìgbọràn tó ti ya ara wọn sọ́tọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ò sí lára wọn. Nínú gbogbo àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere, Jòhánù nìkan ló kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, níbi tí Jésù ti sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kì í ṣe apá kan ayé tàbí wọn kì í ṣe ti ayé yìí. Jésù tún sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ẹ̀ẹ̀mejì nígbà tó ń gbàdúrà tó gbà kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.—Jo 17:14, 16.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 15:21
ní tìtorí orúkọ mi: Nínú Bíbélì, àwọn ìgbà míì wà tí ọ̀rọ̀ náà “orúkọ” máa ń dúró fún ẹni tó ń jẹ́ orúkọ náà, ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ọ́ sí àti gbogbo ohun tí ẹni náà jẹ́. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 6:9.) Ní ti orúkọ Jésù, orúkọ rẹ̀ dúró fún ọlá àṣẹ́ tó ní àti ipò tí Baba rẹ̀ gbé e sí. (Mt 28:18; Flp 2:9, 10; Heb 1:3, 4) Jésù tún ṣàlàyé ìdí tí àwọn èèyàn ayé á fi máa ṣe gbogbo nǹkan tí kò dáa sí àwọn ọmọlẹ́yìn òun: nítorí wọn kò mọ ẹni tí ó rán òun. Tí wọ́n bá mọ Ọlọ́run, èyí máa jẹ́ kí wọ́n lóye, kí wọ́n sì mọ ohun tí orúkọ Jésù dúró fún. (Iṣe 4:12) Èyí kan ipò tí Jésù wà, ìyẹn Alákòóso tí Ọlọ́run yàn, Ọba àwọn ọba, tó yẹ kí gbogbo èèyàn máa forí balẹ̀ fún kí wọ́n lè rí ìyè.—Jo 17:3; Iṣi 19:11-16; fi wé Sm 2:7-12.
it-1 516
Ìgboyà
Gbogbo Kristẹni ló nílò ìgboyà kí ìwà àti ìṣe ayé tó ti kẹ̀yìn sí Jèhófà Ọlọ́run yìí má bàa ràn wọ́n, kí wọ́n sì lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láìka bí ayé ṣe máa kórìíra wọn sí. Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nínú ayé, ẹ óò máa ní ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jo 16:33) Ọmọ Ọlọ́run kò jẹ́ kí ayé yìí kó èèràn ran òun, àmọ́ ó ṣẹ́gun ayé bí kò ṣe fara wé ayé náà lọ́nàkọnà. Jésù ṣẹ́gun ayé, àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn jẹ́ fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, bí Jésù ṣe ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú mú kí àwa náà ní ìgboyà tá a nílò láti lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ká má sì fara wé ayé yìí lọ́nàkọnà, ká má bàa di ẹlẹ́gbin.—Jo 17:16.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 17:21-23
ọ̀kan: Tàbí “ní ìṣọ̀kan.” Jésù gbàdúrà pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun di “ọ̀kan,” kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ pọ̀ fún ète kan náà, bí òun àti Baba rẹ̀ ṣe jẹ́ “ọ̀kan,” kí wọ́n máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kí èrò wọn sì ṣọ̀kan. (Jo 17:22) Nínú 1Kọ 3:6-9, Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe pé irú ìṣọ̀kan yìí wà láàárín àwọn Kristẹni, bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ tí wọ́n sì ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́.—Wo 1Kọ 3:8 àti àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 10:30; 17:11.
ṣe wọ́n pé ní ọ̀kan: Tàbí “jẹ́ ọ̀kan ní gbogbo ọ̀nà.” Nínú ẹsẹ yìí, Jésù so ìṣọ̀kan yẹn mọ́ bí Baba ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Èyí sì wà níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Kol 3:14, tó sọ pé: “Ìfẹ́ . . . jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” Ìṣọ̀kan tí à ń sọ yìí ní ààlà. Kò túmọ̀ sí pé ìwà ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, ohun tí wọ́n mọ̀ ọ́ ṣe, ohun tí wọ́n fẹ́ràn àti ẹ̀rí ọkàn wọn máa rí bákan náà. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé, wọ́n máa jẹ́ ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ń gbé ṣe, ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni.—Ro 15:5, 6; 1Kọ 1:10; Ef 4:3; Flp 1:27.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 17:24
ìgbà pípilẹ̀ ayé: Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa “irú-ọmọ” nínú Heb 11:11, ó lo ọ̀rọ̀ náà “lóyún” fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “pípilẹ̀.” Bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “pípilẹ̀” nínú “ìgbà pípilẹ̀ ayé,” ó ní láti jẹ́ pé ṣe ló ń tọ́ka sí àwọn ọmọ tí Ádámù àti Éfà bí. Jésù mẹ́nu ba Ébẹ́lì nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “ìgbà pípilẹ̀ ayé,” ó ní láti jẹ́ pé òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà, òun sì ni ẹni àkọ́kọ́ tí a kọ orúkọ rẹ̀ “sínú àkájọ ìwé ìyè láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Lk 11:50, 51; Iṣi 17:8) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà sí Baba rẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé tipẹ́tipẹ́, ṣáájú kí Ádámù àti Éfà tó bímọ rárá ni Ọlọ́run ti nífẹ̀ẹ́ Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo.
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 29–NOVEMBER 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 18-19
“Jésù Jẹ́rìí sí Òtítọ́”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 18:37
jẹ́rìí sí: Bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “láti lè jẹ́rìí” (mar·ty·reʹo) àti “jẹ́rìí” (mar·ty·riʹa; marʹtys) ní ìtumọ̀ tó gbòòrò. Bíbélì lo ọ̀rọ̀ méjì yìí fún ẹni tó ń jẹ́rìí nípa ohun kan tó jẹ́ òkodoro, ó lè jẹ́ ohun tí ẹni náà mọ̀ dáadáa tàbí ohun tó ṣojú ẹni náà, àmọ́ ó tún lè túmọ̀ sí kéèyàn “kéde ọ̀rọ̀ kan, kó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ tàbí kó sọ̀rọ̀ dáadáa nípa rẹ̀.” Jésù kéde òtítọ́, ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ torí pé ó dáa lójú. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́, bí Jésù ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ̀ náà tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òtítọ́ ni àwọ́n àsọtẹ́lẹ̀ àti ìlérí Baba rẹ̀. (2Kọ 1:20) Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ ní kíkún nípa àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe nínú Ìjọba rẹ̀, àti ẹni tó máa jẹ́ Ọba Ìjọba náà, ìyẹn Mèsáyà. Nígbà tí Jésù wà ní ayé, títí dìgbà tó fi kú ikú ìrúbọ, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nípa rẹ̀ ló ṣẹ, títí kan àwọn ohun tó wà nínú májẹ̀mú Òfin tó ń tọ́ka sí Jésù. (Kol 2:16, 17; Heb 10:1) Torí náà, a lè sọ pé Jésù ‘jẹ́rìí sí òtítọ́’ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe.
òtítọ́: Kì í ṣe gbogbo nǹkan tó jẹ́ òtítọ́ ni Jésù ń sọ níbí, ohun tó ń tọ́ka sí ni òtítọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe. Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe ni pé Jésù ìyẹn “ọmọkùnrin Dáfídì,” máa di Àlùfáà Àgbà àti Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Mt 1:1) Jésù ṣàlàyé pé olórí ìdí tí òun fi wá sí ayé ni láti kéde òtítọ́ nípa Ìjọba yẹn fún aráyé. Àwọ́n áńgẹ́lì náà kéde irú ohun tó jọ èyí kí wọ́n tó bí Jésù àti nígbà tí wọ́n bí Jésù sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà ìlú tí wọ́n bí Dáfídì sí.—Lk 1:32, 33; 2:10-14.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 18:38a
Kí ni òtítọ́?: Ó ní láti jẹ́ pé gbogbo ohun tó jẹ́ òtítọ́ ni Pílátù ń béèrè, kì í ṣe ọ̀rọ̀ “òtítọ́” tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán. (Jo 18:37) Ká sọ pé lóòótọ́ ni Pílátù fẹ́ mọ̀ ni, ó dájú pé Jésù máa dá a lóhùn. Pílátù fúnra rẹ̀ ò fẹ́ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, ṣe ló kàn fẹ́ bẹnu àtẹ́ lu ohun tí Jésù sọ, bí ẹni sọ pé, “Òtítọ́? Kí ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀? Kò sóhun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀!” Kódà Pílátù ò dúró gbọ́ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, ṣe ló kàn jáde lọ bá àwọ́n Júù.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 19:30
ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Tàbí “ó gbẹ́mìí mì; kò mí mọ́.” Ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí” (ní Gíríìkì, pneuʹma) níbí lè máa tọ́ka sí “èémí” tàbí “ẹ̀mí ìyè.” Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà ek·pneʹo (ní tààràtà, ó túmọ̀ sí “láti mí jáde”) sábà máa ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ yìí nínú àkọsílẹ̀ tó wà nínú Mk 15:37 àti Lk 23:46 (níbi tí wọ́n ti pè é ní “gbẹ́mìí mì” tàbí nínú àwọn ọ̀rọ̀ àfidípò náà “kú” tó wà nínú àlàyé ọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ yẹn). Àwọn kan gbà pé bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà “jọ̀wọ́” túmọ̀ sí pé ṣe ni Jésù mọ̀ọ́mọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kó bàa lè kú, nítorí pé ó ti ṣe ohun gbogbo parí. Ó fínnúfíndọ̀ “tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú.”—Ais 53:12; Jo 10:11.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 19:31
ọjọ́ Sábáàtì yẹn jẹ́ ọjọ́ ńlá: Sábáàtì ni Nísàn 15, ọjọ́ tó tẹ̀ lé Ìrékọjá, láìka ọjọ́ tí déètì yẹn bá bọ́ sí nínú ọ̀sẹ̀. (Le 23:5-7) Nígbà tí irú Sábáàtì yìí bá bọ́ sí ọjọ́ kan náà pẹ̀lú Sábáàtì gangan (ìyẹn ọjọ́ keje nínú kàlẹ́ńdà àwọn Júù, tó máa ń bẹ̀rẹ̀ látìgbà tí oòrùn wọ̀ ní ọjọ́ Friday sí ìgbà tí oòrùn wọ̀ ní Saturday), Sábáàtì “ńlá” ni wọ́n máa ń pè é. Irú sábáàtì yìí ló tẹ̀ lé ọjọ́ Friday tí Jésù kú. Láàárín ọdún 29 sí ọdún 35 Sànmánì Kristẹni, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni nìkan ni Nísàn 14 bọ́ sí ọjọ́ Friday. Ẹ̀rí yìí tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́, Nísàn 14 ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ni Jésù kú.
Bíbélì Kíkà