January 14-20
ÌṢE 23-24
Orin 148 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Wọ́n Fẹ̀sùn Kan Pọ́ọ̀lù Pé Alákòóbá Ni àti Pé Ó Ń Ru Ìdìtẹ̀ Sókè”: (10 min.)
Iṣe 23:12, 16—Wọ́n fẹ́ pa Pọ́ọ̀lù, àmọ́ wọn ò ṣe àṣeyọrí (bt 191 ¶5-6)
Iṣe 24:2, 5, 6—Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan tó ń jẹ́ Tẹ́túlọ́sì fẹ̀sùn èké kan Pọ́ọ̀lù lọ́dọ̀ gómìnà ìjọba Róòmù (bt 192 ¶10)
Iṣe 24:10-21—Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì fìgboyà wàásù fún wọn (bt 193-194 ¶13-14)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Iṣe 23:6—Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi pe ara rẹ̀ ní Farisí? (“Farisí ni mí” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 23:6, nwtsty)
Iṣe 24:24, 27—Ta ni Dùrùsílà? (“Dùrùsílà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 24:24, nwtsty)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Iṣe 23:1-15 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 1)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 2)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 3)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdọọdún: (15 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Kọ́kọ́ ka lẹ́tà látọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdọọdún, lẹ́yìn náà fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde kan tó o ti yàn, kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 1 ¶18-24
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 128 àti Àdúrà