Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JANUARY 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 21-22
“Kí Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ”
“Kí Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ”
15 Láàárín àkókò tí Pọ́ọ̀lù fi wà lọ́dọ̀ Fílípì, ó tún gbàlejò Ágábù, ẹni táwọn ará bọ̀wọ̀ fún. Àwọn tó péjọ sílé Fílípì mọ̀ pé wòlíì ni Ágábù, ó ti sọ tẹ́lẹ̀ nígbà kan rí nípa ìyàn ńlá kan tó mú nígbà ìṣàkóso Kíláúdíù. (Ìṣe 11:27, 28) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti máa rò pé: ‘Kí ni Ágábù wá ṣe? Iṣẹ́ wo ló fẹ́ jẹ́?’ Wọ́n ń wò ó bó ṣe mú àmùrè Pọ́ọ̀lù, ìyẹn aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ kan tó dà bí ìgbànú tí wọ́n máa ń tọ́jú owó àtàwọn nǹkan míì sí. Ágábù fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ náà so ọwọ́ àti ẹsẹ ara rẹ̀. Ó wá sọ ọ̀rọ̀ kan tó gbàrònú, ó ní: “Báyìí ni ẹ̀mí mímọ́ wí, ‘Ọkùnrin tí àmùrè yìí jẹ́ tirẹ̀ ni àwọn Júù yóò dè lọ́nà yìí ní Jerúsálẹ́mù, wọn yóò sì fi í lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́.’ ”—Ìṣe 21:11.
16 Àsọtẹ́lẹ̀ náà fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Pọ́ọ̀lù máa lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ó tún fi hàn pé, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láàárín òun àtàwọn Júù tó wà níbẹ̀ máa mú kí wọ́n fà á “lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́.” Àsọtẹ́lẹ̀ náà wọ àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ lọ́kàn. Lúùkù sọ pé: “Wàyí o, nígbà tí a gbọ́ èyí, àti àwa àti àwọn ará ibẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un láti má gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: ‘Kí ni ẹ ń ṣe nípa sísunkún, tí ẹ sì ń sọ mí di aláìlera ní ọkàn-àyà? Kí ó dá yín lójú pé, mo ti múra tán, kì í ṣe fún dídè nìkan ni, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ní Jerúsálẹ́mù nítorí orúkọ Jésù Olúwa.’ ”—Ìṣe 21:12, 13.
“Kí Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ”
17 Fojú inú wo bí ibẹ̀ á ṣe rí lọ́jọ́ náà. Àwọn ará, tó fi mọ́ Lúùkù, pàrọwà fún Pọ́ọ̀lù pé kó má lọ. Àwọn kan ń sunkún. Bí àwọn èèyàn náà ṣe fi hàn pé àwọn bìkítà nípa Pọ́ọ̀lù wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó wá sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù pé wọ́n ń sọ òun di “aláìlera ní ọkàn-àyà,” tàbí bí Bíbélì kan ṣe túmọ̀ èdè Gíríìkì náà, wọ́n ń “kó ìpayà bá a.” Síbẹ̀ ó dúró lórí ìpinnu ẹ̀, bó ṣe ṣe nígbà tó pàdé àwọn ará ní Tírè, kò sì jẹ́ kí àrọwà tàbí ẹkún wọn mú òun yẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kó lọ síbẹ̀ fún wọn. Ẹ ò rí i pé ìgboyà àti ìpinnu tó lágbára lèyí jẹ́! Bíi ti Jésù, Pọ́ọ̀lù náà pinnu láti lọ sí Jerúsálẹ́mù. (Héb. 12:2) Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù fẹ́ láti di ajẹ́rìíkú o, àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa kà á sí àǹfààní pé òun kú gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi Jésù.
“Kí Ìfẹ́ Jèhófà Ṣẹ”
18 Kí wá làwọn ará ṣe? Ká má fọ̀rọ̀ gùn, wọ́n fara mọ́ ìpinnu ẹ̀. A kà pé: “Nígbà tí a kò lè mú kí ó pa èrò rẹ̀ dà, a gbà láìjanpata pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: ‘Kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.’ ” (Ìṣe 21:14) Àwọn tó gbìyànjú láti yí Pọ́ọ̀lù lèrò pa dà pé kó má lọ sí Jerúsálẹ́mù ò sọ pé ohun táwọn sọ labẹ gbọ́dọ̀ gé. Wọ́n fara mọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, wọ́n gbà pé kí ìfẹ́ Jèhófà di ṣíṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò tó máa rìn kẹ́yìn kó tó kú nìyẹn o. Ó máa rọrùn fún Pọ́ọ̀lù báwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ ò bá gbìyànjú láti yí i lérò pa dà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Ẹ Gbọ́ Ìgbèjà Mi”
10 Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tí wọ́n ṣì ń fẹ́ láti máa tẹ̀ lé àwọn kan lára àṣà àwọn Júù, irú bíi ṣíṣàì ṣe iṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì tàbí títa kété sáwọn oúnjẹ kan. (Róòmù 14:1-6) Kò sì fi òfin kankan lélẹ̀ nípa ìdádọ̀dọ́. Kódà, ó dádọ̀dọ́ fún Tímótì káwọn Júù má bàa máa fura sí i, torí pé Gíríìkì ni bàbá rẹ̀. (Ìṣe 16:3) Ìpinnu ara ẹni ní ìdádọ̀dọ́ jẹ́. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Gálátíà pé: “Ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́ kò ní ìníyelórí kankan, bí kò ṣe ìgbàgbọ́ tí ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìfẹ́.” (Gál. 5:6) Àmọ́ ṣá o, bí ẹnì kan bá dádọ̀dọ́ torí àtilè wà lábẹ́ Òfin tàbí tó bá ń sọ pé dandan ni kéèyàn dádọ̀dọ́ kó bàa lè rójú rere Jèhófà, ńṣe nìyẹn á fi hàn pé onítọ̀hún ò nígbàgbọ́.
11 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àhesọ táwọn èèyàn yẹn sọ kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, kò tíì tán lọ́kàn wọn síbẹ̀. Èyí ló mú kí àwọn àgbà ọkùnrin náà sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ọkùnrin mẹ́rin wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti fi ara wọn jẹ́jẹ̀ẹ́. Mú àwọn ọkùnrin yìí dání, kí o sì wẹ ara rẹ mọ́ lọ́nà ayẹyẹ pẹ̀lú wọn, kí o sì bójú tó [ìnáwó] wọn, kí wọ́n lè fá orí wọn. Nítorí náà, gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé kò sí nǹkan kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ tí a sọ fún wọn nípa rẹ, ṣùgbọ́n pé ìwọ ń rìn létòletò, pé ìwọ alára pẹ̀lú ń pa Òfin mọ́.”—Ìṣe 21:23, 24.
12 Ó ṣeé ṣe fun Pọ́ọ̀lù láti sọ pé, kì í ṣe ọ̀rọ̀ àhesọ tí wọ́n sọ nípa òun gan-an ló fa wàhálà, bí kò ṣe Òfin Mósè táwọn Júù onígbàgbọ́ yẹn rin kinkin mọ́. Àmọ́, kò fẹ́ rin kinkin mọ́ èrò tiẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti ta ko àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀. Ó ti kọ́kọ́ kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Fún àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin mo dà bí ẹni tí ń bẹ lábẹ́ òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi kò sí lábẹ́ òfin, kí n lè jèrè àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin.” (1 Kọ́r. 9:20) Torí náà, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ “dà bí ẹni tí ń bẹ lábẹ́ òfin.” Àpẹẹrẹ rere lohun tó ṣe yìí jẹ́ fún wa lónìí, káwa náà máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà, ká má ṣe máa rin kinkin mọ́ èrò wa.—Héb. 13:17.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 22:16
wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù nípa kíké tí o bá ń ké pe orúkọ rẹ̀: Tàbí “wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù kó o sì ké pe orúkọ rẹ̀.” Ẹni tó bá fẹ́ wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nù gbọ́dọ̀ ké pe orúkọ Jésù kì í ṣe pé kó kàn ṣèrìbọmi nìkan. Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé kẹ́ni náà ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, kó sì máa hùwà tó yẹ Kristẹni.—Iṣe 10:43; Jak 2:14, 18.
Bíbélì Kíkà
JANUARY 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 23-24
“Wọ́n Fẹ̀sùn Kan Pọ́ọ̀lù Pé Alákòóbá Ni àti Pé Ó Ń Ru Ìdìtẹ̀ Sókè”
“Jẹ́ Onígboyà Gidi Gan-an!”
5 Ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù rí gbà yìí bọ́ sákòókò gan-an ni. Lọ́jọ́ kejì, ó ju ogójì [40] ọkùnrin lọ tí wọ́n “di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun, wọ́n sì fi ègún de ara wọn, pé àwọn kò ní jẹ tàbí mu títí àwọn yóò fi pa Pọ́ọ̀lù.” “Tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun àfìbúradè” yìí fi hàn pé àwọn Júù yẹn ti pinnu láti pa Pọ́ọ̀lù. Lójú wọn, bí wọn ò bá fi rí Pọ́ọ̀lù pa pẹ́nrẹ́n, ègún ló jẹ́. (Ìṣe 23:12-15) Àwọn olórí àlùfáà fọwọ́ sí ètò táwọn èèyàn náà ṣe láti mú Pọ́ọ̀lù pa dà wá sílé ẹjọ́ Sànhẹ́dírìn kí wọ́n sì bi í ní ìbéèrè síwájú sí i, kí wọ́n lè rí àrídájú àwọn ọ̀ràn kan nípa rẹ̀ dáadáa. Àmọ́ ńṣe làwọn tó di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun yẹn fẹ́ dènà de Pọ́ọ̀lù kí wọ́n lè pa á.
6 Ó ṣẹlẹ̀ pé ọmọ ẹ̀gbọ́n Pọ́ọ̀lù kan gbọ́ nípa tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun náà ó sì sọ fún Pọ́ọ̀lù. Pọ́ọ̀lù wá ní kó lọ sọ fún Kíláúdíù Lísíà, ọ̀gágun àwọn ará Róòmù. (Ìṣe 23:16-22) Ó dájú pé Jèhófà fẹ́ràn irú àwọn ọ̀dọ́ tó nígboyà bí ọmọ ẹ̀gbọ́n Pọ́ọ̀lù tí Bíbélì ò sọ orúkọ rẹ̀ yìí, tí wọ́n ń fi ire àwọn èèyàn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, tí wọ́n sì ń fi ìṣòtítọ́ ṣe ohunkóhun tí wọ́n bá lè ṣe láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú.
“Jẹ́ Onígboyà Gidi Gan-an!”
10 Ní Kesaréà, wọ́n fi Pọ́ọ̀lù “sábẹ́ ìṣọ́ ní ààfin Hẹ́rọ́dù tí í ṣe ibùgbé ọba,” títí dìgbà táwọn olùfisùn rẹ̀ á fi dé láti Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 23:35) Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn náà ni wọ́n dé, àwọn tó wá ni, Àlùfáà Àgbà Ananíà, olùbánisọ̀rọ̀ ní gbangba kan tó ń jẹ́ Tẹ́túlọ́sì àtàwọn àgbà ọkùnrin mélòó kan. Tẹ́túlọ́sì kọ́kọ́ gbóṣùbà fún Fẹ́líìsì nítorí nǹkan tó ń ṣe fáwọn Júù, ó sì jọ pé ńṣe ló sọ bẹ́ẹ̀ kó bàa le rí ojú rere rẹ̀. Nígbà tí ẹjọ́ náà bẹ̀rẹ̀, Tẹ́túlọ́sì sọ pé Pọ́ọ̀lù jẹ́ “alákòóbá, tí ó sì ń ru ìdìtẹ̀ sí ìjọba sókè láàárín gbogbo àwọn Júù jákèjádò ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, òun sì ni òléwájú nínú ẹ̀ya ìsìn àwọn ará Násárétì, ẹnì tí ó tún gbìyànjú láti sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́, tí a sì gbá mú.” Àwọn Júù tó kù náà wá “dara pọ̀ nínú ìgbéjàkò náà, wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.” (Ìṣe 24:5, 6, 9) Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù lágbára débi pé wọ́n lè torí ẹ̀ dájọ́ ikú fẹ́nì kan, ìyẹn àwọn bíi sísún àwọn èèyàn láti dìtẹ̀ sí ìjọba, jíjẹ́ òléwájú nínú ẹ̀ya ìsìn eléwu àti sísọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́.
“Jẹ́ Onígboyà Gidi Gan-an!”
13 Pọ́ọ̀lù fún wa ní àpẹẹrẹ tá a lè tẹ̀ lé tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọba nítorí ìjọsìn wa, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wá pé adárúgúdù-sílẹ̀ tàbí aṣọ̀tẹ̀ síjọba ni wá, wọ́n tiẹ̀ lè sọ pé “ẹ̀ya ìsìn eléwu” ni wá. Pọ́ọ̀lù ò sọ̀rọ̀ láti fa ojú gómìnà mọ́ra, kò sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ dídún tó jẹ́ ẹ̀tàn bíi ti Tẹ́túlọ́sì. Pọ́ọ̀lù hùwà lọ́nà jẹ́jẹ́ tó sì fọ̀wọ̀ hàn. Pọ́ọ̀lù fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere tó sì jẹ́ òótọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé “àwọn Júù kan ń bẹ, láti àgbègbè Éṣíà,” tí wọ́n fẹ̀sùn kan òun pé òun ń sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́, àmọ́ tí wọn kò sí níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ó wá sọ pé ó yẹ kóun rí wọn, kóun sì gbọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.—Ìṣe 24:18, 19.
14 Ohun tó gbàfiyèsí jù lọ ni pé Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó gbà gbọ́. Pẹ̀lú ìgboyà, àpọ́sítélì náà ṣàtúnsọ ìgbàgbọ́ tó ní nínú àjíǹde, ọ̀rọ̀ yìí ló sì dá wàhálà sílẹ̀ nígbà tó wà nílé ẹjọ Sànhẹ́dírìn. (Ìṣe 23:6-10) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń gbèjà ara rẹ̀, ó tẹnu mọ́ ìrètí àjíǹde. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó jẹ́rìí nípa Jésù àti bó ṣe jíǹde kúrò nínú ikú, àwọn alátakò yẹn ò sì gbà pẹ̀lú ẹ̀. (Ìṣe 26:6-8, 22, 23) Ohun tó dá wàhálà sílẹ̀ báyìí ni bóyá àjíǹde wà tàbí kò sí, àti ní pàtàkì ìgbàgbọ́ nínú Jésù àti àjíǹde rẹ̀.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 23:6
Farisí ni mí: Àwọn kan lára àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ti mọ Pọ́ọ̀lù rí tẹ́lẹ̀. (Iṣe 22:5) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù pe ara rẹ̀ ní ọmọ àwọn Farisí, á ti yé àwọn èèyàn yẹn pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun kan náà ni wọ́n jọ gbà gbọ́. Pọ́ọ̀lù ti di Kristẹni tó ń fìtara wàásù, torí náà wọ́n mọ̀ pé kò ṣàṣìṣe nígbà tó pe ara rẹ̀ ni ọmọ àwọn Farisí. Àmọ́ nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa bó ṣe jẹ́ ọmọ àwọn Farisí bọ́gbọ́n mu torí pé; Pọ́ọ̀lù ò sọ pé òun tan mọ́ àwọn Sadusí, torí pé àwọn Farisí náà gbà gbọ́ nínú àjíǹde ló ṣe pe ara rẹ̀ ni ọmọ wọn. Ohun tó ṣe yẹn ló mú kí àwọn Farisí tó wà níbẹ̀ fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ àjíǹde máa ń fa àríyànjiyàn láàárín àwọn Farisí àtàwọn Sadusí, torí náà ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ronú pé tí òun bá dá ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, àwọn kan lára àwọn ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn máa ti òun lẹ́yìn, bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. (Iṣe 23:7-9) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Iṣe 23:6 bá ohun tó tún sọ mu nígbà tó ń sọ irú èèyàn tí òun jẹ́ fún Ọba Àgírípà lásìkò tó ń gbèjà ara rẹ̀ níwájú ẹ̀. (Iṣe 26:5) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Róòmù, ó kọ̀wé sáwọn ará tó wà ní ìlú Fílípì, nínú lẹ́tà náà, ó tún mẹ́nu ba bó ṣe tan mọ́ àwọn Farisí. (Flp 3:5) Ọ̀nà tí ìwé Iṣe 15:5 gbà sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Farisí tẹ́lẹ̀ gba àfiyèsí.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 15:5.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 24:24
Dùrùsílà: Òun ni ọmọbìnrin kẹta, òun sì ni obìnrin tó kéré jù nínú àwọn ọmọ tí Hẹ́rọ́dù bí, ìyẹn Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní, tí Iṣe 12:1 mẹ́nu kàn. Nǹkan bí ọdún 38 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n bí ọmọbìnrin yìí, ó sì jẹ́ arábìnrin fún Àgírípà Kejì àti Bẹ̀níìsì. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 25:13 àti Glossary, “Hẹ́rọ́dù.”) Gómìnà Fẹ́líìsì ni ọkọ rẹ̀ kejì. Ọba Azizus ti ilẹ̀ Emesa tó wà ní Síríà ni ọkọ tó kọ́kọ́ fẹ́, àmọ́ ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ó sì fẹ́ Fẹ́líìsì lọ́dún 54 Sànmánì Kristẹni, nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún ni nígbà yẹn. Ó ṣeé ṣe kí ọmọbìnrin yìí wà níbẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù dúró níwájú Fẹ́líìsì, tó sì ń sọ̀rọ̀ “nípa òdodo àti ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìdájọ́ tí ń bọ̀.” (Iṣe 24:25) Nígbà tí Fẹ́líìsì gbé ipò gómìnà fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì, ó fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n kó lè “jèrè ojú rere lọ́dọ̀ àwọn Júù,” àwọn kan sì sọ pé ó ṣe èyí kò lè tẹ́ aya rẹ̀ kékeré lọ́rùn torí pé obìnrin Júù ni.—Iṣe 24:27.
Bíbélì Kíkà
JANUARY 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 25-26
“Pọ́ọ̀lù Ké Gbàjarè sí Késárì Ó sì Wàásù fún Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà”
“Mo Ké Gbàjarè sí Késárì!”
6 Ó ṣeé ṣe kí ojúure tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì ń wá lọ́dọ̀ àwọn Júù yìí yọrí sí ikú fún Pọ́ọ̀lù. Torí náà, Pọ́ọ̀lù lo ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí aráàlú Róòmù. Ó sọ fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé: “Mo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Késárì, níbi tí ó yẹ kí a ti ṣèdájọ́ mi. Èmi kò ṣe àìtọ́ kankan sí àwọn Júù, gẹ́gẹ́ bí ìwọ pẹ̀lú ti ń rídìí òtítọ́ rẹ̀ dáadáa. . . . Mo ké gbàjarè sí Késárì!” Béèyàn bá sì ti pe irú ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn báyìí ó ṣòro láti yí i pa dà. Ìyẹn ló mú kí Fẹ́sítọ́ọ̀sì ránnu mọ́ ọn pé: “Késárì ni ìwọ ké gbàjarè sí; ọ̀dọ̀ Késárì ni ìwọ yóò lọ.” (Ìṣe 25:10-12) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn síwájú aláṣẹ tó ga yìí jẹ́ àpẹẹrẹ fáwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní. Nígbà táwọn alátakò bá ń sapá láti fi “àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n,” àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lo ẹ̀tọ́ wa lábẹ́ òfin láti gbèjà ìhìn rere.—Sm. 94:20.
“Mo Ké Gbàjarè sí Késárì!”
10 Pọ́ọ̀lù fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọba Ágírípà fún àǹfààní tó fún un láti gbèjà ara ẹ̀ níwájú ọba, ó sì gbà pé ọba yìí jẹ́ ògbógi nínú gbogbo àṣà àti àríyànjiyàn láàárín àwọn Júù. Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé àwọn ohun tó ti ṣe, ó ní: “Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀ya ìsìn aláìgbagbẹ̀rẹ́ rárá ti ọ̀nà ìjọsìn wa ni mo fi gbé ìgbésí ayé Farisí.” (Ìṣe 26:5) Gẹ́gẹ́ bíi Farisí, Pọ́ọ̀lù gbà gbọ́ pé Mèsáyà ń bọ̀. Nígbà tó sì tí wá di Kristẹni, ó fìgboyà sọ pé Jésù Kristi lẹni náà táwọn ti ń retí látọjọ́ pípẹ́. Ohun tí òun àtàwọn alátakò ẹ̀ jọ gbà gbọ́, pé Ọlọ́run máa mú ìlérí tó ṣe fáwọn baba ńlá wọn ṣẹ gan-an, ni wọ́n ń torí ẹ̀ fọ̀rọ̀ wá Pọ́ọ̀lù lẹ́nu wò lọ́jọ́ yẹn. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí túbọ̀ mú kí Ágírípà nífẹ̀ẹ́ sóhun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ sọ.
11 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa bó ṣe ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni, ó ní: “Èmi, gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, ní ti gidi rò nínú ara mi pé ó yẹ kí n gbé ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ àtakò lòdì sí orúkọ Jésù ará Násárétì . . . níwọ̀n bí orí mi sì ti gbóná sí wọn [àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi] dé góńgó, mo lọ jìnnà dé ṣíṣe inúnibíni sí wọn, kódà ní àwọn ìlú ńlá tí ń bẹ lẹ́yìn òde.” (Ìṣe 26:9-11) Pọ́ọ̀lù ò ṣe àbùmọ́ rárá. Torí pé ọ̀pọ̀ ló mọ̀ nípa inúnibíni tó gbóná tó ṣe sáwọn Kristẹni. (Gál. 1:13, 23) Ó ṣeé ṣe kí Ágírípà máa ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ló lè mú kírú ọkùnrin yìí yi pa dà?’
12 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ tẹ̀ lé e dáhùn ìbéèrè tó ṣeé ṣe kí ọba yẹn máa rò, ó ní: “Bí mo ṣe ń rin ìrìn àjò lọ sí Damásíkù pẹ̀lú ọlá àṣẹ àti ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, ní ọjọ́kanrí lójú ọ̀nà, ìwọ ọba, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan tí ó ré kọjá ìdányanran oòrùn, tí ó kọ mànà láti ọ̀run yí mi ká àti yí ká àwọn tí ń rin ìrìn àjò pẹ̀lú mi. Nígbà tí gbogbo wa sì ti ṣubú lulẹ̀ tán, mo gbọ́ ohùn kan tí ó sọ fún mi ní èdè Hébérù pé, ‘Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Láti máa bá a nìṣó ní títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́ mú kí ó nira fún ọ.’ Ṣùgbọ́n mo wí pé, ‘Ta ni ọ́, Olúwa?’ Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jésù, ẹni tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.’ ”—Ìṣe 26:12-15.
13 Kí iṣẹ́ ìyanu yìí tó ṣẹlẹ̀, lọ́nà àfiṣàjúwe, Pọ́ọ̀lù ti ń bá a nìṣó ní “títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́.” Bí ẹranko arẹrù kan ṣe máa ṣe ara ẹ̀ léṣe bó bá ń ta ibi tó mú lára ọ̀pá kẹ́sẹ́ nípàá, bákan náà ni Pọ́ọ̀lù ṣe ń dínà níní àjọṣe tó dáa mọ́ ara ẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run bó ṣe ń tako ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù tó ti jíǹde fara han Pọ́ọ̀lù lójú ọ̀nà Damásíkù, ó mú kí ọkùnrin olóòótọ́, tí wọ́n ti ṣì lọ́nà, yìí yí èrò ẹ̀ pa dà.—Jòh. 16:1, 2.
14 Pọ́ọ̀lù tètè ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ nígbèésí ayé ẹ̀. Ó sọ fún Ágírípà pé: “Èmi kò di aláìgbọràn sí ìran ti ọ̀run náà, ṣùgbọ́n mo ń mú ìhìn iṣẹ́ náà wá fún àwọn tí ń bẹ ní Damásíkù lákọ̀ọ́kọ́ àti àwọn tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù, àti fún gbogbo ilẹ̀ Jùdíà, àti fún àwọn orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí padà sí Ọlọ́run nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.” (Ìṣe 26:19, 20) Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni Pọ́ọ̀lù ti ń ṣe iṣẹ́ ti Jésù Kristi gbé lé e lọ́wọ́ nínú ìran lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn. Kí wá ni àbájáde ẹ̀? Àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù wàásù ronú pìwà dà kúrò nínú ìṣekúṣe àti àìṣòótọ́ wọn, wọ́n sì yí pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn wọ̀nyí wá di ọmọ orílẹ̀-èdè rere, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún òfin àti ètò ìlú, wọ́n sì ń kọ́wọ́ tì í lẹ́yìn.
15 Gbogbo ìyẹn ò já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn Júù tó ń takò Pọ́ọ̀lù. “Ní tìtorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù fi gbá mi mú nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì gbìdánwò láti pa mí. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí pé mo ti rí ìrànlọ́wọ́ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbà, mo ń bá a lọ títí di òní yìí ní jíjẹ́rìí fún àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá.”—Ìṣe 26:21, 22.
16 Àwa Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa “wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà” ìgbàgbọ́ wa. (1 Pét. 3:15) Bá a bá ń báwọn adájọ́ àtàwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tá a gbà gbọ́, ó lè ṣàǹfààní tá a bá tẹ̀ lé irú ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó ń bá Ágírípà àti Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ̀rọ̀. Bá a bá fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ bí òtítọ́ Bíbélì ṣe tún ìgbésí ayé wa àti tàwọn tó tẹ́wọ́ gba ìhìn rere tá a wàásù ṣe, ó ṣeé ṣe kí èyí rọ àwọn aláṣẹ yìí lọ́kàn.
“Mo Ké Gbàjarè sí Késárì!”
18 Pọ́ọ̀lù ò ṣaláì fèsì ọ̀rọ̀ gómìnà náà, ó ní: “Kì í ṣe pé orí mi ti ń dà rú, Fẹ́sítọ́ọ̀sì Ẹni Títayọ Lọ́lá, ṣùgbọ́n àwọn àsọjáde tí ó jẹ́ òtítọ́ àti ti ìyèkooro èrò inú ni mo ń sọ jáde. Ní ti gidi, ọba tí mo ń bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ mọ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí dáadáa . . . Ágírípà Ọba, ìwọ ha gba àwọn Wòlíì gbọ́ bí? Mo mọ̀ pé o gbà gbọ́.” Ṣùgbọ́n Ágírípà wí fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.” (Ìṣe 26:25-28) Bóyá ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán ló sọ o tàbí ó tọkàn ẹ̀ wá, ohun tó dájú ni pé ìwàásù Pọ́ọ̀lù wọ̀ ọ́ lọ́kàn.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 26:14
títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́: Ọ̀pá kẹ́sẹ́ jẹ́ ọ̀pá gígùn tó máa ń ní orí ṣóńṣó tẹ́nì kan lè fi mú kí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ ṣe ohun tó fẹ́. (Ond 3:31) Ọ̀rọ̀ náà “títàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́” jẹ́ òwe èdè Gíríìkì. Wọ́n ń fi òwe yìí ṣàpèjúwe akọ màlúù kan tó ń ṣagídí nígbà tí wọ́n fi ọ̀pá kẹ́sẹ́ gún un, tó wá ta ọ̀pá kẹ́sẹ́ náà ní ìpá, tó sì ṣe ara rẹ̀ léṣe. Irú ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe náà nìyẹn kó tó di Kristẹni. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń gbìyànjú láti dáwọ́ iṣẹ́ táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń ṣe dúró, tó sì jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run ló ń tì wọ́n lẹ́yìn, ṣe ló dà bí ìgbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ ṣe ara rẹ̀ léṣe. (Fi wé Iṣe 5:38, 39; 1Ti 1:13, 14.) Nínú ìwé Onw 12:11, a fi “ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù” wé ọ̀rọ̀ tí ọlọ́gbọ́n kan sọ láti fúnni nímọ̀ràn, tá á sì sún ẹni náà láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn.
nwt glossary
Ọ̀pá kẹ́sẹ́. Ọ̀pá gígùn tó ní irin ṣóńṣó lẹ́nu tí darandaran máa ń rọra fi gún ẹran ọ̀sìn. Wọ́n máa ń fi wé ọ̀rọ̀ tí ọlọ́gbọ́n èèyàn sọ láti mú kí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ gba ìmọ̀ràn. Tí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan “ń tàpá sí ọ̀pá kẹ́sẹ́,” ńṣe ló dà bí ohun tí akọ màlúù kan tó ya alágídí ń ṣe nígbà tó bá ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ gbá ọ̀pá kẹ́sẹ́, tó sì ṣe ara rẹ̀ léṣe.—Iṣe 26:14; Ond 3:31.
Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Ìjọba Náà
14 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Júù aláfẹnujẹ́ ni Àgírípà. Kí Pọ́ọ̀lù má bàa sọ kọjá ohun tí Àgírípà mọ̀ nípa ìsìn àwọn Júù, ó rí i dájú pé bí òun ṣe ń wàásù, òun “kò sọ nǹkan kan àyàfi àwọn ohun tí àwọn Wòlíì àti Mósè sọ pé yóò ṣẹlẹ̀” nípa ikú àti àjíǹde Mèsáyà. (Ìṣe 26:22, 23) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù darí ọ̀rọ̀ sí Àgírípà fúnra rẹ̀, ó béèrè pé: “Àgírípà Ọba, ìwọ ha gba àwọn Wòlíì gbọ́ bí?” Àgírípà ò lè fèsì ọ̀rọ̀ náà. Tó bá sọ pé òun kò gba àwọn wòlíì gbọ́, yóò pàdánù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gba ìsìn àwọn Júù gbọ́. Tó bá sì sọ pé òun gbà ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù gbọ́, a jẹ́ pé ó fara mọ́ ohun tí àpọ́sítélì náà wí lójú gbogbo èèyàn nìyẹn, ìyẹn sì lè jẹ́ kí wọ́n pè é ní Kristẹni. Pọ́ọ̀lù wá fọgbọ́n dáhùn ìbéèrè tí òun fúnra rẹ̀ béèrè, ó ní: “Mo mọ̀ pé o gbà gbọ́.” Kí ni ọkàn Àgírípà wá sún un láti fi fèsì ọ̀rọ̀ náà? Ó dáhùn pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.” (Ìṣe 26:27, 28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Àgírípà kò di Kristẹni, ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ wọ̀ ọ́ lọ́kàn dé ààyè kan.—Hébérù 4:12.
Bíbélì Kíkà
JANUARY 28–FEBRUARY 3
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 27-28
“Pọ́ọ̀lù Wọkọ̀ Ojú Omi Lọ sí Róòmù”
“Kò Sí Ọkàn Kan Láàárín Yín Tí A Ó Pàdánù”
15 Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ti máa wàásù fáwọn èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ náà nípa “ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe.” (Ìṣe 26:6; Kól. 1:5) Àmọ́ ní báyìí tí ọkọ̀ wọn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ rì, Pọ́ọ̀lù tún wá sọ̀rọ̀ tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n á bọ́. Ó sọ pé: “Ní òru yìí, áńgẹ́lì . . . , dúró tì mí, ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù. Ìwọ gbọ́dọ̀ dúró níwájú Késárì, sì wò ó! Ọlọ́run ti fi gbogbo àwọn tí ẹ jọ ń lọ lójú omi fún ọ lọ́fẹ̀ẹ́.’ ” Pọ́ọ̀lù wá rọ̀ wọ́n pé: “Nítorí náà, ẹ túra ká; nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ fún mi ni yóò rí. Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ gbá wa jù sí èbúté lórí erékùṣù kan.”—Ìṣe 27:23-26.
“Kò Sí Ọkàn Kan Láàárín Yín Tí A Ó Pàdánù”
18 Erékùṣù Málítà tó wà ní gúúsù Sísílì ni gbogbo àwọn tó la ìṣẹ̀lẹ̀ yìí já gúnlẹ̀ sí. (Wo àpótí náà, “Ibo Ni Málítà Wà?”) Àwọn èèyàn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè tó ń gbé ní erékùṣù náà fi “àrà ọ̀tọ̀ inú rere ẹ̀dá ènìyàn” hàn sí wọn. (Ìṣe 28:2) Wọ́n wá dáná káwọn àlejò tó gúnlẹ̀ sí èbúté yìí lè yáná, torí pé gbogbo ara wọn ló rin tí wọ́n sì ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òjò ń rọ̀ tí òtútù sì ń mú, iná yìí ló jẹ́ kí ara wọn móoru. Iṣẹ́ ìyanu kan sì tún ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.
21 Àgbègbè yẹn ni ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Púbílọ́sì ń gbé. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù ní erékùṣù Málítà. Lúùkù pè é ní “ọkùnrin sàràkí erékùṣù náà,” èyí sì jẹ́ orúkọ oyè kan tí wọ́n ti rí lára àwọn ohun fínfín méjì tó jẹ́ tàwọn ará Málítà. Ó sì gba Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò lálejò fún ọjọ́ mẹ́ta. Àmọ́ ṣá, ara bàbá Púbílọ́sì kò yá. Lẹ́ẹ̀kan sí i Lúùkù tún mẹ́nu kan irú àìsàn tó ń ṣe ọkùnrin yìí lọ́nà tó péye. Ó kọ̀wé pé “ibà àti ìgbẹ́ ọ̀rìn ń yọ ọ́ lẹ́nu.” Pọ́ọ̀lù wá gbàdúrà fún un, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì mú un lára dá. Iṣẹ́ ìyanu yìí ya àwọn èèyàn ìlú náà lẹ́nu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé àwọn aláìsàn míì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè wò wọ́n sàn, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀bùn wá fún Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò láti fi bójú tó àìní wọn.—Ìṣe 28:7-10.
“Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná”
10 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn èèyàn náà wọ Róòmù, wọ́n “gba Pọ́ọ̀lù láyè láti wà ní òun nìkan pẹ̀lú ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ.” (Ìṣe 28:16) Ní tàwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n ò le, ńṣe ni wọ́n máa ń fi ẹ̀wọ̀n de ọwọ́ wọn mọ́ ti ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ wọ́n. Síbẹ̀, olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù, ó sì dájú pé ẹ̀wọ̀n tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ ò lè ní kó má wàásù. Torí náà, lẹ́yìn tó ti fúnra ẹ̀ lọ́jọ́ mẹ́ta kí ara ẹ̀ lè wálẹ̀ lẹ́yìn ìrìn àjò yẹn, ó pe àwọn tí wọ́n jẹ́ sàràkí-sàràkí jọ lára àwọn Júù tó wà ní Róòmù kó bàa lè fira ẹ̀ hàn wọ́n kó sì tún wàásù fún wọn.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 27:9
ààwẹ̀ [ọjọ́ ètùtù]: Tàbí “ààwẹ̀ ìgbà ìkórè.” Tá a bá túmọ̀ rẹ̀ ní tààràtà, ó túmọ̀ sí “ààwẹ̀.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún “ààwẹ̀” ń tọ́ka sí ààwẹ̀ kan ṣoṣo tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú Òfin Mósè, ìyẹn ààwẹ̀ tí wọ́n máa ń gbà ní Ọjọ́ Ètùtù lọ́dọọdún, wọ́n tún máa ń pè é ní Yom Kippur (látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà yohm hak·kip·pu·rimʹ, “ọjọ́ ìbo nǹkan mọ́lẹ̀ tàbí ìpẹ̀tù”). (Le 16:29-31; 23:26-32; Nu 29:7; wo Glossary, “Ọjọ́ Ètùtù.”) Gbólóhùn náà “kí ẹ ṣẹ́ ọkàn yín níṣẹ̀ẹ́,” tí Bíbélì lò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Ọjọ́ Ètùtù yé àwọn èèyàn náà pé àwọn gbọ́dọ̀ fi oríṣiríṣi nǹkan du ara wọn, bíi kí wọ́n gbààwẹ̀. (Le 16:29) Ọ̀rọ̀ náà “ààwẹ̀” tí wọ́n lò nínú Iṣe 27:9 ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn pé, ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n máa ń gbà fi hàn pé wọ́n fi nǹkan du ara wọn ní Ọjọ́ Ètùtù ni pé kí wọ́n gba ààwẹ̀. Ìparí oṣù September tàbí ìbẹ̀rẹ̀ October ni ààwẹ̀ Ọjọ́ Ètùtù sábà máa ń bọ́ sí.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 28:11
Àwọn Ọmọ Súúsì: Nínú ìtàn àròsọ àwọn ará Gíríìkì àti àwọn Róòmù, “Àwọn Ọmọ Súúsì” (Gíríìkì, Di·oʹskou·roi) ni Kásítọ̀ àti Pólúsì, ìyẹn àwọn ìbejì tí Ọbabìnrin Lídà bí fún Súúsì (Júpítà). Àwọn èèyàn gbà pé àwọn ló máa ń dáàbò bo àwọn atukọ̀ lórí omi, nígbà tí òkun bá ń ru gùdù. Bí Bíbélì ṣe mẹ́nu ba ère tó wà lórí ọkọ̀ òkun yìí tún jẹ́ ẹ̀rí míì tó fi hàn pé ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣojú ẹni tó kọ ìtàn náà.
Bíbélì Kíkà