ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwbr19 February ojú ìwé 1-5
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2019
  • Ìsọ̀rí
  • FEBRUARY 4-10
  • FEBRUARY 11-17
  • FEBRUARY 18-24
  • FEBRUARY 25–MARCH 3
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2019
mwbr19 February ojú ìwé 1-5

Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

FEBRUARY 4-10

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | RÓÒMÙ 1-3

“Máa Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ”

lv 16 ¶6

Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere

6 Ṣé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nìkan ni Jèhófà dá ẹ̀rí ọkàn mọ́ ni? Gbọ́ ohun tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ, ó ní: “Nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn-àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, a ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí a ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.” (Róòmù 2:​14, 15) Èyí fi hàn pé nígbà míì, ẹ̀rí ọkàn àwọn tí kò mọ àwọn òfin Jèhófà pàápàá máa ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó bá ìlànà Ọlọ́run mu.

lv 17-18 ¶8-9

Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere

8 Báwo lo ṣe máa ń ṣàwọn ìpinnu tá a gbé ka ẹ̀rí ọkàn? Àwọn kan wà tó dà bíi pé ohun tó bá ṣáà ti wá sí wọn lọ́kàn ni wọ́n máa ń ṣe. Wọ́n lè wá sọ pé: “Kò da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú.” Ohun tó bá wu ọkàn-àyà láti ṣe ló máa ń fẹ́ ṣe, ìyẹn sì lè ran ẹ̀rí ọkàn. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremáyà 17:9) Nítorí náà, ohun tó wu ọkàn-aya láti ṣe kọ́ ló yẹ kó jẹ wá lógún, bí kò ṣe ohun tó máa múnu Jèhófà Ọlọ́run dùn.

9 Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ là ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti kọ́ tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, ìpinnu yẹn máa fi hàn pé a ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn àti pé ìfẹ́ inú wa kọ́ là ń ṣe. Àpẹẹrẹ ẹnì kan rèé. Nehemáyà, tó jẹ́ gómìnà tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́, lẹ́tọ̀ọ́ láti máa gba owó orí àtàwọn ìṣákọ́lẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn ará ìlú Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ló dé tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kó fẹ́ dáwọ́ lé ohunkóhun tó lè múnú bí Jèhófà nípa níni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára. Ó sọ pé: “Èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tìtorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (Nehemáyà 5:15) Ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn, ìyẹn ìbẹ̀rù àtọkànwá tí ò ní jẹ́ ká ṣe ohunkóhun tó máa bí Baba wa ọ̀run nínú. Irú ìbẹ̀rù tó ń fọ̀wọ̀ hàn bẹ́ẹ̀ á jẹ́ ká máa wo ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ká tó ṣèpinnu èyíkéyìí.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w08 6/15 30 ¶5

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Róòmù

3:4. Tí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn bá ta ko ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, ńṣe ni ká “jẹ́ kí a rí Ọlọ́run ní olóòótọ́” nípa títẹ̀lé ohun tí Bíbélì sọ, ká sì máa ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Tá a bá ń fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn, a óò lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí Ọlọ́run ní olóòótọ́.

w08 6/15 29 ¶6

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Róòmù

3:​24, 25​—Báwo ni “ìràpadà tí Kristi Jésù san” ṣe kan “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wáyé ní ìgbà tí ó ti kọjá” kí wọ́n tó san ìràpadà náà? Ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nípa Mèsáyà tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ní ìmúṣẹ, ìyẹn nígbà tí wọ́n pa Jésù lórí òpó igi oró. (Gál. 3:​13, 16) Gbàrà tí Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló ti dà bí pé ó ti ní ìmúṣẹ lójú rẹ̀, torí pé kò sí ohun tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ kó má mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nítorí náà, lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, èyí tí kò tíì wáyé nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí yẹn. Ìràpadà yẹn yóò tún jẹ́ kí àjíǹde lè ṣeé ṣe fáwọn tó ti wà ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé.​—Ìṣe 24:15.

Bíbélì Kíkà

FEBRUARY 11-17

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | RÓÒMÙ 4-6

“Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Tirẹ̀ fún Wa”

w11 6/15 12 ¶5

Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Rẹ̀ Fún Wa

5 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tó fà á. Ó bẹ̀rẹ̀ àlàyé rẹ̀ báyìí pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Èyí kò lè ṣàjèjì sí wa torí pé Ọlọ́run mú kí àwọn tó kọ Bíbélì ṣàlàyé bí ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn ṣe bẹ̀rẹ̀. Wọ́n sọ pé Jèhófà dá Ádámù àti Éfà. Ẹni pípé ni Ẹlẹ́dàá tó dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́ yìí, ó sì dá àwọn náà ní pípé. Ó sọ ohun kan ṣoṣo tí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bí wọ́n bá ṣàìgbọràn, wọ́n máa kú. (Jẹ́n. 2:17) Àmọ́, wọ́n yàn láti ṣe ohun tó máa yọrí sí ìparun fún wọn, wọ́n ṣàìgbọràn sí àṣẹ tó mọ́gbọ́n dání tó sì ṣe kedere èyí tí Ọlọ́run pa fún wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn kò gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run àti ẹni tó yẹ kó máa fún àwọn lófin.​—Diu. 32:​4, 5.

w11 6/15 12 ¶6

Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Rẹ̀ Fún Wa

6 Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀ kó tó bí àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ jogún ẹ̀ṣẹ̀ yìí látọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń kú. Àmọ́ torí pé àwọn ọmọ Ádámù kò rú òfin kan náà tí Ádámù rú, Ọlọ́run kò fi ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù bi wọ́n; àti pé kò tíì sí àkójọ òfin kankan nígbà yẹn. (Jẹ́n. 2:17) Síbẹ̀, àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù jogún ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jọba títí di àkókò tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkójọ òfin, èyí tó mú kó ṣe kedere pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. (Ka Róòmù 5:​13, 14.) A lè fi bí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ṣe ń fa ikú wé àwọn àìsàn tàbí àìlera kan tí wọ́n máa ń bí mọ́ni, irú bí àìtó ẹ̀jẹ̀ tàbí àrùn tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tètè dá. O lè ti kà á rí pé wọ́n bí àrùn kan tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tètè dá mọ́ Alexis, tó jẹ́ ọmọ olú ọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ìyẹn Czar Nicholas Kejì àti Alexandra. Síbẹ̀, àwọn ọmọ kan wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ní irú àrùn yìí tí wọ́n lè ní àrùn náà lára ṣùgbọ́n tí kò ní ṣe wọ́n ní nǹkan kan. Ti ẹ̀ṣẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Àìpé tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Gbogbo wa là ń jìyà rẹ̀. Ikú ló sì máa ń yọrí sí. Gbogbo ọmọ ló máa ń jogún rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Ṣé a tiẹ̀ lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ikú yìí?

w11 6/15 13 ¶9-10

Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Rẹ̀ Fún Wa

9 Kí ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ lédè Yorùbá sí “ìpolongo òdodo” àti “pípolongo wọn ní olódodo”? Ọ̀mọ̀wé Williams tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Àfiwé ni. Wọ́n máa ń lò ó láti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ òfin. Gbólóhùn náà ṣàlàyé ìyípadà tí Ọlọ́run mú kó wáyé nínú ìgbésí ayé ẹnì kan, kì í wulẹ̀ ṣe bí èèyàn ṣe yí ọ̀nà tó gbà ń hùwà pa dà . . . Àfiwé náà fi Ọlọ́run sípò adájọ́ tó ti ṣe tán láti dá ẹni tí wọ́n gbé wá sí kóòtù rẹ̀ láre lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn kan onítọ̀hún pé ó hùwà àìṣòdodo. Àmọ́, Ọlọ́run dá ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà sílẹ̀ pátápátá.”

10 Kí ló lè mú kí “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé” dá aláìṣòdodo sílẹ̀ pátápátá? (Jẹ́n. 18:25) A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínu ohun tí Ọlọ́run ṣe. Ìfẹ́ tó ní sí aráyé mú kó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sáyé. Láìka ìdẹwò, ìfiniṣẹ̀sín àti èébú sí, Jésù ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ lọ́nà pípé pérépéré. Ó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ débi tó fi kú lórí òpó igi oró. (Héb. 2:10) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé, Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìràpadà tó lè tú àwọn ọmọ Ádámù sílẹ̀ tàbí kó rà wọ́n pa dà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.​—Mát. 20:28; Róòmù 5:​6-8.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w08 6/15 29 ¶7

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Róòmù

6:​3-5​—Kí ló túmọ̀ sí láti dẹni tá a batisí sínú Kristi Jésù àti sínú ikú rẹ̀? Nígbà tí Jèhófà fẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi, wọ́n dẹni tó wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Jésù, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di apá kan ìjọ, ìyẹn ara Kristi, tí Kristi fúnra rẹ̀ sì jẹ́ Orí ìjọ náà. (1 Kọ́r. 12:​12, 13, 27; Kól. 1:18) Bí wọ́n ṣe dẹni tá a batisí sínú Kristi Jésù nìyẹn. A “batisí” àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “sínú ikú” Kristi ní ti pé, wọ́n ń gbé ìgbé ayé ẹni tó fi ara rẹ̀ rúbọ, wọ́n sì yááfì gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ikú ẹni tó fara rẹ̀ rúbọ ni wọ́n ń kú bíi ti Jésù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò fi ikú tiwọn ṣe ìràpadà. Ó dìgbà táwọn ẹni àmì òróró bá jíǹde sí ọ̀run lẹ́yìn ikú wọn kí batisí tá a batisí wọn sínú ikú Kristi tó parí.

w14 6/1 11 ¶1

Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Baba Ńlá Mi Tó ti Kú?

Tí àwọn aláìṣòdodo bá jíǹde, ṣé ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kú ni Ọlọ́run á fi dá wọn lẹ́jọ́? Rárá o. Róòmù 6:7 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Ọlọ́run ti pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn aláìṣòdodo yẹn rẹ́ nígbà tí wọ́n ti kú. Torí náà, ohun tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí wọ́n jíǹde ni Ọlọ́run á fi dá wọn lẹ́jọ́, kì í ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe nígbà àìmọ̀. Àǹfààní wo ni àwọn èèyàn yìí máa rí?

Bíbélì Kíkà

FEBRUARY 18-24

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | RÓÒMÙ 7-8

“Ṣé Ò Ń Fojú Sọ́nà Pẹ̀lú Ìháragàgà?”

w12 7/15 11 ¶17

Jẹ́ Kí Jèhófà Ṣamọ̀nà Rẹ Síbi Tí Ojúlówó Òmìnira Wà

17 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń jíròrò bí Jèhófà ṣe máa sọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé di òmìnira, ó sọ pé: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà ló wá fi kún un pé: “A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:​19-21) “Ìṣẹ̀dá” túmọ̀ sí aráyé tí wọ́n ní ìrètí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n sì máa jàǹfààní látinú “ìṣípayá” àwọn ọmọ Ọlọ́run tí a fi ẹ̀mí bí. Ìṣípayá yẹn máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá jí “àwọn ọmọ” yìí dìde sí òkè ọ̀run, tí wọ́n sì ran Kristi lọ́wọ́ láti pa gbogbo àwọn ẹni ibi tó wà lórí ilẹ̀ ayé run, tí wọ́n sì pa “ogunlọ́gọ̀ ńlá” mọ́ láàyè wọnú ètò àwọn nǹkan tuntun.​—Ìṣí. 7:​9, 14.

w12 3/15 23 ¶11

Jẹ́ Kí Ìrètí Tá A Ní Máa Fún Ẹ Láyọ̀

11 Jèhófà ló fún ìran èèyàn ní “ìrètí” nígbà tó ṣèlérí pé òun máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” Sátánì Èṣù, nípasẹ̀ “irú-ọmọ” tá a ṣèlérí. (Ìṣí. 12:9; Jẹ́n. 3:15) Jésù Kristi ni àkọ́kọ́ lára “irú-ọmọ” náà. (Gál. 3:16) Nípasẹ̀ ikú àti àjíǹde Jésù, ó pèsè ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ fún ìrètí tí aráyé ní, pé a óò dá wọn sílẹ̀ kúrò nínú jíjẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ìmúṣẹ ìrètí yìí ní í ṣe pẹ̀lú “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Àwọn ẹni àmì òróró tá a ti ṣe lógo ni apá kejì lára “irú-ọmọ” náà. A máa ‘ṣí wọn payá’ nígbà tí wọ́n bá dara pọ̀ mọ́ Kristi láti pa ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì run. (Ìṣí. 2:​26, 27) Èyí máa jẹ́ ìgbàlà fún àwọn àgùntàn mìíràn, tí wọ́n jáde wá látinú ìpọ́njú ńlá náà.​—Ìṣí. 7:​9, 10, 14.

w12 3/15 23 ¶12

Jẹ́ Kí Ìrètí Tá A Ní Máa Fún Ẹ Láyọ̀

12 Ìtura ńlá mà ni “ìṣẹ̀dá,” ìyẹn ẹ̀dá èèyàn, máa ní nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi o! Ní ìgbà yẹn, a máa túbọ̀ ‘ṣí’ “àwọn ọmọ Ọlọ́run” tá a ti ṣe lógo ‘payá’ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà pẹ̀lú Kristi, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí aráyé jàǹfààní látinú ẹbọ ìràpadà Jésù. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba ọ̀run náà, àwọn èèyàn tó jẹ́ “ìṣẹ̀dá” máa bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìdáǹdè lọ́wọ́ ipa tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti ní lórí wọn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a ó “dá” àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn “sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́.” Bí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà jálẹ̀ Ẹgbẹ̀rún ọdún náà àti nígbà ìdánwò ìkẹyìn tó máa tẹ̀ lé e, a óò kọ orúkọ wọn sínú “àkájọ ìwé ìyè” títí láé. Wọ́n á wá wọnú “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Ìṣí. 20:​7, 8, 11, 12) Ìrètí ológo lèyí jẹ́ lóòótọ́!

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w17.06 3

Ǹjẹ́ O Rántí?

Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín “gbígbé èrò inú ka ẹran ara” àti “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí”? (Róòmù 8:6)

Àwọn tó ń gbé èrò inú wọn ka ẹran ara máa ń gbájú mọ́ bí wọ́n á ṣe tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, òun ni wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, tí wọ́n sì fi ń ṣayọ̀. Àmọ́, ẹni tí ń gbé èrò inú rẹ̀ ka ẹ̀mí máa ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ darí èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe òun, ó sì máa ń ṣe ohun tó wu Jèhófà. Ikú ló máa ń gbẹ̀yìn àwọn tó bá gbé èrò wọn ka ẹran ara, àmọ́ àwọn tó bá gbé èrò wọn ka ẹ̀mí máa ní ìyè àti àlàáfíà.​—w16.12, ojú ìwé 15 sí 17.

w09 11/15 7 ¶20

Kí Ni Àdúrà Rẹ Ń Sọ Nípa Rẹ?

20 Ìgbà míì wà tí a kì í mọ ohun tó yẹ ká sọ nínú àdúrà tá à ń dá gbà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìṣòro ohun tí àwa ì bá máa gbàdúrà fún bí ó ti yẹ kí a ṣe ni àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀mí [mímọ́] tìkára rẹ̀ ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú àwọn ìkérora tí a kò sọ jáde. Síbẹ̀síbẹ̀, [Ọlọ́run,] ẹni tí ń wá inú ọkàn-àyà mọ ohun tí ẹ̀mí túmọ̀ sí.” (Róòmù 8:​26, 27) Jèhófà mú kí ọ̀pọ̀ àdúrà wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ló mí sí àwọn tó kọ wọ́n sílẹ̀, tá a bá fi ọ̀rọ̀ inú wọn tọrọ nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ yóò gbọ́ àdúrà wa. Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa, ó sì mọ ìtumọ̀ ohun tó jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ gbẹnu àwọn tó kọ Bíbélì sọ. Nígbà tí ẹ̀mí bá ń bá wa “jírẹ̀ẹ́bẹ̀,” ìyẹn ni pé tó ń bá wa tọrọ nǹkan lọ́wọ́ Jèhófà, Jèhófà máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. Àmọ́ bá a bá ṣe ń lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run síwájú sí i, àwọn ohun tá a fẹ́ gbàdúrà fún yóò máa tètè sọ sí wa lọ́kàn.

Bíbélì Kíkà

FEBRUARY 25–MARCH 3

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | RÓÒMÙ 9-11

“Àpèjúwe Igi Ólífì”

w11 5/15 23 ¶13

‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’

13 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó nípa fífi àwọn tó di apá kan irú-ọmọ Ábúráhámù wé àwọn ẹ̀ka tó wà lára igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ. (Róòmù 11:21) Igi ólífì tá a gbìn yìí ṣàpẹẹrẹ bí ète tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nígbà tó bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú ṣe ní ìmúṣẹ. Gbòǹgbò igi náà jẹ́ mímọ́ ó sì dúró fún Jèhófà tó mú kí Ísírẹ́lì tẹ̀mí wà láàyè. (Aísá. 10:20; Róòmù 11:16) Ìtí igi náà dúró fún Jésù tó jẹ́ apá àkọ́kọ́ lára irú-ọmọ Ábúráhámù. Lápapọ̀, àwọn ẹ̀ka igi náà dúró fún “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye” àwọn tó jẹ́ apá kejì lára irú-ọmọ Ábúráhámù.

w11 5/15 24 ¶15

‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’

15 Kí wá ni Jèhófà ṣe kó lè mú ète rẹ̀ ṣẹ? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé a lọ́ àwọn ẹ̀ka tí wọ́n gé lára igi ólífì ìgbẹ́ sára igi ólífì tá a gbìn náà ká lè fi wọ́n rọ́pò àwọn tí a ṣẹ́ kúrò. (Ka Róòmù 11:​17, 18.) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn, tí àwọn díẹ̀ nínú wọn wà nínú ìjọ Róòmù, la lọ́ sára igi ólífì yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Wọ́n sì tipa báyìí di apá kan irú-ọmọ Ábúráhámù. Wọ́n ti kọ́kọ́ dà bí àwọn ẹ̀ka igi ólífì ìgbẹ́, wọn kò sì ní àǹfààní kankan láti di apá kan májẹ̀mú àkànṣe yìí. Àmọ́, Jèhófà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti di Júù nípa tẹ̀mí.​—Róòmù 2:​28, 29.

w11 5/15 25 ¶19

‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’

19 Ó dájú pé ète Jèhófà nípa “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ti ń ní ìmúṣẹ lọ́nà tó kàmàmà. (Gál. 6:16) Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, “a ó gba gbogbo Ísírẹ́lì là.” (Róòmù 11:26) Bó bá tó àkókò lójú Jèhófà, “gbogbo Ísírẹ́lì,” ìyẹn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye Ísírẹ́lì tẹ̀mí, yóò máa sìn gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà lọ́run. Kò sí ohunkóhun tó lè ní kí ète Jèhófà máà kẹ́sẹ járí!

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w13 6/15 25 ¶5

Jẹ́ Kí Amọ̀kòkò Tí Kò Lẹ́gbẹ́ Náà Mọ Ẹ́

5 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ò gbà kí Jèhófà mọ òun ńkọ́? Báwo ni Jèhófà ṣe máa lo àṣẹ lórí onítọ̀hún? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ká sọ pé amọ̀kòkò kan rí i pé kò ṣeé ṣe láti fi amọ̀ mọ ohun kan tí òun ní lọ́kàn, ó lè fi amọ̀ náà mọ nǹkan míì tàbí kó dà á nù. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé ọwọ́ amọ̀kòkò ni àṣìṣe yẹn ti wá. Àmọ́ Jèhófà kì í ṣàṣìṣe ní tiẹ̀. (Diu. 32:4) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé Jèhófà pa ẹnì kan tì, onítọ̀hún ló fà á. Ohun tí ẹnì kan bá ṣe nígbà tí Jèhófà bá ń tọ́ ọ sọ́nà ló máa pinnu ohun tó máa fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ. Tó bá ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó máa wúlò fún un. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jẹ́ “ohun èlò àánú,” tí Ọlọ́run sọ di ohun èlò fún “ìlò ọlọ́lá.” Àmọ́, àwọn tí kò gbà kí Jèhófà tọ́ wọn sọ́nà di “àwọn ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun.”​—Róòmù 9:​19-23.

it-1 1260 ¶2

Jowú, Owú

Ìtara Tí Kò Tọ̀nà. Ẹnì kan lè ní ìtara lóòótọ́, ó lè máa fi tọkàntọkàn ṣe nǹkan kan, síbẹ̀ kí ohun tó ń ṣe má tọ̀nà, kó sì máa múnú bí Ọlọ́run. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí púpọ̀ lára àwọn Júù ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìyẹn. Wọ́n ń ronú pé bí àwọn ṣe ń tẹ̀ lé Òfin Mósè, àwọn máa di olódodo. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìtara wọn ò tọ̀nà torí pé wọn ò ní ìmọ̀ tó péye. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run ò fi kà wọ́n sí olódodo. Kí wọ́n tó lè bọ́ lọ́wọ́ ìdálẹ́bi Òfin kí wọ́n sì di olódodo, wọ́n máa ní láti gba ẹ̀bi wọn lẹ́bi, wọ́n sì máa ní láti yíjú sí Ọlórun nípasẹ̀ Jésù. (Ro 10:​1-10) Ọ̀kan lára irú àwọn Júù bẹ́ẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù ará Tásù, ó ní ìtara fún ìsìn Júù, ìtara náà sì pọ̀ lápọ̀jù, òun fúnra rẹ̀ sọ pé òun ń “ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run,” òun “sì ń pa á run.” Ṣe ló máa ń tẹ̀ lé Òfin kínníkínní, kó lè di “ẹni tí ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi.” (Ga 1:​13, 14; Flp 3:6) Síbẹ̀, ìtara tó ní fún ẹ̀sìn Júù kì í ṣe èyí tó tọ̀nà. Lóòótọ́, tọkàntọkàn ló fi ń ṣe é, ìdí nìyẹn tí Jèhófà ṣe fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí i nípasẹ̀ Kristi, tó sì wá jẹ́ kó máa lo ìtara rẹ̀ fún ìjọsìn tòótọ́.​—1Ti 1:​12, 13.

Bíbélì Kíkà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́