ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb19 June ojú ìwé 7
  • Fọgbọ́n Yan Eré Ìnàjú Tí Wàá Máa Ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fọgbọ́n Yan Eré Ìnàjú Tí Wàá Máa Ṣe
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yan Eré Ìnàjú Táá Múnú Jèhófà Dùn
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bó O Ṣe Lè Yan Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Ìwọ Lè Rí Ohun Àṣenajú Gbígbámúṣé
    Jí!—1997
  • Eré-Ìnàjú Ẹgbẹ́-Òun-Ọ̀gbà—Gbadun Awọn Anfaani Rẹ̀, Yẹra fun Awọn Idẹkun Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
mwb19 June ojú ìwé 7

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fọgbọ́n Yan Eré Ìnàjú Tí Wàá Máa Ṣe

Kí nìdí tó fi yẹ ká fọgbọ́n yan eré ìnàjú tá a máa ṣe? Ìdí ni pé tá a bá yan fíìmù kan tá a fẹ́ wò, orin tá a fẹ́ gbọ́, ìkànnì kan tá a fẹ́ lọ, ìwé kan tá a fẹ́ kà tàbí géèmù tá a fẹ́ gbá, ṣe là ń yan ohun tá a fẹ́ fi kúnnú ọkàn wa. Ohun tá a bá yàn máa nípa lórí ìwà wa. Ó ṣeni láàánú pé púpọ̀ lára àwọn eré ìnàjú tó wà lónìí ló ní àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra nínú. (Sm 11:5; Ga 5:​19-21) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rọ̀ wá pé ká máa ronú lórí àwọn nǹkan tó máa mú ògo wá fún Jèhófà.​—Flp 4:8.

WO FÍDÍÒ NÁÀ ERÉ ÌNÀJÚ WO LÓ YẸ KÍ N YÀN LÁÀYÒ? KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Ìjà ìjà àjàkú akátá tí wọ́n ń jà ní Róòmù

    Báwo ni ìjà àjàkú akátá tí wọ́n ń jà ní Róòmù láyé àtijọ́ ṣe jọra pẹ̀lú àwọn eré ìnàjú kan lóde òní?

  • Arákùnrin aṣáájú ọ̀nà kan ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí pẹ̀lú ọ̀dọ́kùnrin kan tí wọ́n jọ wà ní ìjọ

    Báwo ni àwọn ará ìjọ ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti yan eré ìnàjú tó gbámúṣé?

  • Ọmọ ogun kan

    Báwo ló ṣe yẹ kí Róòmù 12:9 ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan eré ìnàjú?

  • Àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ń gbá bọ́ọ̀lù

    Irú àwọn eré ìnàjú tó gbámúṣé wo ló wà ní àdúgbò rẹ?

ṢÉ O FẸ́ MÁA ṢE ERÉ ÌNÀJÚ NI ÀBÍ Ó KÀN FẸ́ RÍ OHUN TÍ ẸLÒMÍÌ ṢE?

Àwọn tó ti di gbajúgbajà ní ìdí eré ìnàjú lóde òní ò fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe eré ìnàjú, wọ́n kàn fẹ́ kí wọ́n máa wo ohun tí àwọn ẹlòmíì ṣe. Má gbàgbé pé iṣẹ́ ọpọlọ àwọn ẹlòmíì ni wọ́n máa ń fi hàn nínú fíìmù, ìwé àti ètò orí tẹlifíṣọ̀n, kì í ṣe ìwọ lo ṣe é. Lóòótọ́ kò burú pátápátá tá a bá ń fi ohun táwọn míì ṣe dára yá, àmọ́ ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé àǹfààní pọ̀ níbẹ̀ téèyàn bá ń fúnra rẹ̀ ṣe eré ìnàjú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń fẹ́ lo ohun èlò ìkọrin láti kọrin tàbí kí wọ́n yàwòrán. Àwọn míì fẹ́ràn kí wọ́n máa ṣe àwọn eré ìdárayá míì níta táá jẹ́ kí wọ́n máa sá síbí sá sọ́hùn, àwọn míì sì máa ń lọ wẹ̀ lódò tàbí kí wọ́n jó ijó ìbílẹ̀. Eré ìnàjú èyíkéyìí tá a bá yàn, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a “ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”​—1Kọ 10:31.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́