ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | FÍLÍPÌ 1-4
“Ẹ Má Ṣe Máa Ṣàníyàn Nípa Ohunkóhun”
Àdúrà ni oògùn àníyàn
Tá a bá gbàdúrà, tá a sì ní ìgbàgbọ́, Jèhófà máa fún wa ní àlàáfíà “tó kọjá gbogbo òye”
Lóòótọ́ ó lè jọ pé kò sí ọ̀nà àbáyọ sí àwọn ìṣòro wa, àmọ́ Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á. Ó tiẹ̀ lè ṣe kọjá ohun tá a rò pàápàá.—1Kọ 10:13