MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìwà Mímọ́ àti Ọ̀wọ̀ Tó Jinlẹ̀ Máa Ń Yíni Lọ́kàn Pa Dà
Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwà rere àwọn ìyàwó tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ló máa ń mú kí ọkọ wọn náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́, èyí lè gba pé kí wọ́n fara da àtakò fún ọ̀pọ̀ ọdún. (1Pe 2:21-23; 3:1, 2) Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà ń kojú irú àtakò bẹ́ẹ̀, má ṣe jáwọ́ nínú fífi ire ṣẹ́gun ibi. (Ro 12:21) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ lè gbéṣẹ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ, ó sì lè mú kí ọkọ rẹ yí pa dà kó sì wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Má ṣe máa rin kinkin mọ́ èrò tìẹ, kàkà bẹ́ẹ̀ máa gba ti ẹnì kejì ẹ rò. (Flp 2:3, 4) Máa fìfẹ́ hàn sí i, kó o sì máa ṣe ojúṣe ẹ̀ nínú ilé tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, máa fetí sílẹ̀ dáadáa. (Jem 1:19) Máa ṣe sùúrù, kó o sì jẹ́ kí ẹnì kejì ẹ mọ̀ pé ìfẹ́ rẹ̀ ò kúrò lọ́kàn ẹ. Kódà, tẹ́nì kejì rẹ ò bá fi bẹ́ẹ̀ fìfẹ́ hàn sí ẹ tàbí tí ò bọ̀wọ̀ fún ẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ò ń kojú, ó sì mọyì bó o ṣe jẹ́ olóòótọ́.—1Pe 2:19, 20.
WO FÍDÍÒ NÁÀ JÈHÓFÀ Ń FÚN WA LÓKUN KÁ LÈ GBÉ ẸRÙ WA, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Grace Li nígbà tó ṣègbéyàwó?
Kí ló mú kó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́?
Àwọn ìṣòro wo ni Arábìnrin Li kojú lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi?
Àdúrà wo ni Arábìnrin Li gbà nítorí ọkọ rẹ̀?
Àwọn ìbùkún wo ni Arábìnrin Li ti rí torí pé ó ń hùwà mímọ́, ó sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ ẹ̀?
Ìwà mímọ́ àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ máa ń yíni lọ́kàn pa dà!