MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́?
Tẹ́nì kan bá bi ẹ́ pé kí nìdí tó o fi gbà pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan, kí lo máa sọ? Kó o tó lè fi ìdánilójú dáhùn ìbéèrè yẹn, ohun méjì kan wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe: Lákọ̀ọ́kọ́, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kó dá ìwọ fúnra rẹ lójú pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. (Ro 12:1, 2) Lẹ́yìn náà, o gbọ́dọ̀ ronú nípa bó o ṣe lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fún ẹlòmíì.—Owe 15:28.
Ẹ WO ÀWỌN FÍDÍÒ NÁÀ DÓKÍTÀ TÓ Ń TO EGUNGUN ṢÀLÀYÉ OHUN TÓ GBÀ GBỌ́ ÀTI ONÍMỌ̀ NÍPA ẸRANKO KAN SỌ ÌDÍ TÓ FI GBÀ ỌLỌ́RUN GBỌ́ KẸ́ Ẹ LÈ RÍ ÌDÍ TÁWỌN MÍÌ FI GBÀ PÉ ỌLỌ́RUN LÓ DÁ ÀWỌN NǸKAN, LẸ́YÌN NÁÀ Ẹ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ló mú kí Irène Hof Laurenceau gbà pé ẹnì kan ló dá wa, pé kì í ṣe pé a kàn ṣàdédé wà nípa ẹfolúṣọ̀n?
Kí ló mú kí Yaroslav Dovhanych gbà pé ẹnì kan ló dá wa, pé kì í ṣe pé a kàn ṣàdédé wà nípa ẹfolúṣọ̀n?
Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ìdí tó o fi gbà pé Ọlọ́run ló dá wa fún ẹnì kan?
Àwọn nǹkan wo ni ètò Ọlọ́run ti pèsè ní èdè rẹ, táá jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú, táá sì jẹ́ kó o lè ṣàlàyé fáwọn míì pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan?