January 13-19
JẸ́NẸ́SÍSÌ 3-5
Orin 72 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àbájáde Irọ́ Àkọ́kọ́”: (10 min.)
Jẹ 3:1-5—Èṣù ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́ (w17.02 5 ¶9)
Jẹ 3:6—Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run (w00 11/15 25-26)
Jẹ 3:15-19—Ọlọ́run gégùn-ún fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà (w12 9/1 4 ¶2; w04 1/1 29 ¶2; it-2 186)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Jẹ 4:23, 24—Kí nìdí tí Lámékì fi kọ ewì yìí? (it-2 192 ¶5)
Jẹ 4:26—Ṣé ọ̀nà tó tọ́ làwọn èèyàn fi “bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà” nígbà ayé Énọ́ṣì? (it-1 338 ¶2)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 4:17–5:8 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló wù ẹ lórí nípa bí akéde náà ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Kí la rí kọ́ nípa ìgbà tí akéde náà sọ pé òun máa pa dà wá?
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 1)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 3)
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà, fún un ní ọ̀kan lára ìtẹ̀jáde wa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, tó sọ̀rọ̀ nípa kókó kan tí onílé sọ. (th ẹ̀kọ́ 2)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Bá A Ṣe Lè Fi Àṣàrò Kúkúrú Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò”: (15 min.) Ìjíròrò. Ẹ wo fídíò tó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àṣàrò kúkúrú, lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ jíròrò ẹ̀.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 14 ¶20-21
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 85 àti Àdúrà