ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 3-5
Àbájáde Irọ́ Àkọ́kọ́
Àtìgbà tí Sátánì ti parọ́ fún Éfà ló ti ń ṣi aráyé lọ́nà. (Ifi 12:9) Báwo làwọn irọ́ tí Sátánì pa tó wà nísàlẹ̀ yìí ṣe mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti sún mọ́ Jèhófà?
Kò sí Ọlọ́run
Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run
Ọlọ́run ò lórúkọ
Ọlọ́run máa fi iná ọ̀run àpáàdì dá àwọn èèyàn lóró títí láé
Àmúwá Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí wa
Ọlọ́run ò rí tiwa rò
Báwo làwọn irọ́ yìí ṣe rí lára rẹ?
Kí lo lè ṣe láti gbèjà orúkọ Ọlọ́run?