Ǹjẹ́ Wọ́n Ti Parọ́ fún Ẹ Rí?
ṢÀṢÀ nǹkan ló lè dunni tó kí ẹni tá a fọkàn tán purọ́ fúnni. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè dójú tini, ó lè múnú bíni tàbí kẹ̀, ó lè bani nínú jẹ́. Irọ́ máa ń ba àárín ọ̀rẹ́ àti tọkọtaya jẹ́, àwọn èèyàn sì máa ń purọ́ láti lu àwọn míì ní jìbìtì ọ̀kẹ́ àìmọye owó.
Wá fojú inú wo bó ṣe máa rí lára rẹ tí o bá mọ̀ pé ohun tí wọ́n sọ fún ẹ nípa Ọlọ́run kì í ṣe òótọ́. Tí o bá jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ náà á dùn ẹ́ jù, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí lára àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n sọ̀rọ̀ yìí:
● “Ó dùn mí gan-an nígbà tí mo mọ̀ pé irọ́ ni wọ́n ń pa fún mi ní ṣọ́ọ̀ṣì.”—DEANNE.
● “Inú bí mi. Wọ́n ti tàn mí jẹ, gbogbo ìrètí mi àti ohun tí mo fojú sùn ti já sí òfo.”—LUIS.
O lè má tètè gbà pé wọ́n lè sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ fún ẹ nípa Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ àwọn òbí rẹ, àlùfáà kan, pásítọ̀ kan tàbí ọ̀rẹ́ rẹ àtàtà kan tí kò lè mọ̀ọ́mọ̀ ṣì ọ́ lọ́nà ló kọ́ ẹ ni nǹkan tó o mọ̀. O sì lè ní ohun tó o gbà gbọ́ látìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ. Àmọ́, ṣé o gbà pé ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ lè jẹ́ irọ́? Ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà kan rí, ìyẹn Franklin D. Roosevelt mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kò sí bó o ṣe lè sọ ọ́ tó, irọ́ kò lè di òótọ́ láé.”
Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá wọ́n ti purọ́ fún ẹ? Lákòókò kan tí Jésù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní àwọn ohun tí a lè fi dá òtítọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí irọ́.
O ò ṣe kà nípa bí Bíbélì ṣe tú àṣírí irọ́ márùn-ún táwọn èèyàn sábà máa ń pa nípa Ọlọ́run? Wàá rí i bí òtítọ́ ṣe lè yí ìgbésí ayé rẹ pa dà sí rere.