MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bá A Ṣe Lè Fi Àṣàrò Kúkúrú Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò
Láti January 2018 la ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé apá tá a pè ní ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ sí iwájú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Àtìgbà yẹn la ti ń pọkàn pọ̀ sí bíba àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ dípò ká kàn máa fún wọn láwọn ìwé wa. A tún ṣe àwọn fídíò ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ kó lè rọrùn fún wa láti mọ bá a ṣe lè fi Bíbélì nìkan wàásù. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò fẹ́ ká máa lo àwọn ìtẹ̀jáde wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé dé ilé mọ́ ni? Rárá o! Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa gbéṣẹ́ gan-an láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. A lè gbìyànjú àwọn àbá yìí tá a bá fẹ́ lo èyíkéyìí nínú àwọn àṣàrò kúkúrú náà:
Béèrè ìbéèrè tó wà níwájú àṣàrò kúkúrú náà, kó o sì ní kẹ́ni náà yan ìdáhùn tó rò pé ó tọ́.
Fi ìdáhùn Bíbélì tó wà ní ojú ìwé kejì hàn onílé náà. Tí àkókò bá wà, o lè ka àwọn àlàyé díẹ̀ fún un látinú àṣàrò kúkúrú náà.
Fún un ní àṣàrò kúkúrú náà kó o sì ní kó ka àwọn àlàyé tó kù láyè ara ẹ̀.
Fi àwọn ìbéèrè tó wà lábẹ́ “Rò Ó Wò Ná” han onílé náà kó o sì ṣètò láti pa dà wá jíròrò ẹ̀ nígbà míì.
Nígbà tó o bá pa dà lọ, jíròrò ìbéèrè tó o fi sílẹ̀ kó o sì tún fi ìbéèrè míì sílẹ̀ fún un. O lè yan ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó wà lórí ìkànnì wa tàbí lára èyí tó wà nínú ìtẹ̀jáde tá a tọ́ka sí lẹ́yìn àṣàrò kúkúrú náà. O lè fún onílé náà ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó o bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.