ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 3 ojú ìwé 6
  • Lo Ìbéèrè Bó Ṣe Yẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lo Ìbéèrè Bó Ṣe Yẹ
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Múná Dóko
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 3 ojú ìwé 6

Ẹ̀KỌ́ 3

Lo Ìbéèrè Bó Ṣe Yẹ

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Mátíù 16:13-16

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Fi ọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, táá mú kí wọ́n máa fọkàn bá ẹ lọ, táá mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀, táá sì gbé àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ yọ.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ kí wọ́n sì máa fọkàn bá ẹ lọ. Bi wọ́n ní ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tàbí èyí táá jẹ́ kí wọ́n máa fojú sọ́nà fún ìdáhùn.

  • Mú kí wọ́n ronú lórí kókó ọ̀rọ̀ kan. Jẹ́ kí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ rí i pé àlàyé rẹ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, o lè béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé ohun tí ò ń sọ bọ́gbọ́n mu lóòótọ́.

  • Jẹ́ kí àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere. Tó o bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa kókó pàtàkì kan, kọ́kọ́ béèrè ìbéèrè kan tó gbàfíyèsí. Béèrè àwọn ìbéèrè kan lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ nípa kókó pàtàkì kan tàbí nígbà tó o bá fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ.

    Àwọn àbá

    Lẹ́yìn tó o bá ti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, fi ìbéèrè gbé kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ yọ.

LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa kókó kan, kó o wá sọ pé kí ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ sọ èrò rẹ̀. Fetí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tó bá sọ. Fi òye mọ ìgbà tó yẹ kó o fọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè kan àti bó ṣe yẹ kó o béèrè.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́