Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin Tiẹ̀ Jẹ Ọlọ́run Lógún?
“Obìnrin ló fa ẹ̀ṣẹ̀ sínú ayé, òun ni ó fa ikú wá sórí gbogbo wa pátá.”—ÌWÉ ECCLESIASTICUS, ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KEJÌ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI.
“Ẹ̀yin ni ẹ kọ́kọ́ gba èṣù láyè: ẹ̀yin ni ẹ kọ́kọ́ lọ jẹ èso igi tí Ọlọ́run kà léèwọ̀: ẹ̀yin lẹ kọ́kọ́ tẹ òfin Ọlọ́run lójú . . . Ẹ̀yin ni ẹ bá ọkùnrin tó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run kanlẹ̀ wẹ́rẹ́.”—TERTULLIAN, NÍNÚ ÌWÉ ON THE APPAREL OF WOMEN, TÓ KỌ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KEJÌ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI.
INÚ Bíbélì kọ́ ni wọ́n ti rí àwọn àyọkà tó ti wà tipẹ́tipẹ́ yìí. Láti ọdúnmọ́dún ni àwọn èèyàn ti ń lo irú àwọn àyọkà yìí láti fi dá ṣíṣàìka àwọn obìnrin sí láre. Kódà lóde òní, àwọn agbawèrèmẹ́sìn ṣì máa ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ inú ìwé ẹ̀sìn láti fi ṣe ẹ̀rí pé ó bófin mu láti máa tẹ àwọn obìnrin lórí ba, torí wọ́n ní àwọn obìnrin ló fa àwọn ìṣòro tó dé bá gbogbo aráyé. Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run pète pé kí àwọn ọkùnrin máa fi ojú àwọn obìnrin gbolẹ̀, kí wọ́n sì máa kàn wọ́n lábùkù? Kí ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.
Ṣé Ọlọ́run gégùn-ún fún àwọn obìnrin ni?
Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù” ni Ọlọ́run gé “ègún” fún. (Ìṣípayá 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:14) Nígbà tí Ọlọ́run sọ pé Ádámù yóò “jọba lé” ìyàwó rẹ̀ lórí, kì í ṣe pé ó ń fi hàn pé òun fọwọ́ sí bí àwọn ọkùnrin ṣe ń tẹ àwọn obìnrin lórí ba. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Ṣe ló kàn ń sọ àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe fún tọkọtaya àkọ́kọ́ yẹn.
Nítorí náà, bí àwọn èèyàn ṣe ń fi ojú àwọn obìnrin gbolẹ̀ kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àbájáde jíjẹ́ tí àwa èèyàn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Bíbélì kò fọwọ́ sí èrò àwọn tó sọ pé àwọn ọkùnrin gbọ́dọ̀ máa tẹ àwọn obìnrin lórí ba kí ìyẹn lè jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀.—Róòmù 5:12.
Ǹjẹ́ Ọlọ́run dá obìnrin ní ẹni tó rẹlẹ̀ sí ọkùnrin?
Rárá. Jẹ́nẹ́sísì 1:27 sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” Èyí fi hàn pé láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọlọ́run ti dá àwa èèyàn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lọ́nà tí a ó fi lè máa hùwà bíi tirẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà lọ́nà tó yàtọ̀ síra ní ti ìrísí wọn àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn, irú ìtọ́ni kan náà ni wọ́n jọ gbà, ẹ̀tọ́ kan náà ni wọ́n sì jọ ní lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28-31.
Kí Ọlọ́run tó dá Éfà ló ti sọ pé: “Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un [ìyẹn Ádámù], gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Ṣé ohun tí ọ̀rọ̀ náà “àṣekún” ń fi hàn ni pé obìnrin rẹlẹ̀ sí ọkùnrin? Rárá, torí pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí àṣekún nínú ẹsẹ Bíbélì yìí tún lè túmọ̀ sí “ẹnì kejì” tàbí ‘olùrànlọ́wọ́ tó bá ọkùnrin ṣe rẹ́gí.’ A lè fi ohun tí à ń sọ yìí wé bí iṣẹ́ dókítà oníṣẹ́ abẹ àti iṣẹ́ oníṣègùn apàmọ̀lára ṣe máa ń wọnú ara wọn nígbà iṣẹ́ abẹ. Ǹjẹ́ ọ̀kan nínú wọn lè dá ṣiṣẹ́ láìsí ẹnì kejì? Ìyẹn á ṣòro! Lóòótọ́, dókítà oníṣẹ́ abẹ ló máa ṣe iṣẹ́ abẹ náà, àmọ́ ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé iṣẹ́ rẹ̀ ṣe pàtàkì ju ti oníṣègùn apàmọ̀lára? A ò lè sọ bẹ́ẹ̀ o. Lọ́nà kan náà, ṣe ni Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin kí wọ́n jọ máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kì í ṣe pé kí wọ́n máa bára wọn díje.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24.
Kí ló fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin jẹ Ọlọ́run lógún?
Nítorí pé Ọlọ́run ti rí ohun tí àwọn ọkùnrin aláìpé, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ máa ṣe, ó jẹ́ kó hàn kedere láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn pé òun fẹ́ láti dáàbò bo àwọn obìnrin. Nígbà tí obìnrin òǹkọ̀wé náà, Laure Aynard, ń sọ̀rọ̀ nípa Òfin Mósè, èyí tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sọ nínú ìwé rẹ̀ La Bible au féminin (Ọwọ́ Tí Bíbélì Fi Mú Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin), pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ibi tí Òfin Mósè ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin jẹ́ láti dáàbò bò wọ́n.”
Bí àpẹẹrẹ, Òfin Mósè pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ máa bọlá fún bàbá àti ìyá wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. (Ẹ́kísódù 20:12; 21:15, 17) Ó tún ní kí àwọn èèyàn máa gba ti àwọn aboyún rò dáadáa. (Ẹ́kísódù 21:22) Kódà, tí a bá fi ààbò tí àwọn obìnrin ní lábẹ́ òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wé bí wọ́n ṣe ń fi àwọn ẹ̀tọ́ tí òfin là sílẹ̀ du àwọn obìnrin ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lóde òní, a ó rí i pé gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ni àwọn òfin Ọlọ́run fi ta yọ. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ṣì wà tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin jẹ Ọlọ́run lógún.
Òfin Tó Jẹ́ Ká Rí Irú Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Obìnrin
Òfin tí Jèhófà Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lọ́kùnrin àti lóbìnrin jàǹfààní rẹpẹtẹ nípa ti ara, kí wọ́n ní ìwà tó dára, kí wọ́n sì sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́. Láwọn ìgbà tí orílẹ̀-èdè náà fetí sí Ọlọ́run, tí wọ́n ń pa òfin rẹ̀ mọ́, ṣe ni wọ́n “ga lékè gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Diutarónómì 28:1, 2) Ẹ̀tọ́ wo ni àwọn obìnrin ní lábẹ́ Òfin Mósè? Wo àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí.
1. Olúkúlùkù wọn ní òmìnira. Láyé àtijọ́, àwọn obìnrin ọmọ Ísírẹ́lì ní òmìnira púpọ̀ gan-an, wọn kò dà bí àwọn obìnrin tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Bí àpẹẹrẹ, lóòótọ́ ọkọ ni Ọlọ́run yàn ṣe olórí nínú ìdílé, síbẹ̀ aya tí ọkọ rẹ̀ fọkàn tán dáadáa lè ‘gbé pápá kan yẹ̀ wò, kí ó rí i gbà, kí ó sì fi gbin ọgbà àjàrà.’ Tó bá sì mọ bí wọ́n ṣe ń rànwú tàbí bí wọ́n ṣe ń hun aṣọ, ó lè dá ní òwò tirẹ̀. (Òwe 31:11, 16-19) Lábẹ́ Òfin Mósè, gbogbo obìnrin ló ní ẹ̀tọ́ tiwọn, wọn kò kà wọ́n sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan láwùjọ àwọn ọkùnrin.
Ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn obìnrin ní òmìnira láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run fúnra wọn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Hánà tó gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa ọ̀ràn kan tó jẹ ẹ́ lógún, ó sì tún jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan ní ìdákọ́ńkọ́. (1 Sámúẹ́lì 1:11, 24-28) Bákan náà, obìnrin ará Ṣúnẹ́mù kan sábà máa ń lọ sọ́dọ̀ wòlíì Èlíṣà ní ọjọ́ Sábáàtì. (2 Àwọn Ọba 4:22-25) Ọlọ́run tiẹ̀ yan àwọn obìnrin kan ṣe aṣojú rẹ̀, irú bíi Dèbórà àti Húlídà. Kódà, àwọn ọkùnrin pàtàkì àti àwọn àlùfáà kan tó gbajúmọ̀ lọ gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ irú àwọn obìnrin yìí.—Àwọn Onídàájọ́ 4:4-8; 2 Àwọn Ọba 22:14-16, 20.
2. Àwọn obìnrin láǹfààní láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Níwọ̀n bí àwọn obìnrin ti wà lára àwọn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú Òfin, Ọlọ́run ní kí àwọn náà máa wá fetí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ka Òfin Mósè, èyí sì jẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́. (Diutarónómì 31:12; Nehemáyà 8:2, 8) Wọ́n tún lè gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n á fi lè kópa nínú apá kan lára ètò ìjọsìn ní àwùjọ. Bí àpẹẹrẹ, ó jọ pé àwọn obìnrin kan máa ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn àfètòṣe” níbi àgọ́ ìjọsìn, àwọn míì sì wà lára àwọn akọrin.—Ẹ́kísódù 38:8; 1 Kíróníkà 25:5, 6.
Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin máa ń kọ́ iṣẹ́, wọ́n sì tún mọ bí wọ́n ṣe lè ṣòwò kí wọ́n sì jèrè. (Òwe 31:24) Àṣà àwọn orílẹ̀-èdè yòókù láyé ìgbà yẹn ni pé bàbá nìkan ló máa ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ìyá náà ní láti kópa nínú kíkọ́ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin títí tó fi máa dàgbà. (Òwe 31:1) Èyí fi hàn kedere pé àwọn obìnrin Ísírẹ́lì ìgbàanì kì í ṣe púrúǹtù rárá.
3. Wọ́n ń bọlá fún àwọn obìnrin, wọ́n sì ń fọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n. Nínú Òfin Mẹ́wàá, Ọlọ́run sọ ọ́ kedere pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:12) Ó wà nínú òwe Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.”—Òwe 1:8.
Òfin Mósè pèsè ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtọ́ni nípa bí ó ṣe yẹ kí àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó máa hùwà sí ara wọn, ó ní kí àwọn ọkùnrin máa fi ọ̀wọ̀ àwọn obìnrin wọ̀ wọ́n. (Léfítíkù 18:6, 9; Diutarónómì 22:25, 26) Bákan náà, ọkọ rere gbọ́dọ̀ máa rántí pé ó ní ibi tí agbára aya òun mọ, kó sì máa fi àwọn ìyípadà tó máa ń wáyé déédéé nínú ara rẹ̀ sọ́kàn.—Léfítíkù 18:19.
4. Wọn kò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n. Jèhófà fi hàn nínú Bíbélì Ọrọ̀ rẹ̀ pé òun ni “baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti onídàájọ́ fún àwọn opó.” Ìyẹn ni pé òun ni Olùdáàbòbò àwọn tí kò ní baba tàbí àwọn tí kò ní ọkọ tí yóò máa jà fún ẹ̀tọ́ wọn. (Sáàmù 68:5; Diutarónómì 10:17, 18) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, nígbà tí ẹnì kan fẹ́ fojú aya wòlíì kan tó ti kú gbolẹ̀ torí pé ìdílé opó yìí jẹ ẹ́ ní gbèsè, Jèhófà dá sí i, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu kan kí obìnrin náà lè gbọ́ bùkátà rẹ̀ kí ojú má bàa tì í.—2 Àwọn Ọba 4:1-7.
Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Sélóféhádì tó jẹ́ olórí ìdílé kú láì bí ọmọkùnrin kankan. Àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ márààrún wá bẹ Mósè pé kí ó fún àwọn ní “ohun ìní” ní Ilẹ̀ Ìlérí. Ohun tí Jèhófà ní kí Mósè fún wọn tiẹ̀ ju ohun tí wọ́n béèrè lọ. Ó sọ fún Mósè pé: “Fún wọn ní ohun ìní ti ogún ní àárín àwọn arákùnrin baba wọn, kí o sì mú kí ogún baba wọn kọjá sọ́dọ̀ wọn.” Látìgbà yẹn ló ti di pé àwọn obìnrin ní Ísírẹ́lì lè gba ogún lọ́dọ̀ bàbá wọn, kí ọmọ tiwọn sì wá jogún rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn.—Númérì 27:1-8.
Wọ́n Túmọ̀ Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Obìnrin Gba Ọ̀nà Òdì
Lábẹ́ Òfin Mósè, ojú pàtàkì ni àwọn èèyàn fi ń wo àwọn obìnrin, wọn kì í sì í fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n. Ṣùgbọ́n láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àṣà àwọn Gíríìkì tí wọ́n ka àwọn obìnrin sí ẹni tó rẹlẹ̀ sí àwọn ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí ìsìn àwọn Júù.—Wo àpótí náà “Ìwà Ẹ̀tanú sí Àwọn Obìnrin Nínú Àwọn Ìwé Ayé Ìgbàanì.”
Bí àpẹẹrẹ, akéwì ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń jẹ́ Hesiod, tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, sọ pé àwọn obìnrin ló fa gbogbo ìṣòro tí aráyé ní. Ó sọ nínú ìwé rẹ̀ kan tó pè ní Theogony pé, “ṣe ni olubi ìran àti ẹ̀yà àwọn obìnrin tó ń gbé láàárín ìran àwọn ọkùnrin kàn ń kó wọn sí ìyọnu ṣáá.” Èrò rẹ̀ yìí wá gbilẹ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìwé Támọ́dì tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni kìlọ̀ fún àwọn ọkùnrin pé: “Ẹ má ṣe bá àwọn obìnrin sọ̀rọ̀ púpọ̀, torí ìṣekúṣe ló máa yọrí sí.”
Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá ni èrò náà pé àwọn obìnrin kò ṣeé fọkàn tán ti ń ṣàkóbá fún ipa tó yẹ kí àwọn obìnrin máa kó láwùjọ àwọn Júù. Nígbà ayé Jésù, wọ́n ti fi ibi tí àwọn obìnrin lè dé nínú tẹ́ńpìlì mọ sí Àgbàlá Àwọn Obìnrin nìkan. Àwọn ọkùnrin nìkan ni wọ́n ń kọ́ ní ẹ̀kọ́ ìsìn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa ń ya àwọn obìnrin sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin nínú sínágọ́gù. Ìwé Támọ́dì fa ọ̀rọ̀ tí Rábì kan sọ yọ, ó ní Rábì náà sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ń kọ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní Tórà [ìyẹn Òfin Mósè], ìwà ìbàjẹ́ ló ń gbìn sí i lọ́kàn.” Bí àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe wá túmọ̀ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn obìnrin gba ọ̀nà òdì, ṣe ni wọ́n mú kí ọ̀pọ̀ ọkùnrin máa kórìíra àwọn obìnrin.
Nígbà tí Jésù wà ní ayé, ó ṣàkíyèsí irú àwọn ìwà ẹ̀tanú bẹ́ẹ̀, èyí tó ń jẹ yọ látinú àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́. (Mátíù 15:6, 9; 26:7-11) Ǹjẹ́ irú ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn nípa lórí ọwọ́ tó fi ń mú àwọn obìnrin? Kí la lè rí kọ́ nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀? Ǹjẹ́ ìsìn Kristẹni tòótọ́ tiẹ̀ ń mú ìtura bá àwọn obìnrin? A ó rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.