ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 9/1 ojú ìwé 3
  • Ìṣòro Tí Àwọn Obìnrin Ń Bá Yí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣòro Tí Àwọn Obìnrin Ń Bá Yí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Àwọn Obìnrin Tiẹ̀ Jẹ Ọlọ́run Lógún?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Fífìyà Jẹ Àwọn Obìnrin Ti Di Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Jí!—2008
  • “Awọn Obinrin Ti Wọn Nṣiṣẹ Kára Ninu Oluwa”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Wọ́n Wà Ní Ipò Ọ̀wọ̀ àti Iyì Lójú Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 9/1 ojú ìwé 3

Ìṣòro Tí Àwọn Obìnrin Ń Bá Yí

“Nígbà tí mo wo ohun tí àwọn èèyàn máa ń fojú obìnrin rí, kò wù mí rárá kí n kúrò nípò ọmọdébìnrin.”​—ZAHRA, ỌMỌ ỌDÚN MẸ́Ẹ̀Ẹ́DÓGÚN, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà nínú ìwé ìròyìn GEO, lédè Faransé.

Ọ̀RỌ̀ ọmọbìnrin tí a fà yọ sí apá ọ̀tún yìí pe àfiyèsí sí ohun tó burú jáì kan tó ń ṣẹlẹ̀. Ìyẹn ni pé jákèjádò ayé, wọ́n máa ń hùwà ipá sí àwọn obìnrin lọ́mọdé lágbà, wọ́n sì máa ń ṣàìkà wọ́n sí jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Wo àwọn òótọ́ pọ́ńbélé yìí.

  • Ṣíṣàìka ẹ̀yà obìnrin sí. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn òbí ní ilẹ̀ Éṣíà ló jẹ́ pé ọmọkùnrin ni wọ́n máa ń fẹ́ kí àwọn bí dípò ọmọbìnrin. Ní ọdún 2011, ìròyìn kan látọ̀dọ̀ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rìnléláàádóje [134] obìnrin ni ilẹ̀ Éṣíà ti pàdánù torí pé wọ́n ṣẹ́ oyún wọn dà nù, wọ́n pa wọ́n nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé tàbí nítorí àìrí ìtọ́jú.

  • Ẹ̀kọ́ Ìwé. Kárí ayé, tí a bá rí ẹni mẹ́ta tí kò kàwé rárá tàbí tí kò kà tó ìwé ọdún mẹ́rin, méjì nínú wọn máa jẹ́ obìnrin.

  • Fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni. Ó ju bílíọ̀nù méjì ààbọ̀ obìnrin tó ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò ti ka fífi ipá bá aya ẹni lò pọ̀ sí ìwà ọ̀daràn títí di báyìí.

  • Ìlera. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, nǹkan bí ìṣẹ́jú méjì-méjì ni obìnrin kọ̀ọ̀kan ń kú látàrí àwọn ìṣòro tó máa ń jẹ yọ nígbà oyún tàbí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bímọ, nítorí pé wọn kò rí ìtọ́jú ìṣègùn tó yẹ gbà.

  • Ẹ̀tọ́ láti ní dúkìá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin ló máa ń gbin èyí tó ju ìdajì lọ nínú àwọn ọ̀gbìn oko tó wà lágbàáyé, síbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wọn kò ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti ra ilẹ̀ tàbí kí wọ́n jogún ilẹ̀.

Kí nìdí tí àwọn èèyàn fi ń fi àwọn ẹ̀tọ́ tó yẹ kí gbogbo èèyàn ní yìí du àwọn obìnrin? Ìdí ni pé ní àwọn ilẹ̀ kan, wọ́n máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀sìn àti àṣà tó fàyè gba fífi ojú àwọn obìnrin gbolẹ̀ àti híhu ìwà ipá sí wọn, tàbí kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀sìn àti àṣà tó dá irú nǹkan bẹ́ẹ̀ láre. Ìwé ìròyìn kan nílẹ̀ Faransé fa ọ̀rọ̀ obìnrin agbẹjọ́rò ọmọ ilẹ̀ Íńdíà kan tó ń jẹ́ Chandra Rami Chopra yọ, ó sọ pé: “Ohun kan wọ́pọ̀ nínú òfin gbogbo ẹ̀sìn, ohun náà sì ni pé gbogbo wọ́n ti àṣà ṣíṣàìka àwọn obìnrin sí lẹ́yìn.”

Ṣé o gbà pé òótọ́ ni obìnrin yẹn sọ? Ǹjẹ́ o rò pé Bíbélì ka àwọn obìnrin sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan bíi ti ọ̀pọ̀ ìwé ìsìn yòókù? Àwọn kan máa ń ronú pé ó dà bíi pé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan ti irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn. Àmọ́ irú ojú wo ni Ọlọ́run tó ni Bíbélì fi ń wo àwọn obìnrin? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yìí gbẹgẹ́ gan-an, ó sì máa ń ta àwọn èèyàn lára, síbẹ̀ tí a bá fara balẹ̀, tí a sì fi òótọ́ inú ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀, a máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́