ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 6-8
“Ó Ṣe Bẹ́ẹ̀ Gẹ́lẹ́”
Fojú inú wo ohun tó máa ná Nóà àti ìdílé rẹ̀ kí wọ́n tó lè kan ọkọ̀ áàkì náà láìsí ohun èlò ìgbàlódé tàbí ìmọ̀ nípa iṣẹ́ ẹ̀rọ.
Áàkì náà tóbi gan-an. Gígùn rẹ̀ tó nǹkan bíi mítà mẹ́tàléláàádóje (133), fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ mítà méjìlélógún (22), gíga rẹ̀ sì jẹ́ mítà mẹ́tàlá (13)
Wọ́n ní láti gé igi tó pọ̀ gan-an, kí wọ́n là á, kí wọ́n sì kó wọn wá síbi tí wọ́n ti máa kan ọkọ̀ náà
Wọ́n ní láti fi ọ̀dà bítúmẹ́nì kùn ún tinú tòde
Wọ́n ní láti kó oúnjẹ tí gbogbo ìdílé wọn máa jẹ fún ọdún kan sínú áàkì náà títí kan tàwọn ẹranko tó wà pẹ̀lú wọn
Ó tó nǹkan bí ogójì (40) sí àádọ́ta (50) ọdún kí wọ́n tó lè parí iṣẹ́ náà
Báwo ni ìtàn Nóà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tó bá ṣòro fún wa láti ṣe ohun tí Jèhófà ní ká ṣe?