ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 24
Bí Ísákì Ṣe Rí Ìyàwó
Ìránṣẹ́ Ábúráhámù bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ láti rí ìyàwó gidi fún Ísákì. (Jẹ 24:42-44) Ó yẹ káwa náà máa bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà ká tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé wa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Gbàdúrà
Ka ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run sọ kó o tó ṣèpinnu
Gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn