Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
APRIL 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 31
“Jékọ́bù àti Lábánì Dá Májẹ̀mú Àlàáfíà”
it-1 883 ¶1
Gáléédì
Jékọ́bù àti Lábánì dá májẹ̀mú kí àlàáfíà lè jọba láàárín wọn. Nígbà tí wọ́n fẹ́ dá májẹ̀mú yìí, Jékọ́bù gbé òkúta kan dúró bí òpó, ó sì sọ fún “àwọn arákùnrin” rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe òkìtì òkúta tó ṣeé ṣe kó dà bíi tábìlì, orí ẹ̀ sì ni wọ́n ti jẹ oúnjẹ májẹ̀mú náà. Lẹ́yìn ìyẹn, Lábánì pe ibẹ̀ ní “Jegari-sáhádútà” lédè Árámáíkì (tàbí Síríà) àmọ́ Jékọ́bù pe ibẹ̀ ní “Gáléédì” tó jẹ́ èdè Hébérù. Lábánì sọ pé: “Òkìtì yìí [gal lédè Hébérù] jẹ́ ẹ̀rí [ʽedh lédè Hébérù] láàárín èmi àti ìwọ lónìí.” (Jẹ 31:44-48) Òkìtì òkúta náà (àti òkúta tó dúró bí òpó) jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo àwọn tó ń gba ibẹ̀ kọjá. Bí ẹsẹ 49 ṣe sọ ọ́ gan-an ló rí, ó ní, “Ilé Ìṣọ́ [mits·pahʹ lédè Hébérù],” jẹ́ ẹ̀rí pé Jékọ́bù àti Lábánì ti jọ ṣàdéhùn pé àlàáfíà máa wà láàárín ìdílé méjèèjì. (Jẹ 31:50-53) Bíbélì tún mẹ́nu kan àwọn ìgbà míì tí wọ́n fi òkúta ṣe ẹ̀rí.—Joṣ 4:4-7; 24:25-27.
it-2 1172
Ilé Ìṣọ́
Òkìtì òkúta kan tí Jékọ́bù ṣe, tó sì pè ní “Gáléédì” (tó túmọ̀ sí “Òkìtì Ẹ̀rí”) àti “Ilé Ìṣọ́.” Lábánì wá sọ pé: “Kí Jèhófà máa ṣọ́ èmi àti ìwọ tí a ò bá sí nítòsí ara wa.” (Jẹ 31:45-49) Òkìtì òkúta yìí jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà ń kíyè sí Jékọ́bù àti Lábánì láti mọ̀ bóyá wọ́n á mú májẹ̀mú àlàáfíà náà ṣẹ.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 1087-1088
Tẹ́ráfímù
Ìwádìí táwọn awalẹ̀pìtàn ṣe ní agbègbè Mesopotámíà fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹni tí ère tẹ́ráfímù bá wà lọ́wọ́ ẹ̀ ló máa gba ogún ìdílé náà. Bó ṣe wà nínú àfọ́kù òkúta kan tí wọ́n rí ní Nuzi, tí ọkùnrin kan bá ní àwọn òrìṣà ìdílé bàbá ìyàwó rẹ̀ lọ́wọ́, ọkùnrin náà lè lọ sílé ẹjọ́, kó sì gba ogún ìdílé náà lẹ́yìn tí bàbá ìyàwó rẹ̀ bá kú. (Ancient Near Eastern Texts, ti J. Pritchard, 1974, ojú ìwé 219, 220, àti àlàyé ìsàlẹ̀ 51) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó wà lọ́kàn Réṣẹ́lì nìyẹn, kó ronú pé kò sóhun tó burú nínú bóun ṣe jí ère náà, ó ṣe tán ọ̀pọ̀ ìgbà ni bàbá rẹ̀ gbìyànjú láti rẹ́ Jékọ́bù ọkọ rẹ̀ jẹ. (Fi wé Jẹ 31:14-16.) Ohun míì tó tún jẹ́ ká rí i pé ó ṣeé ṣe kí ẹni tó bá ní ère tẹ́ráfímù náà lọ́wọ́ gba ogún ìdílé náà ni bí Lábánì ṣe ń wá ère náà lójú méjèèjì débi tó fi mú àwọn arákùnrin rẹ̀ tó sì lépa Jékọ́bù fún ọjọ́ méje. (Jẹ 31:19-30) Ohun kan ni pé Jékọ́bù ò mọ nǹkan kan nípa ohun tí Réṣẹ́lì ṣe (Jẹ 31:32), a ò sì rí i kà pé Jékọ́bù gbìyànjú láti lo tẹ́ráfímù náà kó lè gba ogún Lábánì lọ́wọ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Jékọ́bù ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn ọlọ́run èké. Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé tẹ́ráfímù náà wà lára àwọn ọlọ́run àjèjì tí wọ́n kó dànù nígbà tí Jékọ́bù kó gbogbo àwọn ọlọ́run àjèjì tí àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ fún un, tó sì rì wọ́n mọ́lẹ̀ lábẹ́ igi ńlá tó wà nítòsí Ṣékémù.—Jẹ 35:1-4.
Jèhófà Ni Ibùgbé wa
8 Nígbà tí Jékọ́bù dé Háránì, ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó fi Léà àti Rákélì fún un gẹ́gẹ́ bí aya. Àmọ́, nígbà tó yá, Lábánì bẹ̀rẹ̀ sí yan Jékọ́bù jẹ, ó sì yí owó ọ̀yà rẹ̀ pa dà nígbà mẹ́wàá. (Jẹ́n. 31:41, 42) Síbẹ̀, Jékọ́bù fara da gbogbo èyí torí pé ó ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà máa tọ́jú òun. Látàrí èyí, Jèhófà bù kún Jékọ́bù. Lọ́nà wo? Nígbà tí Jèhófà fi máa sọ fún un pé kó pa dà sí ilẹ̀ Kénáánì, ó ti ní “ọ̀pọ̀ agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti àwọn ràkúnmí àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” (Jẹ́n. 30:43) Inú Jékọ́bù dùn, ó sì gbàdúrà sí Jèhófà láti dúpẹ́ oore tó ṣe fún un. Ó ní: “Èmi kò yẹ fún gbogbo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti gbogbo ìṣòtítọ́ tí o ti ṣe sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí pẹ̀lú ọ̀pá mi nìkan ṣoṣo ni mo sọdá Jọ́dánì yìí, mo sì ti di ibùdó méjì nísinsìnyí.”—Jẹ́n. 32:10.
Bíbélì Kíkà
APRIL 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 32-33
“Ṣé Ò Ń Jìjàkadì Kó O Lè Gba Ìbùkún?”
Ǹjẹ́ Ò Ń Wá Jèhófà Tọkàntọkàn?
Àpẹẹrẹ àwọn tó ti sapá gidigidi láti wá Jèhófà pọ̀ gan-an nínú Ìwé Mímọ́. Ọ̀kan lára wọn ni Jékọ́bù, tó wọ̀yá ìjà pẹ̀lú áńgẹ́lì Ọlọ́run títí ilẹ̀ fi mọ́. Ìdí rèé tá a fi sọ Jékọ́bù ní Ísírẹ́lì (Ẹni tó bá Ọlọ́run wọ̀jà) nítorí pé ó wọ̀jà pẹ̀lú Ọlọ́run, tàbí pé ó “lo ara rẹ̀.” Áńgẹ́lì náà bù kún un nítorí ìsapá tó fi gbogbo ọkàn ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 32:24-30.
it-2 190
Arọ
Jékọ́bù Ń Tiro. Nígbà tí Jékọ́bù jẹ́ nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún (97), òun àti áńgẹ́lì Ọlọ́run jìjàkadì láti òru mọ́jú. Kò jẹ́ kí áńgẹ́lì náà lọ títí áńgẹ́lì náà fi bù kún un. Nígbà tí wọ́n ń jìjàkadì, áńgẹ́lì náà fọwọ́ kan egungun ìbàdí rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀. Ìyẹn mú kí Jékọ́bù bẹ̀rẹ̀ sí í tiro. (Jẹ 32:24-32; Ho 12:2-4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé áńgẹ́lì náà sọ fún Jékọ́bù pé ó “ti bá Ọlọ́run [áńgẹ́lì Ọlọ́run] àti èèyàn wọ̀jà, [ó] sì ti wá borí,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jékọ́bù lè borí áńgẹ́lì Ọlọ́run tó jẹ́ alágbára nínú ìjàkadì. Ọlọ́run kàn fàyè gba Jékọ́bù láti bá áńgẹ́lì náà jìjàkadì kó lè hàn gbangba pé Jékọ́bù mọyì gbígba ìbùkún Ọlọ́run, ó sì tiraka kó lè rí ìbùkún náà gbà.
it-1 1228
Ísírẹ́lì
1. Orúkọ tí Ọlọ́run fún Jékọ́bù nígbà tó wà ní nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-un (97). Alẹ́ ọjọ́ tí Jékọ́bù sọdá odò Jábókù nígbà tó fẹ́ lọ pàdé Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀ ló bá ẹnì kan jìjàkadì láìmọ̀ pé áńgẹ́lì ni. Torí pé Jékọ́bù forí tì í bó ṣe ń bá áńgẹ́lì náà jà, ó gba ìbùkún, a sì yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Ísírẹ́lì. Kí Jékọ́bù lè máa rántí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ó pe orúkọ ibẹ̀ ní Péníélì tàbí Pénúélì. (Jẹ 32:22-31; wo JÉKỌ́BÙ No. 1.) Nígbà tó yá tí Jékọ́bù wà ní Bẹ́tẹ́lì, Ọlọ́run tún fi dá a lójú pé òun ti yí orúkọ ẹ̀ pa dà, àtìgbà yẹn ni wọ́n tí ń pe Jékọ́bù ní Ísírẹ́lì títí tó fi kú. (Jẹ 35:10, 15; 50:2; 1Kr 1:34) Ó ju ìgbà ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (2,500) tí Bíbélì lọ orúkọ náà Ísírẹ́lì, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù ló máa ń tọ́ka sí.—Ẹk 5:1, 2.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ọ̀rọ̀ Tútù Máa Ń Mú Kí Àjọṣe Wa Pẹ̀lú Àwọn Míì Sunwọ̀n Sí I
10 Ọ̀rọ̀ tútù àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán lè mú ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, kí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ sì tọ́jọ́. Ká sòótọ́, bá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí àjọse wa pẹ̀lú àwọn míì sunwọ̀n sí i, ìyẹn lè mú kó túbọ̀ rọrùn láti bá wọn sọ̀rọ̀. Bá a bá ń lo ìdánúṣe láti ṣe ohun rere fáwọn èèyàn látọkàn wá, bíi ká ràn wọ́n lọ́wọ́, ká fínnú fíndọ̀ fún wọn ní ẹ̀bùn, ká sì fi ìwà ọ̀làwọ́ hàn sí wọn, ìyẹn lè mú ká máa bára wa sọ̀rọ̀ fàlàlà. Ó sì tún lè “kó òkìtì ẹyín iná” léni lórí, èyí ni pé kó mú àwọn ànímọ́ tó dára jù lọ jáde, kó sì wá túbọ̀ rọrùn láti yanjú àwọn ìṣòro tó bá wáyé.—Róòmù 12:20, 21.
11 Jékọ́bù baba ńlá mọ̀ pé ohun tó yẹ kéèyàn ṣe gan-an nìyẹn. Ísọ̀ bínú gan-an sí Jékọ́bù tó jẹ́ ìbejì rẹ̀; Jékọ́bù sì ní láti sá lọ kí Ísọ̀ má bàa pa á. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Jékọ́bù pa dà wálé. Ísọ̀ wá pàdé rẹ̀ tòun ti irínwó [400] ọkùnrin. Jékọ́bù gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà ló rán àwọn èèyàn ṣáájú pé kí wọ́n lọ kó ẹ̀bùn onírúurú ẹran ọ̀sìn fún Ísọ̀. Ẹ̀bùn náà ṣe iṣẹ́ tí Jékọ́bù torí rẹ̀ kó wọn ránṣẹ́. Nígbà tí wọ́n fi máa fojú kojú, ọkàn Ísọ̀ ti yọ́, ó sáré wá bá Jékọ́bù, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.—Jẹ́n. 27:41-44; 32:6, 11, 13-15; 33:4, 10.
it-1 980
Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì
Torí pé Jékọ́bù bá áńgẹ́lì Jèhófà jìjàkadì ní Péníélì, Ọlọ́run yí orúkọ ẹ̀ pa dà sí Ísírẹ́lì, lẹ́yìn tí òun àti Ísọ̀ arákùnrin rẹ̀ yanjú èdèkòyédè wọn, ó lọ ń gbé ní Súkótù, lẹ́yìn náà ó lọ sí Ṣékémù. Níbẹ̀, ó ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì, ó sì pàgọ́ síbẹ̀. (Jẹ 32:24-30; 33:1-4, 17-19) Lẹ́yìn ìyẹn, Bíbélì sọ pé: “Ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pè é ní Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,” tàbí “Ọlọ́run ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” (Jẹ 33:20) Bí Jékọ́bù ṣe fi orúkọ ara rẹ̀, ìyẹn Ísírẹ́lì sọ pẹpẹ náà fi hàn pé ó tẹ́wọ́ gba orúkọ tí Ọlọ́run fún un, ó mọyì rẹ̀, ó sì tún mọyì bí Jèhófà ṣe dáàbò bò ó títí tó fi dé Ilẹ̀ Ìlérí. Ẹ̀ẹ̀kan péré ni ọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú Ìwé Mímọ́.
Bíbélì Kíkà
APRIL 27–MAY 3
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 34-35
“Àkóbá Tí Ẹgbẹ́ Búburú Máa Ń Fà”
Ṣékémù—Ìlú Tí Ń Bẹ Nínú Àfonífojì
Ojú wo ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin ìlú náà yóò fi wo wúńdíá ọlọ́mọge tí ó máa ń bẹ ìlú wọn wò déédéé—tí ó hàn gbangba pé òun nìkan ni ó máa ń dá wá yìí? Ọmọ olóyè kan “rí i, ó mú un, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bà á jẹ́.” Èé ṣe tí Dínà fi kó ara ẹ̀ sí wàhálà nípa kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ara Kénáánì oníwà àìmọ́? Ṣé torí pé ó wù ú láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n jẹ́ ojúgbà rẹ̀ ni? Àbí torí ó jẹ́ olóríkunkun tó máa ń fẹ́ ṣe tinú rẹ̀ bíi ti díẹ̀ lára àwọn arákùnrin rẹ̀ ni? Ka àkọsílẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì, kí o sì gbìyànjú láti lóye ìrora ọkàn àti ìtìjú tí Jékọ́bù àti Léà máa ní nítorí àbájáde burúkú tí ìbẹ̀wò tí ọmọbìnrin wọn ṣe sí Ṣékémù yọrí sí.—Jẹ́nẹ́sísì 34:1-31; 49:5-7; tún wo Ilé-Ìṣọ́nà, December 15, 1985, ojú ìwé 31.
“Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè”
14 Ó ṣeé ṣe kí Dínà máà ní ìbálòpọ̀ lọ́kàn nígbà tó rí Ṣékémù. Ńṣe ni Ṣékémù náà sì ṣe ohun tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ará Kénáánì máa ṣe bí ara wọn bá béèrè fún ìbálòpọ̀. Ẹ̀pa ò bóró mọ́ fún Dínà torí pé Ṣékémù “mú un” ó sì bá a “sùn.” Ó dà bíi pé lẹ́yìn náà ni Ṣékémù “kó sínú ìfẹ́ fún” Dínà, àmọ́ ìyẹn ò yí ohun tó ti ṣe fún un pa dà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 34:1-4) Nígbà tí gbogbo ẹ̀ sì pàpà já síbi tó máa já sí, Dínà nìkan kọ́ ló fara gbá a. Àwọn tó yàn láti bá ṣọ̀rẹ́ ló ṣokùnfà ohun tó kó ẹ̀gàn àti ìtìjú bá àwọn ara ilé rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 34:7, 25-31; Gálátíà 6:7, 8.
Táwọn Èèyàn Bá Ṣe Ohun Tó Dùn Ẹ́
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń gbẹ̀san lọ́pọ̀ ìgbà láti tu ara wọn nínú lórí ohun tẹ́nì kan ṣe fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà táwọn ọmọ Jékọ́bù, baba ńlá àwọn Hébérù, gbọ́ pé Ṣékémù tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kénáánì ti fipá bá Dínà, arábìnrin wọn lò pọ̀, inú wọn “bàjẹ́, inú sì bí wọn gidigidi.” (Jẹ́nẹ́sísì 34:1-7) Àwọn méjì lára àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù pète lòdì sí Ṣékémù àti agboolé rẹ̀ torí kí wọ́n lè gbẹ̀san aburú tó ṣe fún arábìnrin wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kan, Síméónì àti Léfì wọ ìlú àwọn ará Kénáánì, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin tó wà níbẹ̀ títí kan Ṣékémù.—Jẹ́nẹ́sísì 34:13-27.
Ṣé gbogbo ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí wọ́n ṣe yẹn wá yanjú ọ̀ràn náà? Nígbà tí Jékọ́bù gbọ́ nípa ohun táwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe yìí, ó bá wọn wí lọ́nà mímúná, ó ní: “Ẹ ti mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí mi ní sísọ mí di òórùn burúkú lójú àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí, . . . wọn yóò kóra jọpọ̀ lòdì sí mi, wọn yóò sì fipá kọlù mí, a ó sì pa mí rẹ́ ráúráú, èmi àti ilé mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 34:30) Ó dájú pé, dípò kọ́rọ̀ náà yanjú, òdìkejì ohun tí wọ́n fẹ́ ló ṣẹlẹ̀; ńṣe ni ìdílé Jékọ́bù wá ní láti máa bẹ̀rù àwọn aládùúgbò wọn tínú ń bí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí káwọn èèyàn yìí má bàa wá fìkanra mọ́ ìdílé Jékọ́bù ni Ọlọ́run ṣé fún ìdílé náà nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n kó lọ sí àgbègbè Bẹ́tẹ́lì.—Jẹ́nẹ́sísì 35:1, 5.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 600 ¶4
Dèbórà
1. Olùtọ́jú Rèbékà. Nígbà tí Rèbékà fi ilé Bẹ́túélì bàbá rẹ̀ sílẹ̀ láti lọ fẹ́ Ísákì ní ilẹ̀ Palẹ́sìnì, Dèbórà náà bá a lọ. (Jẹ 24:59) Lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún nílé Ísákì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ nínú ìdílé Jékọ́bù kódà lẹ́yìn tí Rèbékà kú. Ní nǹkan bí ọdún márùndínláàádóje (125) lẹ́yìn tí Rèbékà fẹ́ Ísákì, Dèbórà kú, wọ́n sì sin ín sábẹ́ igi ńlá kan ní Bẹ́tẹ́lì. Orúkọ tí wọ́n pe igi náà (ìyẹn Aloni-bákútì, tó túmọ̀ sí “Igi Óákù Tí Wọ́n Ń Sunkún Lábẹ́ Rẹ̀”) jẹ́ ká rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an nínú ìdílé Jékọ́bù.—Jẹ 35:8.
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, ṣé ìgbà gbogbo ni ìlà ìdílé tí Mèsáyà ti wá máa ń gba ọ̀dọ̀ àkọ́bí ọkùnrin kọjá?
Àwọn ìgbà kan wà tá a ti sọ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ó sì jọ pé èrò yẹn bá ohun tó wà nínú ìwé Hébérù 12:16 mu. Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé Ísọ̀ “kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀” ó sì “fi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí tọrẹ [fún Jékọ́bù] ní pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.” Ẹsẹ yìí mú kó dà bíi pé nígbà tí Ísọ̀ ta “ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí” fún Jékọ́bù, Jékọ́bù tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn baba ńlá Mèsáyà.—Mát. 1:2, 16; Lúùkù 3:23, 34.
Àmọ́ nígbà tá a tún ṣàyẹ̀wò àwọn ìtàn inú Ìwé Mímọ́, a rí i pé kò pọn dandan kí ẹnì kan jẹ́ àkọ́bí kó tó lè wà lára àwọn baba ńlá Mèsáyà. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀rí mélòó kan yẹ̀ wò:
Rúbẹ́nì ni àkọ́bí Jékọ́bù (ìyẹn Ísírẹ́lì), èyí tí Léà bí fún un. Nígbà tó yá, Réṣẹ́lì tó jẹ́ aya Jékọ́bù, tó sì tún jẹ́ ààyò rẹ̀ bí àkọ́bí ọmọkùnrin tiẹ̀ náà, ìyẹn Jósẹ́fù. Nígbà tí Rúbẹ́nì ṣe àṣemáṣe, ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́, ó sì di ti Jósẹ́fù. (Jẹ́n. 29:31-35; 30:22-25; 35:22-26; 49:22-26; 1 Kíró. 5:1, 2) Síbẹ̀, ìlà ìdílé Mèsáyà kò gba ọ̀dọ̀ Rúbẹ́nì àti Jósẹ́fù kọjá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀dọ̀ ọmọ kẹrin tí Léà bí fún Jékọ́bù ìyẹn Júdà ni ìlà ìdílé Mèsáyà gbà kọjá.—Jẹ́n. 49:10.
Bíbélì Kíkà