Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MAY 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 36-37
“Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Hùwà Ìkà Sí I Torí Wọ́n Ń Jowú Rẹ̀”
“Ẹ Jọ̀wọ́, Ẹ Fetí sí Àlá Tí Mo Lá”
Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ, ó ní: “Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ wá rí i pé baba àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ju gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra rẹ̀, wọn kò sì lè bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà àlàáfíà.” (Jẹ́nẹ́sísì 37:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè fa owú lóòótọ́, àmọ́ kò yẹ kí àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù jẹ́ kí ìlara wọ àwọn lọ́kàn. (Òwe 14:30; 27:4) Ṣé o ti bá ara rẹ ní irú ipò bẹ́ẹ̀ rí, tó jẹ́ pé ńṣe lo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara ẹnì kan torí pé àwọn èèyàn gba tiẹ̀ tàbí wọ́n fi nǹkan kan dá a lọ́lá? Rántí àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù. Owú tó jọba nínú ọkàn wọn jẹ́ kí wọ́n gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tí wọ́n kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn. Ìránnilétí àti ẹ̀kọ́ ńlá ni àpẹẹrẹ wọn jẹ́ fún àwa Kristẹni lónìí. Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé ká máa “yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀.”—Róòmù 12:15.
Jósẹ́fù náà ti fura pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti ń bínú òun. Ṣé ó wá tọ́jú ẹ̀wù aláràbarà tí bàbá rẹ̀ fún un káwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ má bàa rí? Ó ṣeé ṣe kí ìbẹ̀rù mú kó fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ẹ rántí pé Jékọ́bù fẹ́ kí ẹ̀wù náà jẹ́ àmì pé ààyò ọmọ ni Jósẹ́fù jẹ́, òun sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Jósẹ́fù náà fẹ́ kí inú bàbá òun máa dùn tó bá ń rí ẹ̀wù yẹn lára òun, ni òun náà bá ń wọ ẹ̀wù náà kiri. Àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn jẹ́ fáwa náà lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Baba wa ọ̀run kì í ṣe ojúṣàájú, àmọ́ nígbà míì, ó máa ń dìídì ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lóore. Ó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn tó jẹ́ oníwà pálapàla àti onímàgòmágó nínú ayé yìí. Bí ẹ̀wù Jósẹ́fù ṣe mú kó dá yàtọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà àwa Kristẹni tòótọ́ ṣe mú ká yàtọ̀ sí àwọn tó yí wa ká. Èyí sì lè mú káwọn èèyàn ayé bẹ̀rẹ̀ sí í jowú wa tàbí kí wọ́n máa bínú wa. (1 Pétérù 4:4) Bí Jósẹ́fù kò ṣe fi ẹ̀wù àmúyangàn rẹ̀ pamọ́ torí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni kò yẹ kí Kristẹni kan fi ìwà rẹ̀ pamọ́ tàbí kó máa díbọ́n kí àwọn èèyàn má bàa rí sí i.—Lúùkù 11:33.
“Ẹ Jọ̀wọ́, Ẹ Fetí sí Àlá Tí Mo Lá”
Jèhófà ló fi àlá yẹn hàn-án lójú oorun. Àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni Jèhófà fi hàn an, ó sì fẹ́ kó sọ ọ́ fáwọn ara ilé rẹ̀. Lọ́nà kan, ohun tí Jèhófà fẹ́ kí Jósẹ́fù ṣe jọ ohun táwọn wòlíì tó gbáyé lẹ́yìn rẹ̀ ṣe, ìyẹn ni pé wọ́n jíṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn tó jẹ́ aláìgbọràn.
Jósẹ́fù wá fọgbọ́n sọ fáwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fetí sí àlá tí mo lá yìí.” Ìtúmọ̀ àlá náà yé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, èyí sì mú kí inú túbọ̀ bí wọn. Wọ́n wá sọ fún un pé: ‘Ìwọ yóò ha jọba lé wa lórí kó o sì jẹ gàba lé wa lórí dájúdájú bí?’ Àkọsílẹ̀ náà wá fi kún un pé: “Nítorí náà, wọ́n rí àkọ̀tun ìdí láti kórìíra rẹ̀ lórí àwọn àlá rẹ̀ àti lórí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀.” Nígbà tí Jósẹ́fù wá rọ́ àlá kejì fún bàbá rẹ̀ àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, ńṣe ni wọ́n tún kẹ́nu bò ó. Bíbélì sọ pé: “Baba rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí lọ́nà mímúná, pé: “Kí ni àlá tí o lá yìí túmọ̀ sí? Èmi àti ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ pẹ̀lú yóò ha wá tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún ọ dájúdájú bí?’ ” Àmọ́ Jékọ́bù bàbá rẹ̀ ò yé ro ọ̀rọ̀ náà pé àbí Jèhófà ló ń bá ọmọ náà sọ̀rọ̀ ni?—Jẹ́nẹ́sísì 37:6, 8, 10, 11.
Jósẹ́fù kọ́ ló máa kọ́kọ́ jíṣẹ́ Ọlọ́run tó bí àwọn èèyàn nínú, òun sì kọ́ ló máa jẹ́ irú ẹ̀ kẹ́yìn. Jésù Kristi ni ọ̀gá nínú àwọn tó jẹ́ irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:20) Gbogbo Kristẹni lọ́mọdé lágbà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìgboyà Jósẹ́fù.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 678
Édómù
(Édómù) [Pupa], Àwọn Ọmọ Édómù.
Édómù ni orúkọ kejì tí wọ́n fún Ísọ̀, tó jẹ́ ìbejì Jékọ́bù. (Jẹ 36:1) Ìdí tí wọ́n ṣe fún un ní orúkọ yẹn ni pé ó ta ogún ìbí rẹ̀ nítorí ọbẹ̀ pupa. (Jẹ 25:30-34) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, nígbà tí wọ́n bí Ísọ̀, àwọ̀ pupa ló ní (Jẹ 25:25), nígbà tó yá, irú àwọ̀ yìí wá wọ́pọ̀ gan-an láwọn ilẹ̀ tí Ísọ̀ àtàwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ tẹ̀ dó sí.
it-1 561-562
Ìkáwọ́
Tí darandaran kan bá gbà láti bójú tó agbo ẹran kan, ohun tó ń sọ ni pé òun gbà láti dáàbò bo agbo ẹran náà. Ṣe ló fi ń dá ẹni tó ni agbo ẹran náà lójú pé òun máa bọ́ àwọn ẹran tó wà ní ìkáwọ́ òun, òun ò sì ní jẹ́ kí wọ́n jí wọn lọ, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, òun máa san ìtanràn tí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àmọ́ o, ìyẹn ò sọ pé àdéhùn wọn ò lè yí pa dà, torí pé tí darandaran náà bá pàdé ohun tó ju agbára rẹ̀ lọ, bí àpẹẹrẹ tí ẹranko búburú bá wá pa àwọn ẹran náà, nírú ipò yìí, darandaran náà ò ní san ìtanràn kankan. Síbẹ̀, kó tó lè sọ pé òun ò ní san ìtanràn kankan, ó máa ní láti fi ẹ̀rí han ẹni tó ni ẹran náà pé ẹranko búburú ló pa wọ́n jẹ, bí àpẹẹrẹ, ó lè gbé òkú ẹran náà wá fi hàn ẹni tó ni ín. Tẹ́ni náà bá rí i pé òótọ́ ló sọ, kò ní bu ìtanràn lé darandaran náà.
Ìlànà kan náà ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé tó bá kan ọ̀rọ̀ ohun ìní tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ ẹnì kan àti àjọṣe tó wà nínú ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, àkọ́bí ọkùnrin ló máa ń dúró bí bàbá fún àwọn àbúrò rẹ̀ tí bàbá wọn ò bá sí níbẹ̀. Èyí jẹ́ ká rí ìdí tí ọkàn Rúbẹ́nì tó jẹ́ àkọ́bí ọkùnrin kò fi balẹ̀ nígbà táwọn tó kù dábàá pé kí wọ́n pa Jósẹ́fù, bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 37:18-30. “Ó sọ pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ ká pa á.‘ . . . ‘Ẹ má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. . . . ẹ má ṣe é léṣe.’ Ó ní in lọ́kàn láti gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn kó lè dá a pa dà sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀.” Nígbà tó dé, tí ò sì rí Jósẹ́fù mọ́, ìdààmú bá a gan-an débi pé “ó fa aṣọ ara rẹ̀ ya” ó sì pariwo pé: “Ọmọ náà ti lọ! Kí ni màá ṣe báyìí?” Ó mọ̀ pé òun ni wọ́n máa bi nípa bí Jósẹ́fù ṣe dàwátì. Kí ẹ̀bi yẹn má bá wá sórí ẹ̀, wọ́n ti aṣọ Jósẹ́fù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ kó lè dà bíi pé ẹranko kan ló pa á. Wọ́n sì fi aṣọ yìí han Jékọ́bù bàbá wọn, ìyẹn mú kí Jékọ́bù gbà pé ẹranko kan ló pa Jósẹ́fù lóòótọ́, kò sì di ẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀ ru Rúbẹ́nì.—Jẹ 37:31-33.
Bíbélì Kíkà
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Kristẹni Máa Jowú?
Owú jíjẹ lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́ ní àǹfààní tirẹ̀ nínú ìjọsìn tòótọ́. Tá ò bá ranrí mọ́ kìkì iyì ara wa tàbí ẹ̀tọ́ wa, owú jíjẹ lọ́nà tó tọ́ máa ń mú ká gbọ́ ti Jèhófà. Ó ń mú ká wá onírúurú ọ̀nà láti sọ òtítọ́ nípa rẹ̀ fáwọn èèyàn, ká gbèjà ọ̀nà rẹ̀ àtàwọn èèyàn rẹ̀.
Onílé kan tó ṣi ohun tí òfin Ọlọ́run sọ nípa ẹ̀jẹ̀ lóye sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí Akiko, tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Akiko fọgbọ́n gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó tiẹ̀ tún mẹ́nu kan àwọn ewu tó wà nínú gbígba ẹ̀jẹ̀ sára pàápàá. Ìtara mímúná tó ní láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà mú kó yí ìjíròrò náà sorí ohun tó wòye pé ó mú kí obìnrin náà máa ṣàtakò—ohun náà ni pé obìnrin yìí kò gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà. Akiko bá onílé náà fèrò wérò nípa bí ìṣẹ̀dá ṣe ti ìgbàgbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà lẹ́yìn. Kì í ṣe pé ìgbèjà tó ṣe láìṣojo yìí mú kí obìnrin náà pa ẹ̀tanú tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó ní tẹ́lẹ̀ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nìkan, ó tún mu kó ṣeé ṣe fún arábìnrin yìí láti bẹ̀rẹ̀ sí bá obìnrin náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Onílé yìí tínú máa ń bí burúkú burúkú tẹ́lẹ̀ ti di olùyin Jèhófà báyìí.
Jíjowú lọ́nà tó tọ́ tàbí ìtara fún ìjọsìn tòótọ́ máa ń jẹ́ ká wà lójúfò, ó sì máa ń jẹ́ ká lo àǹfààní tá a bá ní láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn wa ká sì gbèjà rẹ̀ níbi iṣẹ́, nílé ìwé, níbi ìtajà tàbí nígbà tá a bá ń rìnrìn àjò. Bí àpẹẹrẹ, Midori pinnu pé òun á bá àwọn ẹlẹgbẹ́ òun níbi iṣẹ́ sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tóun gbà gbọ́. Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tó ti lé lẹ́ni ogójì ọdún sọ pé òun ò fẹ́ gbọ́rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà páàpáà. Nígbà tó ṣe, wọ́n jọ ní ìjíròrò mìíràn, àmọ́ obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí ṣàròyé nípa ìwà tí ò dára tí ọmọ rẹ̀ ń hù. Midori fi ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, han obìnrin yìí, ó sì sọ pé òun lè bẹ̀rẹ̀ sí bá ọmọ obìnrin náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé náà. Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bẹ̀rẹ̀, àmọ́ obìnrin náà kì í sí níbi ìjíròrò náà. Midori jẹ́ kí obìnrin yìí wo fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name. Èyí mú èrò òdì tó ti ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ kúrò. Ohun tó rí wú u lórí gan-an, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ dà bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Lòun náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi tọmọ rẹ̀.
Jíjowú lọ́nà tó tọ́ láǹfààní tirẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Ó ń mú kí ìfẹ́ gbilẹ̀ ó sì ń mú ká yẹra fún àwọn ohun tí kò dára tó lè pa àwọn ará wa nípa tẹ̀mí lára, bí òfófó ṣíṣe tàbí ríronú bíi tàwọn apẹ̀yìndà. Jíjowú lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́ á mú ká ti ìpinnu táwọn alàgbà bá ṣe lẹ́yìn, nítorí pé ìgbà míì wà tó máa ń pọn dandan fún wọn láti bá ẹni tó bá hùwà tí ò dáa wí. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13; 1 Tímótì 5:20) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa bó ṣe ń jowú nítorí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Èmi ń jowú lórí yín pẹ̀lú owú lọ́nà ti Ọlọ́run, nítorí èmi fúnra mi ti fẹ́ yín sọ́nà fún ọkọ kan, kí èmi lè mú yín wá fún Kristi gẹ́gẹ́ bí wúńdíá oníwà mímọ́.” (2 Kọ́ríńtì 11:2) Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni owú tá à ń jẹ ń mú ká sa gbogbo ipá wa láti mú kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ wà ní mímọ́ ní ti àwọn ẹ̀kọ́ wa, nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà rere.
Kò sírọ́ ńbẹ̀ o, jíjowú lọ́nà tó dáa—ìyẹn lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́—máa ń mú káwọn ẹlòmíràn ṣe ohun tó dára. Ó ń mú kéèyàn rójú rere Jèhófà, ó sì yẹ kó jẹ́ ọ̀kan lára ànímọ́ àwọn Kristẹni lónìí.—Jòhánù 2:17.
MAY 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 38-39
“Jèhófà Ò Pa Jósẹ́fù Tì”
‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
Bíbélì sọ pé: “Ní ti Jósẹ́fù, a mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí Íjíbítì, Pọ́tífárì, olórí ẹ̀ṣọ́, òṣìṣẹ́ kan láàfin Fáráò, ará Íjíbítì, sì rà á lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì tí ó mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí ibẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:1) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé wọ́n wọ́ Jósẹ́fù nílẹ̀ gan-an, ńṣe ni wọ́n sọ ọ́ di ọjà àràtúntà! Ní báyìí, ará Íjíbítì tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò, ti di ọ̀gá rẹ̀ tuntun. Kò sí ohun tí Jósẹ́fù lè ṣe sí i àfi kó máa bá a lọ sílé.
Ilé tí wọ́n ń mú Jósẹ́fù lọ yàtọ̀ pátápátá sí irú ilé tó ń gbé tẹ́lẹ̀. Ìdílé darandaran ni Jósẹ́fù ti wá, inú àgọ́ sì ni wọ́n máa ń gbé torí wọ́n máa ń ṣí káàkiri ni. Àmọ́ nílẹ̀ Íjíbítì, ilé táwọn ọlọ́lá bíi ti Pọ́tífárì ń gbé sábà máa ń rí rèǹtè-rente. Àwọn awalẹ̀pìtàn sọ pé àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì máa ń ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n á ní ọgbà nínú ilé, wọ́n á tún gbin igi tí wọ́n lè gba atẹ́gùn lábẹ́ rẹ̀, wọ́n máa ń ní odò, wọ́n á sì gbin àwọn ewéko bí òrépèté àti òṣíbàtà sí etí rẹ̀. Àárín ọgbà ni wọ́n ń kọ́ àwọn ilé míì sí, wọ́n á sì ṣe gọ̀bì sí i kí wọ́n lè máa gba atẹ́gùn. Fèrèsé ilé wọn máa ń ga kí atẹ́gùn lè wọlé, wọ́n tún máa ń kọ́ ilé ìjẹun ńlá síbẹ̀, wọ́n á sì yọ yàrá ọ̀tọ̀ fáwọn ìránṣẹ́.
‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ bí túbú wọn ṣe rí nílẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì. Àmọ́ ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí fi hàn pé ńṣe ni wọ́n mọ àwọn ilé náà bí odi gìrìwò, ó sì ní ẹ̀wọ̀n àtàwọn àjàalẹ̀ lóríṣiríṣi. Jósẹ́fù pe túbú náà ní “ihò ẹ̀wọ̀n,” èyí tó fi hàn pé ó jẹ́ ibi tó ṣókùnkùn tó sì ṣòro láti rọ́nà sá lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 40:15) Ìwé Sáàmù tún jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n fìyà jẹ Jósẹ́fù gan-an nínú túbú yẹn, ó ní: ‘Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ẹsẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì fi irin de ọrùn rẹ̀.’ (Sáàmù 105:17, 18) Nígbà míì, àwọn ará Íjíbítì máa ń fi àwọn ìjàrá de àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ ní àdè-sẹ́yìn ní ìgbọ̀nwọ́, àwọn míì sì rèé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ onírin ńlá tó dà bí akọ́rọ́ ni wọ́n á fi kọ́ wọn lọ́rùn pa pọ̀ mọ́ra. Ẹ ò rí i pé ìyà ńlá ni Jósẹ́fù jẹ lẹ́wọ̀n, bẹ́ẹ̀ kò mọwọ́ kò mẹsẹ̀!
Kì í ṣe ìgbà díẹ̀ ni Jósẹ́fù fi wà lẹ́wọ̀n yẹn o. Bíbélì sọ pé Jósẹ́fù “ń bá a lọ láti wà níbẹ̀ nínú ilé ẹ̀wọ̀n” náà, tó fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọdún ló lò nínú ẹ̀wọ̀n burúkú yẹn. Wọn ò dá ọjọ́ tàbí ìgbà kankan fún un tí wọ́n á tú u sílẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọjọ́ ń gorí ọjọ́, ọ̀sẹ̀ ń yí lu ọ̀sẹ̀, oṣù ń yí lu oṣù. Síbẹ̀, Jósẹ́fù ò kárísọ, kò sì sọ̀rètí nù, báwo ló ṣe ṣe é?
Bíbélì dá wa lóhùn pé: “Jèhófà ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí i ṣáá.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:21) Ọkàn àwa ìránṣẹ́ Jèhófà náà balẹ̀ pé ì báà jẹ́ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wá mọ́ àbí inú àjàalẹ̀ lọ́hùn-ún, Jèhófà á nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí wa ṣáá ni. (Róòmù 8:38, 39) Ó dájú pé irú ìgbọ́kànlé tí Jósẹ́fù náà ní nìyẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà tí ẹ̀dùn ọkàn fẹ́ bò ó mọ́lẹ̀, ó ké gbàjarè sí Baba rẹ̀ ọ̀run nínú àdúrà, àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn tí ó ti ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run ìtùnú” wá sì tù ú lára. (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Fílípì 4:6, 7) Jèhófà tún ṣe nǹkan míì fún Jósẹ́fù, ó yọ̀ǹda fún Jósẹ́fù láti rí “ojú rere ní ojú ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n” náà.
‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
Bíbélì dá wa lóhùn pé: “Jèhófà ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí i ṣáá.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:21) Ọkàn àwa ìránṣẹ́ Jèhófà náà balẹ̀ pé ì báà jẹ́ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wá mọ́ àbí inú àjàalẹ̀ lọ́hùn-ún, Jèhófà á nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí wa ṣáá ni. (Róòmù 8:38, 39) Ó dájú pé irú ìgbọ́kànlé tí Jósẹ́fù náà ní nìyẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà tí ẹ̀dùn ọkàn fẹ́ bò ó mọ́lẹ̀, ó ké gbàjarè sí Baba rẹ̀ ọ̀run nínú àdúrà, àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn tí ó ti ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run ìtùnú” wá sì tù ú lára. (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Fílípì 4:6, 7) Jèhófà tún ṣe nǹkan míì fún Jósẹ́fù, ó yọ̀ǹda fún Jósẹ́fù láti rí “ojú rere ní ojú ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n” náà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 555
Ónánì
(Ónánì) [tó túmọ̀ sí “agbára ìbímọ; okun”].
Ọmọkùnrin kejì tí ọmọbìnrin Ṣúà tó jẹ́ ará Kénáánì bí fún Júdà. (Jẹ 38:2-4; 1Kr 2:3) Jèhófà fikú pa Éérì tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Ónánì torí ìwà burúkú tó ń hù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì bímọ. Lẹ́yìn náà, Júdà sọ fún Ónánì pé kó ṣú Támárì tó jẹ́ ìyàwó Éérì lópó. Tó bá bí ọmọkùnrin, ọmọ náà ò ní jẹ́ ti Ónánì, ọmọ náà ló sì máa gba ogún tó tọ́ sí àkọ́bí, torí pé òun ló máa gba ogún tó jẹ́ ti Éérì; tí kò bá sì bí ọmọkùnrin, Ónánì ló máa gba ogún náà. Àmọ́, nígbà tí Ónánì bá Támárì ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lò pọ̀, “ó fi àtọ̀ rẹ̀ ṣòfò sórí ilẹ̀” dípò kó dà á sínú obìnrin náà. Kì í ṣe pé Ónánì ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ, torí pé ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé “nígbà tó bá ìyàwó ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lò pọ̀,” ó fi àtọ̀ rẹ̀ ṣòfò. Ìyẹn ni pé dípò kó da àtọ̀ rẹ̀ sínú obìnrin náà, ṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ dà á sílẹ̀. Fún ìdí yìí, Jèhófà pa Ónánì, kì í ṣe torí pé ó da àtọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, àmọ́ torí pé ó ṣàìgbọràn sí bàbá rẹ̀, ó ṣojú kòkòrò, kò sí bọ̀wọ̀ fún ètò ìgbéyàwó tí Jèhófà là kalẹ̀. Òun náà ò sì bímọ kó tó kú.—Jẹ 38:6-10; 46:12; Nọ 26:19.
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Júdà ṣe ohun tí kò dára ní ti pé kò jẹ́ kí ọmọkùnrin rẹ̀ Ṣélà fi Támárì ṣe aya gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀. Ó tún bá obìnrin kan tí ó rò pé ó jẹ́ aṣẹ́wó tẹ́ńpìlì lò pọ̀. Ohun tó ṣe yìí lòdì sí ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe pé ọkùnrin kan kò gbọ́dọ̀ bá obìnrin mìíràn lò pọ̀ àyàfi ìyàwó rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ní tòdodo, Júdà kò bá aṣẹ́wó lòpọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rọ́pò ọmọkùnrin rẹ̀ Ṣélà láìmọ̀ọ́mọ̀, ó sì ṣú obìnrin náà lópó tó fi bí àwọn ọmọ tó bá ohun tí òfin wí mu.
Ohun tí Támárì ṣe ní tiẹ̀ kì í ṣe ìṣekúṣe. Àwọn ìbejì tó bí kì í ṣe ọmọ tá a fi àgbèrè bí. Nígbà tí Bóásì ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣú Rúùtù ọmọbìnrin Móábù lópó, àwọn àgbààgbà Bẹ́tílẹ́hẹ́mù sọ̀rọ̀ Pérésì ọmọkùnrin Támárì ní rere, wọ́n sọ fún Bóásì pé: “Kí ilé rẹ sì dà bí ilé Pérésì, ẹni tí Támárì bí fún Júdà, láti inú ọmọ tí Jèhófà yóò fi fún ọ nípasẹ̀ ọ̀dọ́bìnrin yìí.” (Rúùtù 4:12) Wọ́n tún ka orúkọ Pérésì mọ́ àwọn baba ńlá Jésù Kristi.—Mátíù 1:1-3; Lúùkù 3:23-33.
Bíbélì Kíkà
MAY 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 40-41
“Jèhófà Gba Jósẹ́fù Sílẹ̀”
“Ìtúmọ̀ Kò Ha Jẹ́ Ti Ọlọ́run?”
Olórí àwọn agbọ́tí náà lè gbàgbé Jósẹ́fù, àmọ́ Jèhófà kò gbàgbé rẹ̀. Lóru ọjọ́ kan, Ọlọ́run mú kí Fáráò lá àlá méjì tó dà á láàmú. Nínú àlá àkọ́kọ́, ó rí màlúù méje tí wọ́n sanra bọ̀rọ̀kọ̀tọ̀, tí wọ́n ń jáde bọ̀ láti inú Odò Náílì. Ó tún rí màlúù méje míì tí wọ́n rù hangogo. Àwọn màlúù tó rù yìí bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àwọn màlúù méje àkọ́kọ́ tí wọ́n sanra. Kò pẹ́ ni Fáráò bá tún lálàá rí ṣírí ọkà méje tó sanra tó sì dára tí wọ́n jáde láti ara pòròpórò kan. Ó tún rí ṣírí ọkà méje míì tí wọ́n tín-ín-rín, tí ẹ̀fúùfù ti jó gbẹ. Àwọn ṣírí ọkà tín-ín-rín náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ṣírí ọkà méje tí wọ́n sanra mì. Nígbà tílẹ̀ fi máa mọ́, ọkàn Fáráò ò balẹ̀ mọ́. Ó ránṣẹ́ pe àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ àtàwọn àlùfáà pidánpidán Íjíbítì láti túmọ̀ àlá náà, ṣùgbọ́n kò sẹ́nì kankan tó mọ ìtúmọ̀ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 41:1-8) Bóyá àwọn pidánpidán náà ò rí ọ̀rọ̀ sọ tàbí kò jẹ́ pé kátikàti ni gbogbo wọ́n ń sọ, ohun tá ṣáà mọ̀ ni pé wọ́n já Fáráò kulẹ̀, inú sì bí i gan-an. Èyí mú kí Fáráò túbọ̀ tẹra mọ́ wíwá ìtumọ̀ àlá náà.
Níkẹyìn, agbọ́tí rántí Jósẹ́fù! Ó dùn ún pé òun gbàgbé Jósẹ́fù, ó lọ bá Fáráò ó sì sọ fún un nípa Jósẹ́fù. Ojú ẹsẹ̀ ni Fáráò pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Jósẹ́fù wá nínú ẹ̀wọ̀n.—Jẹ́nẹ́sísì 41:9-13.
“Ìtúmọ̀ Kò Ha Jẹ́ Ti Ọlọ́run?”
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nírẹ̀lẹ̀ tó sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi fún Jósẹ́fù ní ìtumọ̀ àlá náà. Ko jẹ́ kójú tì í bíi tàwọn ọlọ́gbọ́n àtàwọn àlùfáà Íjíbítì. Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ àlàyé, ó ní ìtumọ̀ kan náà ni àlá Fáráò méjèèjì ní. Àwọn màlúù tó sanra àtàwọn ṣírí ọkà tó dára dúró fún ọdún méje tí oúnjẹ á fi pọ̀ nílùú, àmọ́ àwọn màlúù tó rù hangogo àtàwọn ṣírí ọkà tín-ín-rín tí ẹ̀fúùfù ti jó gbẹ dúró fún ọdún méje ìyàn tí yóò dé lẹ́yìn àkókò ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ. Ìyàn náà á le débi pé yóò jẹ gbogbo ìlú run. Bí Ọlọ́run ṣe fi àlá yìí han Fáráò lẹ́ẹ̀mejì túmọ̀ sí pé “nǹkan náà fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,” ó sì dájú pé á ṣẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 41:25-32.
“Ìtúmọ̀ Kò Ha Jẹ́ Ti Ọlọ́run?”
Gbogbo ohun tí Fáráò sọ gẹ́lẹ́ ló ṣe. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n ti gbé aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà wọ Jósẹ́fù, Fáráò tún fún Jósẹ́fù ní òrùka àmì àṣẹ rẹ̀ àti ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí a fi wúrà ṣe. Wọ́n wá gbé e gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àwọn ọlọ́lá, Fáráò sì fún un ní ọlá àṣẹ lórí gbogbo ilẹ̀ náà kó lè ṣiṣẹ́ lórí àwọn àbá tó dá fún ọba! (Jẹ́nẹ́sísì 41:42-44) Láàárín ọjọ́ kan péré, Ọlọ́run yọ Jósẹ́fù lẹ́wọ̀n ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá láàfin. Ẹlẹ́wọ̀n lásánlàsàn ló wá di igbá kejì ọba yìí! Ẹ ò rí i pé ìgbàgbọ́ tí Jósẹ́fù ní nínú Ọlọ́run mú èrè wá! Jèhófà rí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ti hù sí àyànfẹ́ rẹ̀ yìí. Nígbà tó sì tó àkókò lójú rẹ̀, ó dá sí i, ó sì mú ohun gbogbo tọ́. Àmọ́, ohun tí Jèhófà ṣe gbòòrò ju pé ó san Jósẹ́fù lẹ́san ire, ńṣe ló tún ṣí ọ̀nà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ò fi ní pa run lọ́jọ́ iwájú sílẹ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ tó máa jáde lọ́jọ́ iwájú máa ṣàlàyé sí i lórí kókó yìí.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tí Jósẹ́fù fi fá irun rẹ̀ kó tó lọ rí Fáráò?
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì, Fáráò pàṣẹ pé kí wọ́n mú Jósẹ́fù ọmọ Hébérù tó wà nínú ẹ̀wọ̀n wá ní kíá, kó lè wá túmọ̀ àwọn àlá tí Fáráò lá. Ní àkókò yìí, Jósẹ́fù ti lo ọdún mélòó kan lẹ́wọ̀n. Láìka pé ojú ń kán Fáráò, Jósẹ́fù ṣì kọ́kọ́ lọ fá irun rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 39:20-23; 41:1, 14) Bí ẹni tó kọ ìwé yìí ṣe sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tó dà bíi pé kò pọn dandan yìí fi hàn pé ó mọ àṣà àwọn ará Íjíbítì dunjú.
Dídá irùngbọ̀n sí wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn ìgbàanì, títí kan àwọn ọmọ Hébérù. Àmọ́, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ọmọ Íjíbítì. Ìwé tí McClintock àti Strong ṣe tí wọ́n pè ní, Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature sọ pé “àwọn ọmọ Íjíbítì ìgbàanì nìkan ni orílẹ̀-èdè tí kì í dá irùngbọ̀n sí nígbà náà lọ́hùn-ún.”
Ṣé irùngbọ̀n nìkan ni wọ́n máa ń fá? Ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review sọ pé àwọn àṣà kan ní Íjíbítì ìgbàanì gba pé kí ọkùnrin tó bá máa wọlé sọ́dọ̀ Fáráò múra bí ẹni tó ń lọ sínú tẹ́ńpìlì. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, Jósẹ́fù máa ní láti fá gbogbo irun ara rẹ̀.
Bá A Ṣe Lè Máa Hùwà Tó Bójú Mu Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run
14 Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run rí i dájú pé àwọn kọ́ àwọn ọmọ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ ilé. Wo bí Ábúráhámù àti Ísákì ọmọ rẹ̀ ṣe bá ara wọn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 22:7. Ẹ̀kọ́ rere táwọn òbí Jósẹ́fù kọ́ ọ hàn nínú ìwà rẹ̀. Nígbà tí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, ìwà tó bójú mu ló ń hù sáwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n pàápàá. (Jẹ́n. 40:8, 14) Ọ̀nà tó gbà bá Fáráò sọ̀rọ̀ fi hàn pé ó ti kọ́ bó ṣe yẹ kéèyàn máa bá ẹni tó wà nípò gíga sọ̀rọ̀.—Jẹ́n. 41:16, 33, 34.
Bíbélì Kíkà
MAY 25-31
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 42-43
“Jósẹ́fù Kó Ara Ẹ̀ Níjàánu Lọ́nà Tó Lágbára”
“Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
Ṣé Jósẹ́fù dá wọn mọ̀ ní tiẹ̀? Ojú ẹsẹ̀ ló dá wọn mọ̀! Síwájú sí i, nígbà tó rí wọn tí wọ́n tẹrí ba fún un, ó rántí ìgbà tó wà lọ́mọdé. Ìtàn náà fi hàn pé “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jósẹ́fù rántí àwọn àlá” tí Jèhófà jẹ́ kó lá nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé, àwọn àlá yìí sọ nípa ìgbà kan lọ́jọ́ iwájú táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ máa tẹrí ba mọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe níwájú rẹ̀ báyìí! (Jẹ́nẹ́sísì 37:2, 5-9; 42:7, 9) Kí ni Jósẹ́fù máa ṣe? Ṣé ó máa gbá wọn mọ́ra ni? Àbí ó máa gbẹ̀san?
“Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
Ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù yìí má ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Síbẹ̀, gbọ́nmi-si omi-ò-to àti ìyapa sábà máà ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé lóde òní. Tí irú ìṣòro yìí bá dé bá wa, a lè fẹ́ ṣe ohunkóhun tó bá wá sọ́kàn wa, ká sì fi bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa hùwà. Ohun tó dára jù ni pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù, ká sì gbìyànjú láti mọ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká bójú tó ọ̀rọ̀ náà. (Òwe 14:12) Máa rántí pé bó ti ṣe pàtàkì pé kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn mẹ́ńbà ìdílé wa, bẹ́ẹ̀ náà ló túbọ̀ ṣe pàtàkì pé kí àlàáfíà wà láàárín àwa, Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀.—Mátíù 10:37.
“Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í dán àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wò lóríṣiríṣi ọ̀nà kó lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Kò bá wọn sọ̀rọ̀ ní tààràtà, ẹnì kan ló ń túmọ̀ ohun tó ń sọ fún wọn. Ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ líle sí wọn, ó fẹ̀sùn kàn wọ́n pé amí ni wọ́n wá ṣe láti ilẹ̀ òkèèrè. Nígbà tí wọ́n ń ṣàlàyé ara wọn, wọ́n sọ fún un nípa ìdílé wọn, kódà wọ́n mẹ́nu bà á pé àwọn ṣì ní àbúrò kan tó wà nílé. Inú Jósẹ́fù dùn, àmọ́ ó pa á mọ́ra. Ǹjẹ́ òótọ́ ni pé àbúrò rẹ̀ ṣì wà láàyè? Jósẹ́fù ti wá mọ ohun tó máa ṣe báyìí. Ó ní: “Èyí ni a óò fi dán yín wò,” ó wá sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ mú àbíkẹ́yìn yìí wá kóun lè rí i. Nígbà tó yá, ó gbà kí wọ́n pa dà sílé lọ mú àbúrò wọn pátápátá wá, kìkì tí ẹnì kan lára wọn bá gbà kí wọ́n mú òun sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 42:9-20.
it-2 108 ¶4
Jósẹ́fù
Nítorí èyí, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ronú pé ẹ̀san ló ń ké báyìí, wọ́n wò ó pé Jèhófà ló ń fìyà jẹ àwọn fún báwọn ṣe ta Jósẹ́fù sóko ẹrú lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara wọn lẹ́bi níwájú Jósẹ́fù láìmọ̀ pé òun ló wà níwájú wọn. Nígbà tí Jósẹ́fù gbọ́ bí wọ́n ṣe fi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn, ṣe ló kúrò níwájú wọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Nígbà tó jáde sí wọn pa dà, ó ní kí wọ́n de Síméónì títí dìgbà tí wọ́n á fi mú àbúrò wọn wá.—Jẹ 42:21-24.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 795
Rúbẹ́nì
Rúbẹ́nì ní àwọn ànímọ́ kan tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tàwọn tó kù pinnu láti pa Jósẹ́fù, ṣe ló rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe pa á, ó ní kí wọ́n jù ú sínú kòtò kan tí kò lómi, èrò ọkàn rẹ̀ ni pé òun á pa dà wá níkọ̀kọ̀ láti wá gba Jósẹ́fù sílẹ̀. (Jẹ 37:18-30) Ní ohun tó ju ogún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ní Íjíbítì pé amí ni wọ́n, èyí mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ìwà táwọn hù sí Jósẹ́fù làwọn ń jìyà rẹ̀ báyìí, Rúbẹ́nì wá rán àwọn tó kù létí pé òun ò bá wọn lọ́wọ́ sí ohun tí wọ́n ṣe sí Jósẹ́fù nígbà yẹn lóhùn-ún. (Jẹ 42:9-14, 21, 22) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Jékọ́bù ò jẹ́ kí Bẹ́ńjámínì tẹ̀ lé àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ sí Íjíbítì nígbà tí wọ́n ń pa dà lọ lẹ́ẹ̀kejì, Rúbẹ́nì yìí kan náà ló fi àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì dúró. Ó sọ pé “O lè pa àwọn ọmọkùnrin mi méjèèjì tí mi ò bá mú [Bẹ́ńjámínì] pa dà wá bá ọ.”—Jẹ 42:37.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì—Apá Kejì
43:32—Èé ṣe táwọn ará Íjíbítì fi kà á sóhun ìríra láti bá àwọn Hébérù jẹun? Lájorí ohun tó fà á lè jẹ́ nítorí ẹ̀tanú ìsìn tàbí nítorí ẹ̀mí ẹ̀yà-tèmi-lọ̀gá tí wọ́n ní. Àwọn ará Íjíbítì kórìíra àwọn olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú. (Jẹ́nẹ́sísì 46:34) Kí ló fà á? Ó lè jẹ́ nítorí pé ipò àwọn olùṣọ́ àgùntàn rẹlẹ̀ láwùjọ ní ilẹ̀ Íjíbítì. Tàbí kẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ sí fáwọn èèyàn láti dáko, èyí mú káwọn ará Íjíbítì fojú ẹ̀gàn wo àwọn tí wọ́n ń wá pápá tí wọ́n á ti máa da ẹran.
Bíbélì Kíkà