MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Fọkàn Yàwòrán Ohun Tó Ò Ń Kà
Tó o bá ń ka Bíbélì, máa fọkàn yàwòrán ohun tó ò ń kà. Ronú nípa àyíká ọ̀rọ̀ yẹn, àwọn tá a mẹ́nu kàn àti ohun tó ṣeé ṣe kó fà á tí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe. Fojú inú wò ó bíi pé o wà níbẹ̀, kí làwọn ohun tó o máa rí, kí ló ṣeé ṣe kó o gbọ́, báwo nibẹ̀ ṣe ń rùn, báwo sì ni nǹkan ṣe rí lára ẹni náà?
JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÚ KÍ BÓ O ṢE Ń KA BÍBÉLÌ SUNWỌ̀N SÍ I—ÀYỌLÒ, LẸ́YÌN NÁÀ, Ẹ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí làwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó fà á tí àárín Jósẹ́fù àtàwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ò fi gún?
Kí ló ṣeé ṣe kó fà á táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù fi bínú ẹ̀ débi tí wọ́n fi hùwà láìronú ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ?
Tá a bá ronú nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa Jékọ́bù, kí la lè sọ nípa irú ẹni tó jẹ́?
Àpẹẹrẹ tó dáa wo ni Jékọ́bù fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká yanjú aáwọ̀?
Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú fídíò yìí?