ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 42-43
Jósẹ́fù Kó Ara Ẹ̀ Níjàánu Lọ́nà Tó Lágbára
Fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Jósẹ́fù nígbà tó ṣàdédé rí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Ká sọ pé Jósẹ́fù ò kó ara ẹ̀ níjàánu ni, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lá ti jẹ́ káwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ̀ pé òun ni Jósẹ́fù, ó lè wá gbá wọn mọ́ra tàbí kó gbẹ̀san lára wọn. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí lo máa ṣe táwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tàbí àwọn míì bá hùwà àìdáa sí ẹ? Àpẹẹrẹ Jósẹ́fù jẹ́ ká rí i pé ó dáa ká máa kó ara wa níjàánu, ká sì máa ṣe sùúrù dípò ká kánjú hùwà tàbí ká gbé ìgbésẹ̀ láìronú.
Báwo lo ṣe lè fara wé Jósẹ́fù nínú ipò èyíkéyìí tó o bá wà?