June 15-21
JẸ́NẸ́SÍSÌ 48-50
Orin 30 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Àwọn Àgbàlagbà Ní Ohun Púpọ̀ Láti Kọ́ Wa”: (10 min.)
Jẹ 48:21, 22—Jékọ́bù fi hàn pé òun nígbàgbọ́ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣẹ́gun àwọn ará Kénáánì (it-1 1246 ¶8)
Jẹ 49:1—Àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ kó tó kú fi hàn pé ó nígbàgbọ́ (it-2 206 ¶1)
Jẹ 50:24, 25—Jósẹ́fù nígbàgbọ́ pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ (w07 6/1 28 ¶10)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Jẹ 49:19—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nípa Gádì ṣe ṣẹ? (w04 6/1 15 ¶4-5)
Jẹ 49:27—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nípa Bẹ́ńjámínì ṣe ṣẹ? (it-1 289 ¶2)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 49:8-26 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Ìpadàbẹ̀wò: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo làwọn akéde yẹn ṣe fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nígbà tí wọ́n ń wàásù? Báwo la ṣe lè fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ bíi tiwọn nígbà tá a bá ń wàásù?
Ìpadàbẹ̀wò: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 6)
Ìpadàbẹ̀wò: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà, fún un ní ìwé Bíbélì Kọ́ Wa, kó o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní orí 9. (th ẹ̀kọ́ 16)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ẹ̀kọ́ Wo Lo Lè Kọ́ Lára Àwọn Kristẹni Tó Nírìírí?”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà A Wà Níṣọ̀kan Bí Wọ́n Tilẹ̀ Fòfin Dè Wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) jy orí 119
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 25 àti Àdúrà