ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 48-50
Àwọn Àgbàlagbà Ní Ohun Púpọ̀ Láti Kọ́ Wa
Táwọn àgbàlagbà bá sọ ohun tí wọ́n ti rí nípa àwọn “iṣẹ́ àgbàyanu” tí Jèhófà ń ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ìyẹn máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀ túbọ̀ lágbára. (Sm 71:17, 18) Tẹ́ ẹ bá láwọn àgbàlagbà nínú ìjọ yín, o lè bi wọ́n nípa
bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa sìn ín nìṣó láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n ní sí
bó ṣe rí lára wọn bí wọ́n ṣe ń rí i tí àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ń pọ̀ sí i
bí inú wọn ṣe ń dùn láti rí bí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ṣe túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i
àwọn ìyípadà tó ti wáyé nínú ètò Ọlọ́run