ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb20 June ojú ìwé 5
  • Ẹ̀kọ́ Wo Ló Lè Kọ́ Lára Àwọn Kristẹni Tó Nírìírí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Wo Ló Lè Kọ́ Lára Àwọn Kristẹni Tó Nírìírí?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Ran Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Ètò Jèhófà Dunjú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ẹ Ní Ìdí fún Ayọ̀ Yíyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Wà Láìséwu Gẹ́gẹ́ Bí Apá Kan Ètò Àjọ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Bí O Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Akéde Tó Nírìírí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
mwb20 June ojú ìwé 5
Arábìnrin ọ̀dọ́ kan di ọwọ́ arábìnrin àgbàlagbà kan mú.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀kọ́ Wo Ló Lè Kọ́ Lára Àwọn Kristẹni Tó Nírìírí?

Nínú àwọn ìjọ wa, a láwọn tó ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ọdún. A sì lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. A lè bi wọ́n nípa ìtàn àwa èèyàn Jèhófà àtàwọn ìṣòro tí Jèhófà ti mú kí wọ́n borí. A tiẹ̀ lè pe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wá sí Ìjọsìn Ìdílé wa, ká sì ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní.

Tó bá jẹ́ pé o ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run, o lè sọ àwọn ìrírí tó o ti ní fáwọn Kristẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́. Jékọ́bù àti Jósẹ́fù náà sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní fáwọn míì. (Jẹ 48:21, 22; 50:24, 25) Nígbà tó yá, Jèhófà pàṣẹ pé káwọn olórí ìdílé máa kọ́ àwọn ọmọ wọn láwọn nǹkan àgbàyanu tóun ti ṣe. (Di 4:9, 10; Sm 78:4-7) Lákòókò wa yìí, àwọn òbí àtàwọn míì nínú ìjọ lè kọ́ àwọn ọ̀dọ́ láwọn nǹkan àgbàyanu tí wọ́n ti rí tí Jèhófà ṣe nípasẹ̀ ètò rẹ̀.

WO FÍDÍÒ NÁÀ A WÀ NÍṢỌ̀KAN BÍ WỌ́N TILẸ̀ FÒFIN DÈ WÁ, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Báwo ni ẹ̀ka ọ́fíìsì Austria ṣe ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa?

  • Kí làwọn ará tó wà láwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára?

  • Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn ará ní Ròmáníà fi ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ètò Ọlọ́run, báwo sì ni wọ́n ṣe pa dà?

  • Báwo làwọn ìrírí yìí ṣe fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun?

Àwòrán: Àwòrán látinú fídíò ‘A Wà Níṣọ̀kan Bí Wọ́n Tilẹ̀ Fòfin Dè Wá.’ 1. Àwòrán ilẹ̀ kan tó jẹ́ ká mọ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin dè wá ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù. 2. Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan. 3. Àwọn ará tó ń sọ èdè Romanian ń gbá ara wọn mú.

Kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn Kristẹni tó ti nírìírí gan-an kí ìgbàgbọ́ rẹ lè lágbára!

Tó bá jẹ́ pé àìpẹ́ yìí lọ̀pọ̀ àwọn tó wà nínú ìjọ rẹ ṣèrìbọmi ńkọ́? Wàá rí ìrírí àwọn ará tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run ní abala “Fídíò” lábẹ́ Ohun Tá A Ní lórí ìkànnì jw.org/yo tàbí kó o tẹ “Ìtàn Ìgbésí Ayé” sínú apá tá a pè ní “wá a” lórí ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti WatchTower.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́