Bí O Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Akéde Tó Nírìírí
A mọyì àwọn akéde tó nírìírí tí wọ́n wà nínú ìjọ. Àwọn kan lára wọn ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà bọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn míì sì wà nínú ìjọ tí wọ́n nírìírí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, àmọ́ tí wọn ò tíì pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run. Àwọn akéde yìí ti rí bí Jésù ṣe ń darí ìjọ Kristẹni láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, tó sì ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn túbọ̀ gbòòrò sí i. (Mát. 28:19, 20) Torí pé wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, àwọn akéde yìí ń gba “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” tó ń jẹ́ kí wọ́n lè kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n ní àtàwọn àdánwò. (2 Kọ́r. 4:7) Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára àwọn akéde tó nírìírí yìí. Tá a bá fún wọn láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀, inú wọ́n máa ń dùn láti kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí wọ́n mọ̀. (Sm. 71:18) Torí náà, ó yẹ ká lo àǹfààní tá a bá ní láti kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Báwo la ṣe lè ṣe é?
Ní Òde Ẹ̀rí. Àwọn akéde tuntun tàbí àwọn akéde tí kò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè di ọ̀jáfáfá lóde ẹ̀rí. Wọ́n lè kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lára àwọn akéde tó nírìírí tí wọ́n bá ń kíyè sí bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. (Wo àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ February 15, 2015 tó ní àkọlé náà, “Máa Fi Ìtara Wàásù Nìṣó,” ìpínrọ̀ kẹta lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Máa Ran Àwọn Akéde Tuntun Lọ́wọ́.”) Báwo lo ṣe jàǹfààní nínú bíbá àwọn akéde tó nírìírí ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí?
Ǹjẹ́ o lè sọ fún akéde kan tó tóótun pé wàá fẹ́ bá a ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí? Tó bá jẹ́ pé aláìlera ni akéde náà, o lè lọ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnì kan ní ilé rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́, ní kí akéde náà sọ ohun tó kíyè sí nípa bó o ṣe darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kó o sì ní kó gbà ọ́ nímọ̀ràn nípa rẹ̀.
Máa Lo Àkókò Pẹ̀lú Wọn: Tó o bá ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn akéde tó nírìírí yìí, èyí á jẹ́ kó o sún mọ́ wọn dáadáa. Pe ọ̀kan lára wọn wá sí ìjọsìn ìdílé yín, kí ẹ sì fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Bí akéde náà bá jẹ́ aláìlera, o lè ṣètò láti lọ ṣe ìjọsìn ìdílé ní ilé wọn. Ní kí wọ́n sọ bí wọ́n ṣe rí òtítọ́. Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n ti rí? Àwọn ìtẹ̀síwájú wo ni wọ́n ti rí? Kí ló ń fún wọn láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń sin Jèhófà?
Má ṣe máa retí ohun tó pọ̀ jù lọ́dọ̀ àwọn akéde yìí. Bíi tiwa, àwọn akéde tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní àwọn ẹ̀bùn àbínibí tó yàtọ̀ síra. (Róòmù 12:6-8) Àgbàlagbà ọlọ́jọ́ lórí làwọn kan lára wọn, èyí sì lè dín àkókò tí wọ́n lè lò pẹ̀lú wa kù. Síbẹ̀, torí ìrírí tí wọ́n ní bí wọ́n ṣe ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà, a lè kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lára wọn.