Ṣé O Lè Ké sí Wọn?
Ọ̀pọ̀ ìjọ máa ń ní àwọn akéde tí àìlera ń bá fínra. Àwọn míì sì wà tó jẹ́ pé ara tó ti ń dara àgbà kò jẹ́ kí wọ́n lè kópa tó pọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù mọ́. (2 Kọ́r. 4:16) Ǹjẹ́ o lè ké sí ẹni tó ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ pé kẹ́ ẹ jọ lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnì kan? Tó bá sì jẹ́ pé akéde náà kò lè jáde nílé, o lè lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nílé rẹ̀. Ǹjẹ́ o lè ṣètò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé kí ìwọ àti akéde tó jẹ́ aláìlera jọ wàásù láti ilé dé ilé láwọn ojúlé mélòó kan tàbí kí ẹ jọ lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò kan tàbí méjì? Púpọ̀ nínú àwọn akéde tó ti dàgbà ti ní ìrírí tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Torí náà, tó o bá sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́, kì í ṣe pé o máa fún wọn níṣìírí nìkan ni, ìwọ náà á jàǹfààní lára wọn. (Róòmù 1:12) Láfikún sí i, Jèhófà máa bù kún ẹ bó o ṣe ń sapá láti fi ìfẹ́ hàn lọ́nà yìí.—Òwe 19:17; 1 Jòh. 3:17, 18.