June 22-28
Ẹ́KÍSÓDÙ 1-3
Orin 7 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Èmi Yóò Di Ohun Tí Mo Bá Fẹ́”: (10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù.]
Ẹk 3:13—Mósè fẹ́ mọ ohun tí orúkọ Jèhófà túmọ̀ sí àti irú ẹni tó jẹ́ (w13 3/15 25 ¶4)
Ẹk 3:14—Jèhófà lè di ohunkóhun tó bá fẹ́ láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ (kr 43, àpótí)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Ẹk 2:10—Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà pé ọmọbìnrin Fáráò gba Mósè ṣọmọ? (g04 4/8 6 ¶5)
Ẹk 3:1—Irú àlùfáà wo ni Jẹ́tírò? (w04 3/15 24 ¶4)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ẹk 2:11-25 (th ẹ̀kọ́ 11)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 16)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà, fún onílé ní ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ kan tó jíròrò ohun tí onílé náà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (th ẹ̀kọ́ 12)
Àsọyé: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w02 6/15 11 ¶1-4—Àkòrí: Ohun Kan Tó Níye Lórí Ju Àwọn Ìṣúra Íjíbítì Lọ. (th ẹ̀kọ́ 13)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Orúkọ Jèhófà: (6 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, tó bá ṣeé ṣe, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan wá sórí pèpéle, kó o sì bi wọ́n pé: Kí ni orúkọ Jèhófà túmọ̀ sí? Kí láwọn nǹkan tí Jèhófà dá? Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́?
Ọlọ́run Gbé Orúkọ Rẹ̀ Ga ní Scandinavia: (9 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi mọ orúkọ Ọlọ́run ṣáájú àwọn ọdún 1500? Báwo ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lo orúkọ Jèhófà ní Scandinavia? Kí nìdí tó o fi mọyì Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) jy orí 120
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 104 àti Àdúrà