July 27–August 2
Ẹ́KÍSÓDÙ 12
Orin 20 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ohun Tí Ìrékọjá Túmọ̀ sí fún Àwa Kristẹni”: (10 min.)
Ẹk 12:5-7—Ohun tí ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá náà dúró fún (w07 1/1 20 ¶4)
Ẹk 12:12, 13—Ohun tí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n wọ́n sára òpó ilẹ̀kùn náà dúró fún (it-2 583 ¶6)
Ẹk 12:24-27—Ẹ̀kọ́ tí Ìrékọjá náà kọ́ wa (w13 12/15 20 ¶13-14)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Ẹk 12:12—Báwo ni àwọn ìyọnu tó dé bá àwọn ará Íjíbítì, pàápàá ìyọnu kẹwàá ṣe jẹ́ ìdájọ́ lórí àwọn ọlọ́run èké tí wọ́n ń sìn? (it-2 582 ¶2)
Ẹk 12:14-16—Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú àwọn àpéjọ mímọ́ irú bí Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú, àǹfààní wo sì nìyẹn ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (it-1 504 ¶1)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ẹk 12:1-20 (th ẹ̀kọ́ 5)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 2)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Fún un ní ìwé ìròyìn kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tẹ́ ẹ jíròrò. (th ẹ̀kọ́ 6)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) bhs 16 ¶21-22 (th ẹ̀kọ́ 19)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Jèhófà Ń Dáàbò Bo Àwọn Èèyàn Rẹ̀”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Ibi Tá À Ti Ń Ṣàfihàn Ìṣẹ́ Wa ní Oríléeṣẹ́ Fi Hàn Pé A Jẹ́ “Àwọn Èèyàn fún Orúkọ Jèhófà”.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) jy orí 125
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 129 àti Àdúrà