ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 January ojú ìwé 3
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Rí I Pé Ẹ̀ Ń Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Rí I Pé Ẹ̀ Ń Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kejì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ogun Iyebíye Làwọn Ọmọ Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 January ojú ìwé 3
Àwọn òbí kan ń kọ́ ọmọ wọn bí wọ́n ṣe máa sọ pé ‘Rárá!’ tẹ́nì kan bá ní kí wọ́n ṣe ohun tí kò dáa.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Rí I Pé Ẹ̀ Ń Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín

Lónìí, àwọn èèyàn gbà pé ohun tó dára burú, ohun tó burú sì dára. (Ais 5:20) Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ fi ń ṣe ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí, irú bíi kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀. Àwọn kan nílé ìwé lè máa fúngun mọ́ àwọn ọmọ wa láti hùwà àìtọ́. Báwo lo ṣe lè múra ọkàn àwọn ọmọ rẹ sílẹ̀ láti borí ìṣòro yìí tàbí èyí tó ṣeé ṣe kó yọjú lọ́jọ́ iwájú?

Máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Le 18:3) Máa kọ́ wọn ní ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀, kó o sì rí i pé ohun tó ò ń kọ́ wọn bá ọjọ́ orí wọn mu. (Di 6:7) Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo ti kọ́ ọmọ mi bó ṣe yẹ kó máa bá àwọn míì ṣeré lọ́nà tí ò fi ní gbé èròkerò síni lọ́kàn? Ṣé mo ti jẹ́ kó mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn máa wọ aṣọ tó bójú mu àti ohun tó yẹ kó ṣe tẹ́nì kan bá fẹ́ fọwọ́ kàn án lọ́nà tí kò tọ́? Tẹ́nì kan bá fẹ́ fi àwòrán ìṣekúṣe han ọmọ mi tàbí tí wọ́n bá ní kó ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra, ṣé ó mọ ohun tó yẹ kó ṣe?’ Tó o bá ti kọ́ wọn ní ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, wọn ò ní kó sínú ìṣòro. (Owe 27:12; Onw 7:12) Bó o ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì mọyì ẹ̀bùn tí Jèhófà fún ẹ.​—Sm 127:3.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ KỌ́ ILÉ TÓ MÁA WÀ PẸ́ TÍTÍ​—DÁÀBÒ BO ÀWỌN ỌMỌ RẸ LỌ́WỌ́ “OHUN BÚBURÚ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Kọ́ Ilé Tó Máa Wà Pẹ́ Títí​—Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ ‘Ohun Búburú.’’ Ìyá kan àti ọmọkùnrin rẹ̀ jọ ń wo fídíò ‘Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ.’

    Kí nìdí tí kò fi rọrùn fáwọn òbí kan láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Kọ́ Ilé Tó Máa Wà Pẹ́ Títí​—Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ ‘Ohun Búburú.’’ Àwọn òbí kan ń fi ìwé ‘Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà’ àtàwọn ìtẹ̀jáde míì kọ́ àwọn ọmọ wọn.

    Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn ní “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà”?​—Ef 6:4

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Kọ́ Ilé Tó Máa Wà Pẹ́ Títí​—Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ ‘Ohun Búburú.’’ Àwọn òbí kan nílẹ̀ Áfíríkà ń ka Bíbélì fún àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì jọ ń sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.

    Ọgbọ́n máa ń dáàbò boni

    Àwọn nǹkan wo ni ètò Jèhófà ti ṣe kó lè rọrùn fáwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa ìbálòpọ̀?​—w19.05 12, àpótí

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ déédéé kí wọ́n má bàa kó sínú ìṣòro?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́