ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 March ojú ìwé 5
  • Ọ̀nà Mẹ́ta Tá A Lè Gbà Fi Hàn Pé A Gbára Lé Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Mẹ́ta Tá A Lè Gbà Fi Hàn Pé A Gbára Lé Jèhófà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Máa Gbàdúrà Kó O Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Báwo Lo Ṣe Máa Ń Ṣèpinnu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 March ojú ìwé 5

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ọ̀nà Mẹ́ta Tá A Lè Gbà Fi Hàn Pé A Gbára Lé Jèhófà

Dáfídì ṣẹ́gun Gòláyátì torí pé ó gbára lé Jèhófà. (1Sa 17:45) Ó máa ń wu Jèhófà láti fi agbára rẹ̀ hàn nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (2Kr 16:9) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbára lé Jèhófà dípò òye àti ìrírí tá a ní? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀:

  • Máa gbàdúrà déédéé. Kò dìgbà tó o bá ṣàṣìṣe kó o tó gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí jì ẹ́, ó yẹ kó o máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ lókun tó o bá ń kojú ìdẹwò, kó o má bàa dẹ́ṣẹ̀. (Mt 6:12, 13) Kì í ṣe ìgbà tá a bá ti ṣèpinnu tán nìkan ló yẹ ká gbàdúrà fún ìbùkún Jèhófà, àmọ́ ó tún yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà kó sì fún wa lọ́gbọ́n tá a nílò ká tó ṣèpinnu.​—Jem 1:5

  • Máa ka Bíbélì déédéé kó o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Sm 1:2) Ronú nípa àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì kó o sì fi àwọn ẹ̀kọ́ tó o bá kọ́ sílò. (Jem 1:23-25) Máa múra sílẹ̀ kó o tó lọ sóde ẹ̀rí, dípò kó o gbára lé ìrírí tó o ní. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ń múra ìpàdé sílẹ̀, wà á túbọ̀ gbádùn ìpàdé náà.

  • Máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò Ọlọ́run. Máa kíyè sí àwọn ìtọ́ni tó dé kẹ́yìn, kó o sì múra tán láti tẹ̀ lé wọn láìjáfara. (Nọ 9:17) Bákan náà, máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni táwọn alàgbà bá ń fún wa.​—Heb 13:17

Àwọn ọlọ́pàá ń mú arákùnrin kan lọ sí àgọ́ wọn, àwọn oníròyìn àtàwọn ará sì wà níbẹ̀.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ KÒ YẸ KÁ BẸ̀RÙ INÚNIBÍNI, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

• Àwọn nǹkan wo ló ba àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lẹ́rù?

• Àwọn nǹkan wo ló fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́