ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ìfẹ́ . . . Máa Ń Retí Ohun Gbogbo”
Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tá a ní sáwọn ará wa máa ń jẹ́ ká gbà pé wọ́n máa ṣe ìpinnu tó tọ́. (1Kọ 13:4, 7) Bí àpẹẹrẹ, tí arákùnrin kan bá dẹ́ṣẹ̀, tí àwọn alàgbà sì bá a wí, a máa ń retí pé ó máa gba ìbáwí náà, á sì ṣe ìyípadà tó yẹ. A tún máa ń ṣe sùúrù pẹ̀lú àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára, a sì máa ń sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ro 15:1) Tí ẹnì kan bá fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, a máa ń nírètí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tó máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.—Lk 15:17, 18.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ GBÀGBÉ OHUN TÍ ÌFẸ́ MÁA Ń ṢE—Ó MÁA Ń RETÍ OHUN GBOGBO, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ni Ábínérì ṣe?
Ojú wo ni Dáfídì fi wo ohun tí Ábínérì béèrè, àmọ́ kí ni Jóábù ṣe?
Kí nìdí tó fi yẹ ká nírètí pé àwọn ará wa máa ṣe ohun tó dáa?