MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé O Lè Fara Da Ìṣòro Àìlówó Lọ́wọ́
Ìṣòro pọ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, nǹkan ò sì rọrùn rárá. Bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí, ó dájú pé nǹkan á túbọ̀ máa le sí i. Àwọn ìgbà míì máa wà tá ò ní láwọn nǹkan tá a nílò. (Hab 3:16-18) Kí lá jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ bá a tiẹ̀ ń kojú àwọn ìṣòro yìí? A gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà gbogbo. Jèhófà ti ṣèlérí pé òun á bójú tó àwọn ìránṣẹ́ òun, ó sì dájú pé ó lè pèsè ohun tá a nílò nígbàkigbà.—Sm 37:18, 19; Heb 13:5, 6.
Ohun tó o lè ṣe:
Bẹ Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà, kó fún ẹ lọ́gbọ́n tó o nílò, kó sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Sm 62:8
Múra tán láti ṣe iṣẹ́ tọ́pọ̀ èèyàn ò kà sí, kódà tó bá jẹ́ iṣẹ́ tó ò ṣe rí.—w12 6/1 23; g-E 1/10 8-9, àwọn àpótí
Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, máa lọ sí ìpàdé déédéé, kó o sì máa wàásù
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ KỌ́ ILÉ TÓ MÁA WÀ PẸ́ TÍTÍ—“NÍ ÌTẸ́LỌ́RÙN PẸ̀LÚ ÀWỌN NǸKAN ÌSINSÌNYÍ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ìṣòro wo làwọn ìdílé kan ní?
Kí ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé?
Báwo la ṣe lè ran àwọn aláìní lọ́wọ́?