ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb19 February ojú ìwé 8
  • Máa Fi Ìháragàgà Dúró Dè É Pẹ̀lú Ìfaradà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fi Ìháragàgà Dúró Dè É Pẹ̀lú Ìfaradà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Kó O Pàdánù Èrè Ọjọ́ Iwájú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • “Ẹ Jẹ́ Kí Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Rẹ̀ Pé Pérépéré”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìfaradà—Ṣekókó fún Àwọn Kristian
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Sisa Eré-Ìje Naa Pẹlu Ifarada
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
mwb19 February ojú ìwé 8

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Fi Ìháragàgà Dúró Dè É Pẹ̀lú Ìfaradà

Báwo ló ti ṣe pẹ́ tó, tí o ti ń retí pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé? Ó ṣeé ṣe kó o ti máa fi sùúrù fara da àwọn ìṣòro tó le koko. (Ro 8:25) Wọ́n ń ṣe inúnibíni sí àwọn kan lára wa, wọ́n ń hùwà ìkà sáwọn míì, àwọn kan lára wa wà lẹ́wọ̀n, wọ́n sì ń fi ikú halẹ̀ mọ́ àwọn míì. Àìsàn burúkú ló ń bá àwọn kan fínra, ọjọ́ ogbó ni tàwọn míì.

Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ìháragàgà dúró, tí ìṣòro èyíkéyìí bá tiẹ̀ ń bá wa fínra? A gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká sì máa ronú lórí ohun tá à ń kà, ìyẹn ló máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. A tún gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ìrètí tá a ní. (2Kọ 4:16-18; Heb 12:2) A gbọ́dọ̀ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́. (Lk 11:10, 13; Heb 5:7) Baba wa onífẹ̀ẹ́ máa ràn wá lọ́wọ́ ká ‘lè fara dà á ní kíkún, ká sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.’​—Kol 1:11.

WO FÍDÍÒ NÁÀ A GBỌ́DỌ̀ ‘FI ÌFARADÀ SÁRÉ’​—JẸ́ KÓ DÁ Ọ LÓJÚ PÉ WÀÁ GBA ÈRÈ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Jamie àti ìyàwó rẹ̀ lóde ẹ̀rí

    “Ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” wo ló lè wáyé? (Onw 9:11)

  • Lẹ́yìn tí àìsàn rọpárọsẹ̀ ṣe Jamie, Carl ń ka ẹsẹ Bíbélì kan fun

    Ìrànlọ́wọ́ wo ni àdúrà máa ń ṣe fún wa tá a bá wà nínú ìṣòro?

  • Jamie àti Carl lọ ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ tọkọtaya kan

    Tá ò bá lè ṣe tó báa ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà, kí nìdí tó fi yẹ ká máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tí agbára wa ká?

  • Jamie ń ronú ìgbà tí ara rẹ̀ máa yá nínú Párádísè

    Tẹjú mọ́ èrè náà

    Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé wàá rí èrè náà gbà?

Báwo lo ṣe lè ran àwọn tí ìṣòro dé bá àti ìdílé wọn lọ́wọ́?

  • Máa sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró, má ṣe máa fi wọ́n wé ẹlòmíì

  • Máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn

  • Máa fi wọ́n sínú àdúrà rẹ, kó o sì máa gbàdúrà pẹ̀lú wọn

  • Bá wọn se oúnjẹ tàbí kó o bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ ilé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́