ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 January ojú ìwé 8-9
  • January 29–February 4

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • January 29–February 4
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 January ojú ìwé 8-9

JANUARY 29–FEBRUARY 4

JÓÒBÙ 40-42

Orin 124 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Kí La Rí Kọ́ Nínú Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù?

(10 min.)

Máa rántí pé ìmọ̀ àti òye Jèhófà ga ju tìẹ lọ fíìfíì (Job 42:1-3; w10 10/15 3-4 ¶4-6)

Jẹ́ kó máa yá ẹ lára láti gba ìmọ̀ràn tí Jèhófà àti ètò rẹ̀ bá fún ẹ (Job 42:5, 6; w17.06 25 ¶12)

Jèhófà máa ń san àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí i lẹ́san láìka ìṣòro wọn sí (Job 42:10-12; Jem 5:11; w22.06 25 ¶17-18)

Jóòbù àtìyàwó ẹ̀ wà lórí òkè, inú wọn sì ń dùn bí wọ́n ṣe ń wo ara wọn. Jóòbù nawọ́ sí àwọn ẹran àti ilé wọn.

Jèhófà bù kún Jóòbù torí pé ó jẹ́ olóòótọ́

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Job 42:7—Ta ni àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí gan-an, báwo sì lohun tá a mọ̀ yìí ṣe lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí wa? (it-2 808)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Job 42:1-17 (th ẹ̀kọ́ 11)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni tó o fẹ́ wàásù fún kì í ṣe Kristẹni. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3)

5. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) lff ẹ̀kọ́ 13 kókó 6-7 àti Àwọn Kan Sọ Pé (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 4)

6. Àsọyé

(4 min.) lmd àfikún A kókó 2—Àkòrí: Ayé Yìí Ò Ní Pa Run Láé. (th ẹ̀kọ́ 13)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 108

7. Ṣe Ohun Táá Mú Káwọn Míì Gbà Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wọn

(15 min.) Ìjíròrò.

Apá kan nínú fídíò “A Rí Ìfẹ́ Láàárín Àwọn Èèyàn Jèhófà.” Mimi àti ìyá ẹ̀ mú káàdì àti òdòdó wá fún arábìnrin kan tó wà nílé ìwòsàn.

Inú wa dùn gan-an pé Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ là ń sìn. (1Jo 4:8, 16) Ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa ló mú kó wù wá láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ká sòótọ́, gbogbo àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà la lè jẹ́rìí sí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

Bíi ti Jèhófà, à ń sa gbogbo ipá wa láti máa fìfẹ́ hàn sáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àtàwọn míì. (Job 6:14; 1Jo 4:11) Bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn míì ti mú káwọn náà wá mọ Jèhófà kí wọ́n sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àmọ́ tá ò bá fìfẹ́ hàn sí wọn, ó lè ṣòro fún wọn láti gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ A Rí Ìfẹ́ Láàárín Àwọn Èèyàn Jèhófà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

Kí lo rí kọ́ nínú ìrírí Lei Lei àti Mimi tó bá di pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn míì?

Kí lohun tá a lè ṣe táá jẹ́ káwọn ará wa gbà pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn?

  • Máa wò wọ́n bí àgùntàn Jèhófà tó ṣeyebíye.—Sm 100:3

  • Máa bá wọn sọ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró.—Ef 4:29

  • Máa fọ̀rọ̀ wọn ro ara ẹ wò.—Mt 7:11, 12

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 5 ¶1-8, àpótí tó wà lójú ìwé 39

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 126 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́