Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2023 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
JANUARY 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 32-33
Máa Mára Tu Àwọn Tó Ní Ìdààmú Ọkàn
it-1 710
Élíhù
Élíhù ò ṣe ojúsàájú, kò sì fi ọ̀rọ̀ dídùn pọ́n ẹnikẹ́ni. Ó gbà pé bíi ti Jóòbù, Olódùmarè ló dá òun àti pé amọ̀ ló fi mọ òun. Élíhù ò sọ ohun tó máa dẹ́rù ba Jóòbù, àmọ́ ó bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni. Bí àpẹẹrẹ, Élífásì, Bílídádì àti Sófárì ò lo orúkọ Jóòbù nígbà tí wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀, àmọ́ Élíhù ṣe bẹ́ẹ̀.—Job 32:21, 22; 33:1, 6.
JANUARY 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 36-37
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 492
Ìròyìn àti Ìsọfúnni
Onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn máa ń gbà fi ìsọfúnni ránṣẹ́ láyé àtijọ́ láwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ẹnu àwọn èèyàn ni wọ́n ti máa ń gbọ́ ìròyìn ohun tó ń lọ ládùúgbò àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ìlú míì. (2Sa 3:17, 19; Job 37:20) Àwọn tó ń rìnrìn àjò sábà máa ń sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ìlú tó jìnnà tí wọ́n bá dúró lágbègbè kan láti ra oúnjẹ, omi àtàwọn nǹkan míì. Torí ibi tí ilẹ̀ Palẹ́sìnì bọ́ sí, àwọn tó ń rìnrìn àjò lọ sí Éṣíà, Áfíríkà àti Yúróòpù sábà máa ń gba ibẹ̀ kọjá. Ìyẹn mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó ń gbé níbẹ̀ láti mọ ohun tó ń lọ láwọn ilẹ̀ tó jìnnà gan-an. Torí náà, tí ẹnì kan bá lọ sí ọjà, ó máa gbọ́ ìròyìn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nílùú àtohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ilẹ̀ míì.
JANUARY 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 38-39
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 222
Afúnnilófin
Jèhófà ló ń fúnni lófin. Jèhófà ni Afúnnilófin láyé àti lọ́run. Òun ló ṣètò gbogbo òfin táwọn ẹ̀dá rẹ̀ ń tẹ̀ lé títí kan àwọn ohun tí ò lẹ́mìí (Job 38:4-38; Sm 104:5-19) àtàwọn ẹranko. (Job 39:1-30) Torí pé Jèhófà ló dá àwa èèyàn, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn òfin tó ń darí àgbáyé yìí. Bákan náà, torí pé a lè ronú, a lè lóye ohun tó dáa àtohun tí ò dáa, ká sì sún mọ́ Ọlọ́run, a tún gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé òfin tí Ọlọ́run fún wa nípa ìwà rere. (Ro 12:1; 1Kọ 2:14-16) Kódà, àwọn òfin Jèhófà ò yọ àwọn áńgélì sílẹ̀.—Sm 103:20; 2Pe 2:4, 11.
Àwọn òfin Jèhófà tó ń darí àgbáyé yìí ò ṣeé yí pa dà. (Jer 33:20, 21) Àwọn òfin yìí fẹsẹ̀ múlẹ̀ débi pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣírò ibi tí òṣùpá àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì míì máa wà lákòókò kan, kó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Tẹ́nì kan bá rú àwọn òfin tó ń darí àgbáyé yìí, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa jìyà àbájáde ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí tó bá kan àwọn òfin ìwà rere tí Ọlọ́run fún wa. Bó ṣe jẹ́ pé téèyàn bá rú òfin tó ń darí àgbáyé yìí, á jìyà ẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé téèyàn bá rú àwọn òfin ìwà rere, á jìyà ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyà náà lè má jẹ́ ojú ẹsẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kò ṣeé tàn. Nítorí ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.”—Ga 6:7; 1Ti 5:24.
JANUARY 29–FEBRUARY 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 40-42
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 808
Ọ̀rọ̀ Àbùkù
Jóòbù jẹ́ olóòótọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùtùnú èké mẹ́ta sọ̀rọ̀ àbùkù sí i. Àmọ́ èrò tó ní ò dáa, ìyẹn sì mú kó ṣàṣìṣe, torí náà Élíhù tún èrò ẹ̀ ṣe. Élíhù sọ pé: “Èèyàn míì wo ló dà bíi Jóòbù, tó ń mu ẹ̀gàn bí ẹni mu omi?” (Job 34:7) Ohun tó gba Jóòbù lọ́kàn ni bó ṣe máa dá ara ẹ̀ láre dípò Ọlọ́run, ó sì ń ronú pé òdodo òun ju ti Ọlọ́run lọ. (Job 35:2; 36:24) Jóòbù gba ẹ̀gàn àwọn olùtùnú èké mẹ́ta náà mọ́ra torí ó gbà pé òun ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí kì í ṣe Ọlọ́run. Ṣe ló dà bí ẹni tó gbà káwọn míì máa sọ̀rọ̀ àbùkù sóun tínú ẹ̀ sì ń dùn, ó wá dà bí ẹni tó ń mu ẹ̀gàn bí ẹni tó ń gbádùn omi tútù. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Ọlọ́run sọ fún Jóòbù pé ṣe làwọn olùtùnú èké yẹn sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa Ọlọ́run. (Job 42:7) Lọ́nà kan náà, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé àwọn fẹ́ ọba, Jèhófà sọ fún Sámúélì pé: “Kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ ní ọba wọn.” (1Sa 8:7) Bákan náà, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Gbogbo orílẹ̀-èdè sì máa kórìíra yín [kì í ṣe nítorí ohun tẹ́ ẹ ṣe, àmọ́] nítorí orúkọ mi.” (Mt 24:9) Tí Kristẹni kan bá fi èyí sọ́kàn, ọ̀rọ̀ àbùkù èyíkéyìí tí wọ́n bá sọ sí i kò ní kó ìrẹ̀wèsì bá a, á sì gba èrè lọ́jọ́ iwájú torí pé ó fara dà á.—Lk 6:22, 23.
FEBRUARY 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 1-4
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 425
Ìyàngbò
Ìyàngbò ni èèpo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó wà lára ọkà, bíi bálì àti àlìkámà tàbí wíìtì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sábà máa ń lo ìyàngbò lọ́nà àpẹẹrẹ, ó jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe máa ń pa ọkà láyé àtijọ́. Lẹ́yìn ìkórè, èèpo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ò wúlò mọ́. Torí náà, Bíbélì sábà máa ń fi ìyàngbò ṣàpèjúwe ohun tí kò wúlò, tó yẹ ká yà sọ́tọ̀, ká sì kó dà nù.
Lákọ̀ọ́kọ́, tí wọ́n bá ń pa ọkà, wọ́n á yọ ìyàngbò kúrò lára ọkà. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa fẹ́ ẹ, atẹ́gùn á sì fẹ́ ìyàngbò fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ náà dànù. (Wo FÍFẸ́ ỌKÀ.) Èyí ṣàpẹẹrẹ bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe máa ya àwọn apẹ̀yìndà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn rẹ̀, àti bó ṣe máa pa àwọn ẹni ibi àtàwọn orílẹ̀-èdè tó ń ta kò ó run. (Job 21:18; Sm 1:4; 35:5; Ais 17:13; 29:5; 41:15; Ho 13:3) Ìjọba Ọlọ́run máa fọ́ àwọn ọ̀tá yìí túútúú, á sì lọ̀ wọ́n débi pé ṣe ni wọ́n á fẹ́ dànù bí ìyàngbò.—Da 2:35.
Wọ́n sábà máa ń gbá ìyàngbò náà jọ, wọ́n á sì sun ún kó má bàa tún fẹ́ pa dà sínú ọkà tí wọ́n fẹ́ lò. Lọ́nà kan náà, Jòhánù Onírìbọmi sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun ìsìn èké. Jésù Kristi máa kó àlìkámà jọ, “àmọ́ ó máa fi iná tí kò ṣeé pa sun ìyàngbò.”—Mt 3:7-12; Lk 3:17; wo ÌPAKÀ.
FEBRUARY 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 5-7
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 995
Sàréè
Ní Róòmù 3:13, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 5:9 yọ, tó fi ọ̀fun àwọn ẹni burúkú wé “sàréè tó ṣí sílẹ̀.” Bó ṣe jẹ́ pé òkú àtàwọn nǹkan tó ti bà jẹ́ la máa ń kó sínú sàréè tó ṣí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ burúkú àti ọ̀rọ̀ rírùn ló máa ń jáde táwọn ẹni burúkú bá la ẹnu wọn.—Fi wé Mt 15:18-20.
FEBRUARY 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 8-10
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 832
Ìka
Bíbélì máa ń sọ ọ́ lọ́nà àpèjúwe pé Ọlọ́run fi ìka rẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ kan. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé ìka Ọlọ́run ló kọ Òfin Mẹ́wàá sórí wàláà òkúta (Ẹk 31:18; Di 9:10), àti pé ó ṣiṣẹ́ ìyanu (Ẹk 8:18, 19), ó sì fi dá òṣùpá, ìràwọ̀ àtàwọn nǹkan míì (Sm 8:3). Ẹ̀mí mímọ́ tàbí agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ni “ìka” Ọlọ́run máa ń tọ́ka sí, ìyẹn hàn gbangba nínú àkọsílẹ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn nǹkan nínú Jẹ́nẹ́sísì. Níbẹ̀, Bíbélì sọ pé agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run (ruʹach, ìyẹn “ẹ̀mí”) ń lọ káàkiri lójú omi. (Jẹ 1:2) Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jẹ́ ká mọ ohun tí ìka Ọlọ́run ṣàpẹẹrẹ. Àkọsílẹ̀ Mátíù sọ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ni Jésù fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, àmọ́ ti Lúùkù sọ pé “ìka Ọlọ́run” ló fi lé wọn jáde.—Mt 12:28; Lk 11:20.