ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Damásíkù (1-11)

      • Jèhófà máa bá àwọn orílẹ̀-èdè wí (12-14)

Àìsáyà 17:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 49:23; Sek 9:1
  • +2Ọb 16:8, 9; Ais 8:4; Emọ 1:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 195

Àìsáyà 17:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:34; Joṣ 13:15, 16; 2Ọb 10:32, 33

Àìsáyà 17:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:6; Ais 7:8; 28:1, 2; Ho 5:14
  • +2Ọb 16:8, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 195-196

Àìsáyà 17:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ọ̀rá ẹran ara rẹ̀.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 195-196

Àìsáyà 17:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:8, 12; 18:11, 16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 195-196

Àìsáyà 17:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:27; 24:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 195-196

Àìsáyà 17:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 196-197

Àìsáyà 17:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 31:1
  • +Ho 8:6, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 196-197

Àìsáyà 17:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 10:14; Emọ 3:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 196-197

Àìsáyà 17:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó wuni.”

  • *

    Tàbí “ọlọ́run àjèjì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 50:22; Ho 8:14
  • +Di 32:4; 2Sa 22:32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 196-197

Àìsáyà 17:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:30; Ho 8:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 196-197

Àìsáyà 17:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 197-198

Àìsáyà 17:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

  • *

    Tàbí “ewéko gbígbẹ tí atẹ́gùn ń gbé kiri.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 197-198

Àìsáyà 17:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 198-199

Àwọn míì

Àìsá. 17:1Jer 49:23; Sek 9:1
Àìsá. 17:12Ọb 16:8, 9; Ais 8:4; Emọ 1:5
Àìsá. 17:2Nọ 32:34; Joṣ 13:15, 16; 2Ọb 10:32, 33
Àìsá. 17:32Ọb 17:6; Ais 7:8; 28:1, 2; Ho 5:14
Àìsá. 17:32Ọb 16:8, 9
Àìsá. 17:5Joṣ 15:8, 12; 18:11, 16
Àìsá. 17:6Di 4:27; 24:20
Àìsá. 17:82Kr 31:1
Àìsá. 17:8Ho 8:6, 11
Àìsá. 17:9Ho 10:14; Emọ 3:11
Àìsá. 17:10Sm 50:22; Ho 8:14
Àìsá. 17:10Di 32:4; 2Sa 22:32
Àìsá. 17:11Di 28:30; Ho 8:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 17:1-14

Àìsáyà

17 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Damásíkù:+

“Wò ó! Damásíkù ò ní jẹ́ ìlú mọ́,

Ó sì máa di àwókù.+

 2 A máa pa àwọn ìlú Áróérì tì; +

Wọ́n máa di ibi tí àwọn agbo ẹran ń dùbúlẹ̀ sí

Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.

 3 Àwọn ìlú olódi ò ní sí mọ́ ní Éfúrémù,+

Ìjọba ò sì ní sí mọ́ ní Damásíkù;+

Àwọn tó ṣẹ́ kù lára Síríà

Sì máa dà bí ògo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,”* ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

 4 “Ní ọjọ́ yẹn, ògo Jékọ́bù máa dín kù,

Ara rẹ̀ tó dá ṣáṣá* sì máa joro.

 5 Ó máa dà bí ìgbà tí ẹni tó ń kórè bá ń kó ọkà tó wà ní ìdúró jọ,

Tí apá rẹ̀ sì ń kórè ṣírí ọkà,

Bí ìgbà tí èèyàn ń pèéṣẹ́* ọkà ní Àfonífojì* Réfáímù.+

 6 Èéṣẹ́ nìkan ló máa ṣẹ́ kù,

Bí ìgbà tí wọ́n lu igi ólífì:

Ólífì méjì tàbí mẹ́ta tó pọ́n nìkan ló ṣẹ́ kù lórí ẹ̀ka tó ga jù,

Mẹ́rin tàbí márùn-ún nìkan lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó ń so èso,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí.

7 Ní ọjọ́ yẹn, èèyàn máa yíjú sókè wo Aṣẹ̀dá rẹ̀, ojú rẹ̀ á sì máa wo Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì. 8 Kò ní wo àwọn pẹpẹ,+ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;+ kò sì ní tẹjú mọ́ ohun tó fi ìka rẹ̀ ṣe, ì báà jẹ́ àwọn òpó òrìṣà* tàbí àwọn pẹpẹ tùràrí.

 9 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ìlú ààbò rẹ̀ máa dà bí ibi tí wọ́n pa tì lórí ilẹ̀ tí igi pọ̀ sí,+

Bí ẹ̀ka tí wọ́n pa tì níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;

Ó máa di ahoro.

10 Torí o ti gbàgbé Ọlọ́run+ ìgbàlà rẹ;

O ò rántí Àpáta+ ààbò rẹ.

Ìdí nìyẹn tí o fi gbin àwọn ohun tó rẹwà,*

Tí o sì fi ọ̀mùnú àjèjì* gbìn ín.

11 Ní ọ̀sán, o rọra ṣe ọgbà yí oko rẹ ká,

Ní àárọ̀, o mú kí irúgbìn rẹ rú jáde,

Àmọ́ ìkórè ò ní sí ní ọjọ́ àìsàn àti ìrora tí kò ṣeé wò sàn.+

12 Fetí sílẹ̀! Ọ̀pọ̀ èèyàn ń fa rúkèrúdò,

Wọ́n ń pariwo bí omi òkun tó ń ru gùdù!

Àwọn orílẹ̀-èdè ń hó yèè,

Ìró wọn dà bí ariwo alagbalúgbú omi!

13 Ìró àwọn orílẹ̀-èdè máa dà bí ariwo omi púpọ̀.

Ó máa bá wọn wí, wọ́n sì máa sá lọ jìnnà réré,

Wọ́n á sá lọ bí ìgbà tí atẹ́gùn ń fẹ́ ìyàngbò* lórí àwọn òkè,

Bí ẹ̀gún* tí ìjì ń gbé yípo yípo.

14 Ìbẹ̀rù wà ní ìrọ̀lẹ́.

Kó tó di àárọ̀, wọn ò sí mọ́.

Ìpín àwọn tó ń kó wa lẹ́rù nìyí,

Ohun tó sì máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń kó ohun ìní wa nìyí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́