ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 July ojú ìwé 10-16
  • August 5-11

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • August 5-11
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 July ojú ìwé 10-16

AUGUST 5-11

SÁÀMÙ 70-72

Orin 59 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Máa Sọ Nípa Agbára Ọlọ́run “fún Ìran Tó Ń Bọ̀”

(10 min.)

Jèhófà dáàbò bo Dáfídì nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ (Sm 71:5; w99 9/1 18 ¶17)

Jèhófà dúró ti Dáfídì nígbà tó darúgbó (Sm 71:9; g04 10/8 23 ¶3)

Dáfídì sọ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí i fáwọn ọ̀dọ́ kó lè fún wọn níṣìírí (Sm 71:17, 18; w14 1/15 23 ¶4-5)

Ìdílé tó wà ní apá “Àwọn Ohun Tó Lè Mú Kẹ́ Ẹ Túbọ̀ Gbádùn Ìjọsìn Ìdílé Yín” tá a gbé yẹ̀ wò lọ́sẹ̀ tó kọjá. Wọ́n pe tọkọtaya àgbàlagbà kan wá sí ìjọsìn ìdílé wọn, inú wọn sì ń dùn bí tọkọtaya yìí ṣe ń sọ ìrírí wọn, tí wọ́n sì ń fi fọ́tò hàn wọ́n.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Èwo nínú àwọn tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún nínú ìjọ wa ni mo lè fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nígbà Ìjọsìn Ìdílé wa?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 72:8—Báwo ni ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù ní Jẹ́nẹ́sísì 15:18 ṣe ṣẹ nígbà tí Ọba Sólómọ́nì ń ṣàkóso? (it-1 768)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 71:1-24 (th ẹ̀kọ́ 5)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn, dá ọ̀rọ̀ rẹ dúró lọ́nà pẹ̀lẹ́. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Kàn sí mọ̀lẹ́bí rẹ kan tẹ́ ẹ ti jọ sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, bẹ́ ẹ ṣe ń bọ́rọ̀ lọ, o kíyè sí i pé kò wù ú láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 4)

6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(5 min.) Àsọyé. ijwfq 49—Àkòrí: Kí Ló Fà Á Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Yí Àwọn Ohun Kan tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Pa Dà? (th ẹ̀kọ́ 17)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 76

7. Àwọn Ohun Tẹ́ Ẹ Lè Ṣe Nígbà Ìjọsìn Ìdílé

(15 min.) Ìjíròrò.

Ìdílé tá a rí lẹ́ẹ̀kan dúró, wọ́n sì ń kọ orin Ìjọba náà.
Ìdílé náà ń wo ètò Tẹlifíṣọ̀n JW.
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin náà ń bá ìyá rẹ̀ sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣe ìdánrawò kan nínú ìjọsìn ìdílé wọn.

Ìjọsìn Ìdílé jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan táwọn òbí lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn ní “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Ef 6:4) Kì í rọrùn láti kẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ àwọn òbí lè mú káwọn ọmọ wọn gbádùn Ìjọsìn Ìdílé, pàápàá tó bá ń wu àwọn ọmọ náà láti túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Jo 6:27; 1Pe 2:2) Káwọn òbí lè mọ bí wọ́n ṣe lè mú kí Ìjọsìn Ìdílé gbádùn mọ́ni, káwọn tó wà níbẹ̀ sì rí ẹ̀kọ́ kọ́, ẹ wo àpótí náà “Àwọn Àbá Tẹ́ Ẹ Lè Lò fún Ìjọsìn Ìdílé,” kẹ́ ẹ sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Èwo nínú àwọn àbá tó wà níbí ni wàá fẹ́ gbìyànjú?

  • Àwọn nǹkan míì wo lẹ ti ṣe tó o gbà pé ó dáa fún ìjọsìn ìdílé?

ÀWỌN ÀBÁ TẸ́ Ẹ LÈ LÒ FÚN ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ

BÍBÉLÌ:

  • Ẹ gbọ́ àtẹ́tísí Bíbélì kíkà fún ọ̀sẹ̀ yẹn, tàbí kẹ́ ẹ pín in kà. Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé lè ka ọ̀rọ̀ ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú Bíbélì kíkà náà

  • Ẹ ṣètò àwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì kíkà fún ọ̀sẹ̀ yẹn. Kí ẹnì kọ̀ọ̀kàn nínú ìdílé mú ìbéèrè kan, kó sì ṣèwádìí nípa ẹ̀. Lẹ́yìn náà, kí kálukú sọ ohun tí wọ́n kọ́

  • Ẹ béèrè ìbéèrè kan tàbí kẹ́ ẹ sọ ohun kan tó lè ṣẹlẹ̀, kẹ́ ẹ wá ṣèwádìí àwọn ìlànà Bíbélì tẹ́ ẹ lè lò nínú ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́

  • Ẹ yan ìtàn kan nínú Bíbélì, kẹ́ ẹ sì ṣe é bí eré

  • Ẹ ṣètò káàdì kan fún ọ̀sẹ̀ kan, kẹ́ ẹ sì kọ ẹsẹ Bíbélì kan sínú káàdì náà, bí èyí tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn. Lẹ́yìn náà, ẹ gbìyànjú láti há ẹsẹ Bíbélì náà sórí. Ẹ ṣàyẹ̀wò àwọn káàdì tẹ́ ẹ ti lò sẹ́yìn

  • Ẹ jíròrò apá kan nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!

  • Ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lábẹ́ “Ohun Tí Bíbélì Sọ” tàbí “Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì,” ní abala Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ lórí ìkànnì jw.org

ÌPÀDÉ:

  • Ẹ múra apá ìpàdé kan sílẹ̀

  • Ẹ múra ohun tẹ́ ẹ máa dáhùn nípàdé sílẹ̀, kẹ́ ẹ sì fi dánra wò dáadáa. Ẹ rí i dájú pé ìdáhùn náà ò gùn jù

  • Ẹ máa kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run

  • Ẹ jíròrò ohun tẹ́ ẹ lè sọ táá fún ẹnì kan níṣìírí ṣáájú tàbí lẹ́yìn ìpàdé

  • Tí ẹnì kan bá níṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ nípàdé, ẹ jọ múra ẹ̀ sílẹ̀, kẹ́ ẹ sì fi dánra wò

IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ:

  • Ẹ múra ìwàásù ilé-dé-ilé sílẹ̀

  • Ẹ múra ohun tẹ́ ẹ máa sọ nígbà ìpadàbẹ̀wò sílẹ̀

  • Ẹ ronú ohun tẹ́ ẹ lè bá ẹnì kan sọ tẹ́ ẹ bá bára yín níbi tẹ́ ẹ ti lè wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà

  • Ẹ jíròrò àwọn nǹkan pàtó tẹ́ ẹ lè ṣe táá mú kẹ́ ẹ lè fi kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín lásìkò Ìrántí Ikú Kristi àti lásìkò ìsinmi níbiṣẹ́ tàbí nílé ìwé

ÀWỌN OHUN TÓ Ń FẸ́ ÀBÓJÚTÓ NÍNÚ ÌDÍLÉ:

  • Ẹ jíròrò ohun tẹ́ ẹ lè ṣe sí àwọn ìṣòro kan tẹ́ ẹ ní tàbí èyí tó ṣeé ṣe kó yọjú. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa bẹ́ ò ṣe ní dá sọ́rọ̀ òṣèlú, ohun tí ọmọ rẹ lè ṣe tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ọn nílé ìwé, ọ̀rọ̀ níní àfẹ́sọ́nà àtàwọn ayẹyẹ tí ò bá Bíbélì mu

  • Ẹ lè ṣe ìdánrawò níbi táwọn òbí ti máa ṣe bí ọmọ, táwọn ọmọ sì máa ṣe bí òbí. Àwọn ọmọ ló máa ṣèwádìí ohun tẹ́ ẹ máa lò, wọ́n á sì jíròrò ẹ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn

ÀWỌN ÀBÁ MÍÌ:

  • Ẹ wo ètò JW Broadcasting® kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀

  • Ẹ ka àpilẹ̀kọ kan tàbí kẹ́ ẹ wo fídíò kan lórí ìkànnì jw.org, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀

  • Ẹ jíròrò àpilẹ̀kọ kan ní abala “Ọ̀dọ́” tàbí “Ọmọdé” ní abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ lórí ìkànnì jw.org

  • Ẹ jíròrò àwọn ohun tẹ́ ẹ kọ́ nígbà àpéjọ agbègbè àti àpèjọ àyíká

  • Ẹ kíyè sí tàbí ṣèwádìí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, kẹ́ ẹ sì jíròrò ohun tí wọ́n kọ́ yín nípa Jèhófà

  • Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ pe ẹnì kan wá sí ìjọsìn ìdílé yín, kẹ́ ẹ sì fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò

  • Ẹ pinnu ohun tẹ́ ẹ máa fẹ́ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kẹ́ ẹ sì ronú bọ́wọ́ yín ṣe máa tẹ̀ ẹ́

  • Ẹ jọ ṣiṣẹ́ lórí ohun kan, bíi kíkan ọkọ̀ Nóà, yíya àwòrán ilẹ̀ tàbí kẹ́ ẹ jíròrò àwọn àtẹ tó wà nínú Bíbélì tàbí nínú àwọn ìwé wa

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ẹ Jẹ́ Kí Ìjọsìn Ìdílé Yín Túbọ̀ Gbádùn Mọ́ni. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo ni ọkọ kan ṣe lè mú kí ìyàwó ẹ̀ gbádùn ìjọsìn ìdílé tí wọ́n bá wà láwọn nìkan?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 13 ¶17-24

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 123 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́