NOVEMBER 4-10
SÁÀMÙ 105
Orin 3 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Ó Ń Rántí Májẹ̀mú Rẹ̀ Títí Láé”
(10 min.)
Jèhófà ṣèlérí kan fún Ábúráhámù, ó sì tún ìlérí náà ṣe fún Ísákì àti Jékọ́bù (Jẹ 15:18; 26:3; 28:13; Sm 105:8-11)
Ṣe ló dà bíi pé ìlérí náà ò ní lè ṣẹ (Sm 105:12, 13; w23.04 28 ¶11-12)
Jèhófà ò gbàgbé májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá (Sm 105:42-44; it-2 1201 ¶2)
BI ARA RẸ PÉ, ‘Àǹfààní wo ló máa ṣe mí tí mo bá fi sọ́kàn pé gbogbo ìlérí Jèhófà ló máa ń ṣẹ?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 105:19—Báwo ni “ọ̀rọ̀ Jèhófà” ṣe yọ́ Jósẹ́fù mọ́? (w16.08 23 ¶13)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 105:24-45 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(1 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Dá ọ̀rọ̀ rẹ dúró lọ́nà pẹ̀lẹ́ nígbà tẹ́ni náà bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 5)
6. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fún ẹni náà ní ìwé ìròyìn tó dá lórí ohun kan tẹ́ni náà nífẹ̀ẹ́ sí nígbà tẹ́ ẹ kọ́kọ́ pàdé. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)
7. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Sọ fún ẹni náà nípa JW Library®, kó o sì bá a wà á sórí fóònù ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)
Orin 84
8. Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Fìfẹ́ Hàn
(15 min.) Ìjíròrò.
Tá a bá ń fi àkókò wa, okun wa àti owó wa ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Kristi Jésù, Ọba tí Jèhófà yàn. Tá a bá ń fi ìfẹ́ wa hàn lọ́nà yìí, inú Jèhófà á dùn sí wa, àwọn ará wa sì máa jàǹfààní. (Jo 14:23) Àwọn àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ” lórí ìkànnì jw.org máa ń jẹ́ ká rí bí owó tá a fi ń ṣètìlẹyìn ṣe ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́ kárí ayé.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Iṣẹ́ Kékeré Kọ́ Ni Ìtìlẹyìn Yín Ń Ṣe. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Báwo ni owó ìtìlẹyìn tá à ń ná ká lè jọ́sìn Ọlọ́run fàlàlà ṣe ń ṣe àwọn ará wa láǹfààní?
Àǹfààní wo la ti rí bá a ṣe ń mú ‘kí nǹkan dọ́gba’ tó bá dọ̀rọ̀ ìtìlẹyìn táwọn ará ń ṣe ká lè kọ́ àwọn Ilé Ìpàdé wa kárí ayé?—2Kọ 8:14
Àǹfààní wo la ti rí bá a ṣe ń lo owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì?
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 17 ¶13-19