NOVEMBER 18-24
SÁÀMÙ 107-108
Orin 7 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Ẹ Fi Ọpẹ́ fún Jèhófà, Nítorí Ó Jẹ́ Ẹni Rere”
(10 min.)
Bí Jèhófà ṣe gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe dá wa nídè lọ́wọ́ ayé Sátánì (Sm 107:1, 2; Kol 1:13, 14)
A máa ń yin Jèhófà nínú ìjọ torí a mọyì ohun tó ń ṣe fún wa (Sm 107:31, 32; w07 4/15 20 ¶2)
Tá a bá ń fara balẹ̀ kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ìyẹn máa jẹ́ ká túbọ̀ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ látọkàn (Sm 107:43; w15 1/15 9 ¶4)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 108:9—Kí nìdí tí Bíbélì ṣe fi Móábù wé “bàsíà” tí Ọlọ́run fi ń wẹ ẹsẹ̀? (it-2 420 ¶4)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 107:1-28 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Ṣàlàyé bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fún un ní káàdì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)
6. Àsọyé
(5 min.) ijwyp 90—Àkòrí: Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́? (th ẹ̀kọ́ 14)
Orin 46
7. À Ń Kọrin Ká Lè Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà
(15 min.) Ìjíròrò.
Lẹ́yìn tí Jèhófà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ́rù ń bà lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Íjíbítì alágbára ní Òkun Pupa, inú wọn dùn gan-an, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin ọpẹ́. (Ẹk 15:1-19) Kódà, àwọn ọkùnrin ló bẹ̀rẹ̀ orin náà. (Ẹk 15:21) Jésù àtàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń kọrin ìyìn sí Ọlọ́run. (Mt 26:30; Kol 3:16) Àwa náà lè fi hàn pé a mọyì àwọn ohun tí Jèhófà ṣe fún wa tá a bá ń kọrin láwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ àyíká àti agbègbè. Bí àpẹẹrẹ, àtọdún 1966 la ti ń kọ orin tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ tán yìí, ìyẹn “A Dúpẹ́, Jèhófà,” láwọn ìpàdé wa.
Láwọn ilẹ̀ kan, ojú máa ń ti àwọn ọkùnrin láti kọrin ní gbangba. Àwọn míì kì í fẹ́ kọrin torí wọ́n gbà pé àwọn ò lóhùn orin. Síbẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé kíkọ orin láwọn ìpàdé wa jẹ́ apá kan ìjọsìn wa. Ètò Ọlọ́run ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti kọ àwọn orin aládùn, kí wọ́n sì tún yan àwọn èyí tá a máa kọ láwọn ìpàdé wa. Tiwa ò ju pé ká pa ohùn wa pọ̀ láti kọ orin ìyìn sí Baba wa ọ̀run ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, a sì mọyì gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa.
Jẹ́ káwọn ara wo FÍDÍÒ Ìtàn Wa—Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni Orin Kíkọ, Apá kejì. Lẹ́yìn náà béèrè pé:
Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1944?
Báwo làwọn ará wa ní Siberia ṣe fi hàn pé àwọn fẹ́ràn láti máa kọ orin Ìjọba Ọlọ́run?
Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi fọwọ́ pàtàkì mú orin kíkọ?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 18 ¶6-15