NOVEMBER 25–DECEMBER 1
SÁÀMÙ 109-112
Orin 14 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Kọ́wọ́ Ti Àkóso Jésù, Ọba Wa!
(10 min.)
Lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run, ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà (Sm 110:1; w06 9/1 13 ¶6)
Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ látọdún 1914 (Sm 110:2; w00 4/1 18 ¶3)
A lè fi hàn pé à ń kọ́wọ́ ti àkóso Jésù tá a bá yọ̀ǹda ara wa tinútinú (Sm 110:3; be 76 ¶2)
BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn nǹkan wo ni mo lè ṣe táá fi hàn pé mò ń kọ́wọ́ ti àkóso Jésù?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 110:4—Ṣàlàyé májẹ̀mú tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ? (it-1 524 ¶2)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 109:1-26 (th ẹ̀kọ́ 2)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìléwọ́ wa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)
5. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àṣefihàn. ijwfq 23—Àkòrí: Kí Nìdí Tí Ẹ Ò Kì Í Jagun? (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 4)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Orin 72
7. Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé Lóòótọ́ Là Ń Kọ́wọ́ Ti Ìjọba Ọlọ́run?
(15 min.) Ìjíròrò.
Bí Jèhófà ṣe fi Jésù ṣe Ọba Ìjọba rẹ̀ fi hàn pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ láyé àti lọ́run. (Da 2:44, 45) Torí náà, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kọ́wọ́ ti Ìjọba yìí, ṣe là ń fi hàn pé a gba Jèhófà ní Ọba Aláṣẹ ayé àti ọ̀run.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Ti “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” Lẹ́yìn Tọkàntọkàn. Lẹ́yìn náà béèrè pé:
Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ là ń kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run?
Àwọn ọ̀nà tá a lè gbà kọ́wọ́ ti Ìjọba Ọlọ́run la tò sísàlẹ̀ yìí. Kọ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ọ̀kọ̀ọ̀kan mu.
Rí i pé àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù láyé rẹ.
Jẹ́ kí ìlànà Ọlọ́run máa dárí èrò, ìwà àti ìṣe rẹ nígbà gbogbo.
Máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.
Máa pa àṣẹ ìjọba mọ́, àmọ́ rí i dájú pé Ọlọ́run lo ṣègbọràn sí tí òfin ìjọba bá forí gbárí pẹ̀lú òfin Ọlọ́run.
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 18 ¶16-24