MARCH 24-30
ÒWE 6
Orin 11 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Kí La Lè Kọ́ Lára Àwọn Èèrà?
(10 min.)
Tá a bá ń kíyè sí àwọn èèrà, ọ̀pọ̀ nǹkan la máa kọ́ lára wọn (Owe 6:6)
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèrà ò ní ẹni tó ń darí wọn, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọ́n sì máa ń ṣètò ohun tí wọ́n nílò lọ́jọ́ iwájú sílẹ̀ (Owe 6:7, 8; it-1 115 ¶1-2)
Tá a bá ń fara wé àwọn èèrà, ó máa ṣe wá láǹfààní (Owe 6:9-11; w00 9/15 26 ¶3-4)
© Aerial Media Pro/Shutterstock
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 6:16-19—Ṣé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí nìkan ni Ọlọ́run kórìíra?(w00 9/15 27 ¶4)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 6:1-26 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe mọ̀lẹ́bí ẹ kan tí kò wá sípàdé mọ́ sí àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Sọ fún ọ̀gá ẹ pé o fẹ́ gba àyè lọ́jọ́ Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)
6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe ẹni náà wá sí àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3)
Orin 2
7. Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Fi Hàn Pé Ó Fẹ́ Ká Máa Yọ̀—Àwọn Ẹranko Àgbàyanu
(5 min.) Ìjíròrò.
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí làwọn ẹranko lè kọ́ wa nípa Jèhófà?
8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(10 min.)
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 24 ¶7-12, àpótí ojú ìwé 193