JUNE 9-15
ÒWE 17
Orin 157 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
Tọkọtaya kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì ń jẹun, ọkàn wọn sì balẹ̀
1. Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ìdílé Rẹ
(10 min.)
Ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá kí àlàáfíà tó lè wà nínú ìdílé, àmọ́ ìsapá yẹn tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ (Owe 17:1; wo àwòrán)
Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohun tí kò tó nǹkan fa ìjà láàárín yín (Owe 17:9; g 11/14 11 ¶2)
Má ṣe tètè máa bínú (Owe 17:14; w08 5/1 10 ¶6–11 ¶1)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 17:24—Báwo ni ‘ojú àwọn òmùgọ̀ ṣe ń rìn gbéregbère títí dé ìkángun ayé’? (it-1 790 ¶2)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 17:1-17 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnì kan. (lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 4)
6. Àsọyé
(5 min.) ijwbv àpilẹ̀kọ 60—Àkòrí: Kí Ni Ìtumọ̀ Òwe 17:17? (th ẹ̀kọ́ 13)
Orin 113
7. Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kẹ́ Ẹ Lè Máa Sọ̀rọ̀ Dáadáa
(15 min.) Ìjíròrò.
Tá a bá fẹ́ kí ìdílé wa láyọ̀, ó yẹ ká máa bá ara wa sọ̀rọ̀ dáadáa ká sì máa tẹ́tí sílẹ̀. Tí àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń túra ká tí wọ́n sì ń finú han ara wọn, wọ́n á lè jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀, wọ́n á sì lè máa ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. (Owe 15:22) Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kẹ́ ẹ lè máa bá ara yín sọ̀rọ̀ dáadáa?
Ẹ máa wà pa pọ̀. (Di 6:6, 7) Tí àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń ṣe nǹkan pa pọ̀, tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀, tí wọ́n sì ń ṣeré pa pọ̀, wọ́n á túbọ̀ sún mọ́ra, wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ó tún yẹ kí wọ́n máa wáyè láti máa gbafẹ́ pa pọ̀, kí wọ́n lè túra ká. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Nígbà míì, ó lè gba pé kó o ṣe ohun tí ìdílé ẹ fẹ́ bí nǹkan yẹn ò bá tiẹ̀ wù ẹ́ ṣe, torí àǹfààní tó wà níbẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ! (Flp 2:3, 4) Kí làwọn ohun tẹ́ ẹ lè máa ṣe tẹ́ ẹ bá wà pa pọ̀ táá mú kára tù yín?—Ef 5:15, 16.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ìdílé Rẹ—Ẹ Jọ Máa Sọ̀rọ̀ Dáadáa. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Ewu wo ló wà níbẹ̀ táwọn tó wà nínú ìdílé ò bá fọgbọ́n lo fóònù?
Kí ni ohun míì tó o tún kọ́ nínú fídíò yẹn nípa bí àwọn tó wà nínú ìdílé ṣe lè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ dáadáa?
Máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. (Jem 1:19) Ó máa ń rọrùn fún àwọn ọmọdé láti sọ tinú wọn tí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn òbí wọn ò ní gba ọ̀rọ̀ wọn sódì. Torí náà, má tètè bínú táwọn ọmọ ẹ bá sọ nǹkan tó rí bákan lára ẹ. (Owe 17:27) Kàkà bẹ́ẹ̀, máa tẹ́tí sí wọn kó o sì máa gba ti wọn rò. Gbìyànjú láti mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn kó o lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, kó o sì fìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́.
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 27 ¶19-22, àpótí tó wà lójú ìwé 212