ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb25 May ojú ìwé 12-13
  • June 16-22

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • June 16-22
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
mwb25 May ojú ìwé 12-13

JUNE 16-22

ÒWE 18

Orin 90 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Máa Sọ̀rọ̀ Ìtùnú Fáwọn Tó Ń Ṣàìsàn

(10 min.)

Máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ò ń jẹ́ kí ọgbọ́n Ọlọ́run darí ẹ (Owe 18:4; w22.10 22 ¶17)

Fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹni náà, kó o lè mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ (Owe 18:13; mrt àpilẹ̀kọ 19 àpótí)

Jẹ́ ọ̀rẹ́ tó ń ranni lọ́wọ́, kó o sì máa ṣe sùúrù (Owe 18:24; wp23.1 14 ¶3–15 ¶1)

Ọkọ kan fetí sílẹ̀ dáadáa bí ìyàwó ẹ̀ ṣe ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Kí lẹnì kan lè ṣe láti ran ọkọ tàbí aya ẹ̀ lọ́wọ́ tó bá ń ṣàìsàn tó le tàbí tó bá ní àárẹ̀ ọpọlọ?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 18:18—Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń ṣẹ́ kèké láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì? (it-2 271-272)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Owe 18:1-17 (th ẹ̀kọ́ 11)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(1 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Èdè tí ẹni náà ń sọ yàtọ̀ sí tìẹ. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé kó o má jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ gùn jù. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)

6. Pa Dà Lọ

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ ohun pàtàkì kan tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)

7. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(4 min.) Àṣefihàn. ijwfq àpilẹ̀kọ 30—Àkòrí: Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì í Fi Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn Wọn? (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 144

8. Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Èèyàn Wa Lọ́wọ́ Láti Wá Sin Jèhófà “Láìsọ Ohunkóhun”

(15 min.) Ìjíròrò.

Ọ̀pọ̀ nínú wa la mọ ẹnì kan tí kò sin Jèhófà báyìí, ó lè jẹ́ ẹnì kejì wa nínú ìgbéyàwó, ọmọ wa tàbí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ kan tó ti ṣáko lọ kúrò nínú ìjọ. Ṣó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí pé nígbà tó ò ń rọ̀ wọ́n láti wá sin Jèhófà, ṣe lo bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó le gan-an, tó o sì fúngun mọ́ wọn? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ṣe la fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ tá a sọ lè túbọ̀ ba nǹkan jẹ́. (Owe 12:18) Ọ̀nà wo ló dáa jù láti ràn wọ́n lọ́wọ́?

Pétérù kìíní 3:1 sọ pé tí ọkọ arábìnrin kan ò bá kí ń ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ‘ó lè jèrè ẹ̀ láìsọ ohunkóhun.’ Èyí fi hàn pé tí ọkọ arábìnrin náà ò bá gbà á láyè láti sọ̀rọ̀ Bíbélì pẹ̀lú òun, arábìnrin náà ṣì lè ràn án lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà. Lọ́nà wo? Àwọn ẹ̀kọ́ tí arábìnrin náà ti kọ́ látinú Bíbélì ti máa jẹ́ kó ní àwọn ìwà rere bí ìfẹ́, inú rere àti ọgbọ́n. Àwọn ìwà tí arábìnrin yìí ní sì lè mú kí ọkọ ẹ̀ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Owe 16:23) Tá a bá ń hùwà tó dáa, tá a sì jẹ́ onínúure, èyí lè mú kó wu àwọn èèyàn wa tí kò sin Jèhófà báyìí láti wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀.—w10 6/15 20-21 ¶4-6.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ìgbàgbọ́ Ń Mú Kí Wọ́n Ja Àjàṣẹ́gun—Àwọn Tí Ọkọ Tàbí Aya Wọn Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

    Apá kan nínú fídíò “Ìgbàgbọ́ Ń Mú Kí Wọ́n Ja Àjàṣẹ́gun—Àwọn Tí Ọkọ Tàbí Aya Wọn Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Arábìnrin Hideko Sasaki.
  • Kí la rí kọ́ látinú ìrírí Arábìnrin Sasaki?

  • Apá kan nínú fídíò “Ìgbàgbọ́ Ń Mú Kí Wọ́n Ja Àjàṣẹ́gun—Àwọn Tí Ọkọ Tàbí Aya Wọn Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Arábìnrin Noriko Ito.
  • Kí la rí kọ́ látinú ìrírí Arábìnrin Ito?

  • Apá kan nínú fídíò “Ìgbàgbọ́ Ń Mú Kí Wọ́n Ja Àjàṣẹ́gun—Àwọn Tí Ọkọ Tàbí Aya Wọn Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Arábìnrin Tomoe Okada.
  • Kí la rí kọ́ látinú ìrírí Arábìnrin Okada?

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 27 ¶23-26, àwọn àpótí ojú ìwé 214, 217

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 60 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́