SEPTEMBER 15-21
ÒWE 31
Orin 135 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ohun Tá A Kọ́ Látinú Ìmọ̀ràn Onífẹ̀ẹ́ Tí Ìyá Kan Fún Ọmọ Ẹ̀
(10 min.)
Kọ́ àwọn ọmọ ẹ ní ìlànà Jèhófà nípa ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó (Owe 31:3, 10; w11 2/1 19 ¶7-8)
Kọ́ àwọn ọmọ ẹ ní ìlànà Jèhófà nípa ọtí mímu (Owe 31:4-6; ijwhf àpilẹ̀kọ 4 ¶11-13)
Kọ́ àwọn ọmọ ẹ láti máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bíi ti Jèhófà (Owe 31:8, 9; g17.6 9 ¶5)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 31:28—Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkọ máa yin ìyàwó ẹ̀? (w25.01 13¶16)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 31:10-31 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Bá ẹnì kan tó fi inúure hàn sí ẹ sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jíròrò ọ̀kan lára àwọn àkòrí tó wà lábẹ́ “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn,” ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)
6. Pa Dà Lọ
(5 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Pe ẹnì kan tó gba Ilé Ìṣọ́ No. 1 2025 wá sí àkànṣe àsọyé tá a máa gbọ́ láìpẹ́. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)
Orin 121
7. Ran Àwọn Ọmọ Ẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Fọgbọ́n Lo Fóònù
(8 min.) Ìjíròrò.
Ṣé o ti rí ọmọ kékeré kan tó ń lo fóònù rí? Wàá ti kíyè sí i pé kì í pẹ́ tí wọ́n fi máa ń mọwọ́ fóònù láìjẹ́ pé ẹnì kan kọ́ wọn. Àmọ́ wọ́n nílò ẹni tó máa kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa fọgbọ́n lò ó. Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè máa fọgbọ́n lo fóònù?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Lo Àkókò Rẹ Lọ́nà Tó Dáa. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí fóònù?
Àwọn nǹkan pàtàkì míì wo ló yẹ ká wáyè fún?
Dípò tí wàá fi máa fara wé àwọn òbí míì, àwọn ìlànà Bíbélì ni kó o gbára lé tó o bá fẹ́ ṣèpinnu. (Ga 6:5) Bí àpẹẹrẹ, bi ara ẹ pé:
Ṣé ọmọ mi ti ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé ó lè ṣèpinnu tó tọ́? Ṣé ó sì ti fi hàn pé ó lè kó ara ẹ̀ níjàánu débi tí màá lè jẹ́ kó lo fóònù mi tàbí kí n ra tiẹ̀ fún un?—1Kọ 9:25
Ṣó yẹ kí n jẹ́ kí ọmọ mi máa lo fóònù nígbà tó bá dá wà?—Owe 18:1
Àwọn ìkànnì wo ni màá gbà á láyè láti lọ, àwọn wo ni mi ò sì ní gbà á láyè láti lọ?—Ef 5:3-5; Flp 4:8, 9
Báwo ló ṣe yẹ kí àkókò tó máa lò lórí fóònù lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan pẹ́ tó, kó lè ráyè ṣe àwọn nǹkan pàtàkì míì?—Onw 3:1
8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(7 min.)
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 18-19