SEPTEMBER 22-28
ONÍWÀÁSÙ 1-2
Orin 103 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ẹ Túbọ̀ Máa Dá Àwọn Ìran Tó Ń Bọ̀ Lẹ́kọ̀ọ́
(10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù.]
Ó yẹ káwọn tó ti dàgbà máa dá àwọn tó kéré sí wọn lọ́jọ́ orí lẹ́kọ̀ọ́ (Onw 1:4; w17.01 27-28 ¶3-4)
Tá a bá ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń faṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́, èyí á jẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń fi okun wọn sin Jèhófà (Onw 2:24)
Má sọ pé o ò ní dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ torí pé ẹ̀rù ń bà ẹ́ pé wọ́n lè gba iṣẹ́ náà mọ́ ẹ lọ́wọ́
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Onw 2:24—Kí ni Bíbélì sọ nípa iṣẹ́? (lff ẹ̀kọ́ 37 kókó 1)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Onw 1:1-18 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Gbìyànjú láti mọ ohun tí ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí. Béèrè bó o ṣe lè kàn sí i nígbà míì. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Jíròrò ọ̀kan lára àwọn àkòrí tó wà lábẹ́ “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn,” ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn. Lo àbá tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ lábẹ́ àfikún A láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)
6. Pa Dà Lọ
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Dáhùn ìbéèrè tẹ́ni náà béèrè nígbà tẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)
7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì han ẹni náà, kó o sì ṣètò bẹ́ ẹ ṣe máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nígbà míì. (lmd ẹ̀kọ́ 10 kókó 3)
Orin 84
8. Ohun Mẹ́ta Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Tá A Bá Fẹ́ Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́
(15 min.) Ìjíròrò.
Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, àá máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, èyí á sì jẹ́ ká lè ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa láṣeyọrí
Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó ta yọ ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè kọ́ nínú bí Sámúẹ́lì ṣe dá Sọ́ọ̀lù lẹ́kọ̀ọ́, bí Èlíjà ṣe dá Èlíṣà lẹ́kọ̀ọ́, bí Jésù ṣe dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ àti bí Pọ́ọ̀lù ṣe dá Tímótì lẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀, kò sí olùkọ́ tá a lè fi wé Jèhófà. Kí la rí kọ́ nínú bó ṣe ń kọ́ wa?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Fara Wé Jèhófà Tó O Bá Ń Dáni Lẹ́kọ̀ọ́ (Jòh. 5:20)—Àyọlò. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Àwọn ẹ̀kọ́ mẹ́ta wo la lè kọ́ lára Jèhófà tó bá dọ̀rọ̀ ká dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 20-21