ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb25 September ojú ìwé 8-9
  • September 29–October 5

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • September 29–October 5
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
mwb25 September ojú ìwé 8-9

SEPTEMBER 29–OCTOBER 5

ONÍWÀÁSÙ 3–4

Orin 93 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Inú tọkọtaya kan ń dùn bí wọ́n ṣe ń ka Bíbélì pa pọ̀.

Ẹ máa wáyè láti wà pa pọ̀ kẹ́ ẹ sì máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà

1. Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kí Okùn Onífọ́nrán Mẹ́ta Yín Já

(10 min.)

Ẹ máa wáyè kẹ́ ẹ lè jọ máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa ṣe yín láǹfààní (Onw 3:1; ijwhf àpilẹ̀kọ 10 ¶2-8)

Ẹ jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀ (Onw 4:9; w23.05 23-24 ¶12-14)

Ẹ máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà (Onw 4:12; w23.05 20 ¶3)


BI ARA RẸ PÉ, ‘Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ìgbéyàwó mi tó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mi kì í sí pẹ̀lú ẹnì kejì mi, tí mo bá rìnrìn àjò lọ gbafẹ́ láìmú ẹnì kejì mi dání, tàbí tí iṣẹ́ sábà máa ń gbé mi rìnrìn àjò?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Onw 3:11—Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa kú? (w22.12 4 ¶7)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Onw 4:1-16 (th ẹ̀kọ́ 2)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi Ilé Ìṣọ́ No. 1 2025 wàásù fẹ́nì kan. Yí ọ̀rọ̀ ẹ pa dà nígbà tó o rí i pé ohun míì lẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnì kan tó gba Ilé Ìṣọ́ No. 1 2025. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 4)

6. Àsọyé

(5 min.) lmd àfikún A kókó 12—Àkòrí: Ọlọ́run Kì Í Ṣe Ojúsàájú. (th ẹ̀kọ́ 19)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 131

7. Ẹ Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Yín Lọ́wọ́ Tí Ìgbéyàwó Yín Bá Níṣòro

(15 min.) Ìjíròrò.

Jèhófà ti pèsè gbogbo ohun táwọn tọkọtaya Kristẹni nílò kí ìdílé wọn lè láyọ̀. Àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tọkọtaya lè má gbọ́ ara wọn yé. (1Kọ 7:28) Tí wọn ò bá tètè yanjú ìṣòro tí wọ́n ní, ó lè fa ẹ̀dùn ọkàn, kí wọ́n wá máa ronú pé ìṣòro náà ò lè yanjú láé. Ṣé nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé ẹ náà nìyẹn?

Nínú fídíò Kí Ni Ìfẹ́ Tòótọ́? tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ ní ìṣòro tó le gan-an nínú ìdílé wọn. Ṣé ẹ rántí ohun tí bàbá ọmọbìnrin náà sọ fún un nígbà tí ọmọbìnrin náà fẹ́ ṣe ìpinnu tí kò bá ìfẹ́ Jèhófà mu?

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Kí Ni Ìfẹ́ Tòótọ́?—Àyọlò. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká gbára lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà tí ìṣòro bá yọjú nínú ìdílé wa?—Ais 48:17; Mt 19:6

Tó o bá ní àwọn ìṣòro tó le gan-an nínú ìgbéyàwó ẹ, máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Máa lo àwọn ìlànà Bíbélì láti yanjú àwọn ìṣòro ẹ, kó o sì ka àwọn ìtẹ̀jáde tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ò ń fi hàn pé o fẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, wàá sì rí ìbùkún ẹ̀.—Owe 10:22; Ais 41:10.

Àwòrán kan látinú fídíò “Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohun tí Ayé Ń Pè Ní Àlàáfíà Tàn Ẹ́ Jẹ!—Darrel àti Deborah Freisinger.” Àwòrán tó jẹ́ ká rí ìgbà tí Arábìnrin Freisinger wà lọ́dọ̀ọ́, ó ń wo fọ́tò kan.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohun tí Ayé Ń Pè Ní Àlàáfíà Tàn Ẹ́ Jẹ!—Darrel àti Deborah Freisinger. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí ni ìrírí Arákùnrin àti Arábìnrin Freisinger kọ́ wa nípa ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá ní ìṣòro tó le gan-an nínú ìgbéyàwó wa?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 22, ọ̀rọ̀ ìṣáájú apá 5 àti ẹ̀kọ́ 23

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 51 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́