OCTOBER 6-12
ONÍWÀÁSÙ 5-6
Orin 42 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
Àwùjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ń fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ bí àlùfáà kan ṣe ń ṣàlàyé Ìwé Òfin
1. Bá A Ṣe Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Wa Atóbilọ́lá
(10 min.)
Tá a bá ń kíyè sí bá a ṣe ń múra wá sípàdé, ìyẹn á fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà (Onw 5:1; w08 8/15 15-16 ¶17-18)
Tẹ́nì kan bá ń ṣojú fún ìjọ nínú àdúrà, kó gbà á tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kó nítumọ̀, kó má sì jẹ́ kí àdúrà náà gùn jù (Onw 5:2; w09 11/15 11 ¶21)
Ó yẹ ká mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ (Onw 5:4-6; w17.04 6 ¶12)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Onw 5:8—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè tù wá nínú tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ? (w20.09 31 ¶3-5)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Onw 5:1-17 (th ẹ̀kọ́ 12)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(1 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà fẹ́ máa bá ẹ jiyàn. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 5)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jíròrò kókó kan ní apá “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn” ní àfikún A látinú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)
6. Pa Dà Lọ
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi fídíò kan tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ han ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 3)
7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Orin 160
8. Ṣé O Máa Ń Lo Apá “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn”?
(15 min.) Ìjíròrò.
Kò sí àní-àní pé àtìgbà tí ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn ti jáde ló ti ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ já fáfá nínú bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. A dìídì ṣètò àwọn kókó tó wà nínú Àfikún A kó lè rọrùn fún wa láti fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ṣe tààrà kọ́ àwọn èèyàn. (Heb 4:12) Ṣé o mọ àwọn àkòrí mẹ́sàn-án tó wà ní apá “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn”?
Báwo la ṣe lè mú ọ̀rọ̀ Bíbélì wọnú ọ̀rọ̀ tá à ń bá ẹnì kan sọ?—lmd àfikún A
Àwọn àkòrí wo làwọn tó wà lágbègbè yín nífẹ̀ẹ́ sí?
Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o túbọ̀ mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà ní àfikún A?
Bó o ṣe ń lo àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí lóde ìwàásù látìgbàdégbà, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti tètè rántí wọn. Àmọ́ ká tó lè lò wọ́n, ó yẹ ká kọ́kọ́ rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ “Irin Ń Pọ́n Irin”—Máa Wá Àwọn Tó O Máa Wàásù Fún. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí la lè ṣe ká lè máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀ lágbègbè wa?
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 24-25