OCTOBER 13-19
ONÍWÀÁSÙ 7–8
Orin 39 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Lọ sí Ilé Ọ̀fọ̀”
(10 min.)
Máa wáyè láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú (Onw 7:2; w17.07 14 ¶12)
O lè tu ẹni tèèyàn rẹ̀ kú nínú tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà rere tẹ́ni tó kú náà ní (Onw 7:1; w19.06 23 ¶15)
Gbàdúrà pẹ̀lú ẹni tí èèyàn rẹ̀ kú (w17.07 16 ¶16)
RÁNTÍ PÉ: Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣì máa ń nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn ará kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù téèyàn wọn kú.—w17.07 16 ¶17-19.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Onw 7:20-22—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè jẹ́ ká mọ̀ bóyá ó yẹ ká lọ bá ẹnì kan tó ṣẹ̀ wá tàbí ká má ṣe bẹ́ẹ̀? (w23.03 31 ¶18)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Onw 8:1-13 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fọgbọ́n wádìí ohun tẹ́ni náà nífẹ̀ẹ́ sí, kó o sì béèrè bó o ṣe lè kàn sí i nígbà míì. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)
6. Pa Dà Lọ
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ohun kan han ẹni náà lórí ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 4)
7. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àṣefihàn. ijwfq àpilẹ̀kọ 50—Àkòrí: Báwo Ni Ìsìnkú Àwa Ẹlẹ́rìí Ṣe Máa Ń Rí? (th ẹ̀kọ́ 17)
Orin 151
8. Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Àwọn Òkú Máa Jíǹde
(15 min.) Ìjíròrò.
Ọ̀kan lára ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tí Jèhófà fún wa ni ìlérí tó ṣe pé òun máa jí àwọn èèyàn tó ti kú dìde. Ìrètí àjíǹde yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà jẹ́ alágbára, ọlọ́gbọ́n, aláàánú àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Jo 3:16.
Láìka ìṣòro yòówù ká ní sí, tó bá dá wa lójú pé àjíǹde máa wà, àá lè máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún ọjọ́ iwájú, a ò sì ní máa ṣàníyàn jù nípa àwọn ìṣòro wa. (2Kọ 4:16-18) Ìrètí àjíǹde yìí máa ń fọkàn wa balẹ̀, ó sì máa ń tù wá nínú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa, tá a bá ń ṣàìsàn tàbí téèyàn wa kan bá kú. (1Tẹ 4:13) Tí àjíǹde ò bá dá wa lójú, a ò lè ní ayọ̀ tòótọ́. (1Kọ 15:19) Ó yẹ ká fi ṣe àfojúsùn wa láti máa ṣe àwọn ohun tó máa mú kí ìrètí tá a ní yìí túbọ̀ dá wa lójú.
Ka Jòhánù 11:21-24. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Báwo ni Màtá ṣe fi hàn pé ó dá òun lójú pé àjíǹde máa wà?
Ìbùkún wo ni Màtá rí torí pé ó nígbàgbọ́?—Jo 11:38-44
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Obìnrin Tí Ìgbàgbọ́ Wọn Lágbára!—Màtá. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí nìdí tó o fi mọyì ìrètí àjíǹde?
Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé àjíǹde máa wà?
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 26-27